Ìdùnnú ṣubú layọ bí Ghana ṣe gba àwọn nǹkan ìṣẹ̀nbáyé tí wọ́n jígbé lọ sókè òkun padà

Fila t'awọn oṣiṣẹ kootu maa n de ni Kumasi wa lara awọn nnkan ti wọn gba pada

Oríṣun àwòrán, British Museum

Àkọlé àwòrán, Fila t'awọn oṣiṣẹ kootu maa n de ni Kumasi wa lara awọn nnkan ti wọn gba pada
    • Author, Favour Nunoo & Thomas Naadi
    • Role, BBC News, Kumasi

Orilẹede Ghana ṣe afihan awọn nkan iṣẹnbaye ijọba Asante aye ọjọun ti wọn gba pada, lẹyin aadọjọ ọdun ti ijọba amunisin ilẹ Gẹẹsi ti ji wọn ko lọ.

Ọpọ ọmọbibi orilẹede Ghana lo lọ foju lounjẹ ni ile iko nnkan iṣẹnbaye si to wa ni aafin Manhyia ni ilu Kumasi lẹkun Asante lati wo nnkan mejilelọgbọn ti ijọba ilẹ Gẹẹsi da pada.

Ọba Otumfuo Osei Tutu Keji ti ilẹ Asante ni "ọjọ oni jẹ ọjọ awọn Asante, o si tun jẹ ọjọ gbogbo iran eeyan dudu."

Ọdun mẹta ni ijọba ilẹ Gẹẹsi sọ pe awọn nnkan iṣẹnbaye yii yoo fi wa ni Ghana.

Amọ, wọn tun ti ṣe afikun igba ti awọn nnkan yii yoo fi wa ni Ghana.

Adehun yii lo wa laarin ile iko nnkan iṣẹnbaye si meji nilẹ Gẹẹsi ati ọba Asante, sugbọn ko si adehun yii pẹlu ijọba orilẹede Ghana.

Ọba Asante jẹ ami ati alaṣẹ aṣa ni Ghana, ati pe igbagbọ eeyan ni Ghana ni ẹmi awọn baba nla rẹ ṣi wa lara rẹ.

Ọga ọlọpaa kan to ti feyinti, Henry Amankwaatia, sọ fun BBC pe "a ti gba iyi wa pada'

Mẹtadinlogun ninu nnkan iṣẹnbaye mejilelọgbọn ti wọn ṣẹṣẹ ko de Ghana pada ni ile iko-nkan iṣẹnbaye si V&A ko silẹ nigba ti ile iko-nkan iṣẹnbaye si ilẹ Gẹẹsi ko mẹẹdogun yoku silẹ.

Amọ, adehun to wa nibẹ ni pe wọn ya Ghana ni awọn nnkan iṣẹnbaye yii fun igba diẹ ni.

Nnkan ọṣọ ade to wa lara awọn nnkan yii ni wọn sọ pe wọn ji gbe lọ lasiko ogun ilẹ Gẹẹsi ati Ashanti ati ogun Sargrenti lọdun 1874.

Ara awọn goolu ti wọn ji ko lọ ree

Oríṣun àwòrán, British Museum

Àkọlé àwòrán, Ara awọn nnkan iṣẹnbaye ti wọn ko wa si Ghana pada ree.
Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Awọn nnkan mii bii ohun elo orin jita ni wọn fun oṣiṣẹ ijọba ilẹ Gẹẹsi lọdun 1817.

Ọmọwe Tristam Hunt to jẹ adari ile iko-nkan iṣẹnbaye si V&A nilẹ Gẹẹsi sọ pe "a mọ bi itan bawọn nnkan yi ṣe kuro ni Ghana ṣe dun awọn eeyan Ghana to, papaa julọ itan to niṣe pẹlu ijọba akonilẹru.

Awọn nkan yii jẹ ami to n ṣapujuwe iṣẹgun ati idojukọ ijọba Asante aye ọjọun ni Kumasi."

Ida to jẹ ọkan lara awọn nnkan ti wọn da pada jẹ ami to ṣe pataki laarin awọn eeyan Asante.

Ida yii jẹ ami ti wọn fi maa n bura fun ọba at'awọn oloye Asante laye ọjọhun.

Onimọ nipa itan, Osei-Bonsu Safo-Kantanka sọ fun BBC pe ni ṣe lo dabi "ẹni pe wọn ji lara ọkan wa lọ nigba ti awọn nnkan iṣẹnbaye yii ko fi si ni aarin ra ni Asante."

Amọ, ọrọ si tun pọ lori awọn nnkan iṣẹnbaye yii tori labẹ ofin, ile iko-nkan iṣẹnbaye si V &A ati ti ilẹ Gẹẹsi ko gbọdọ da iru nnkan iṣẹnbaye yii pada patapata.

Dida awọn nnkan iṣẹnbaye yii pada fun saa kan bi eyi to n lọ lọwọ ni Ghana jẹ ọna kan ti ilẹ Gẹẹsi maa fi n da iru nnkan yii pada.

Ọpọ awọn orilẹ-ede ti wọn n sọ pe awọn l'awọn ni awọn nnkan iṣẹnbaye yii maa n kọminu pe eto dida awọn nnkan iṣẹnbaye bayii pada fun igba diẹ le jẹ wi pe ilẹ Gẹẹsi lo ṣi ni awọn nnkan yii.

Ọpọ awọn ọmọbibi Ghana lo sọ pe ni ṣe lo yẹ k'awọn nnkan iṣẹnbaye yii pada si Ghana patapata.

Awọn orilẹ-ede Afirika ti n pe fun idapada awọn nnkan iṣẹnbaye yii s'awọn ibi ti wọn ti ji wọn ko lọ tipẹ.

Ni ọdun 2022, orilẹede Germany da ọpọ nnkan iṣẹnbaye ilu Benin to le ni ẹgbẹrun kan pada si Naijiria.

Minisita ọrọ ilẹ okeere ni orilẹede Germany sọ pe igbesẹ yii jẹ ọkan lara ọna lati ṣe atunṣe lori awọn nnkan to buru ti ijọba akonilẹru ṣe ni ilẹ Afirika.