Ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ fún ìjọba di ìparí oṣù yìí láti san N615,000 owó oṣù òṣìṣẹ́ tó kéré jùlọ tí wọ́n ń bèèrè

Aworan egbe osise

Oríṣun àwòrán, Nigeria Labour Congress/X

Ẹgbẹ oṣiṣẹ ni Naijiria ti fun ijọba apapọ ni gbedeke ọjọ kọkanlelọgbọn oṣu Karun un yii lati fẹnuko lori N615,000 t'awọn oṣiṣẹ n beere fun.

Awọn adari ẹgbẹ oṣiṣẹ sọrọ yii nibi ayajọ ọjọ awọn oṣiṣẹ lánàá ọjọ kinni oṣu Karun un ọdun 2024.

Lasiko ti ayẹyẹ ayajọ ọjọ oṣiṣẹ n lọ lọwọ niluu Abuja ni ẹgbẹ oṣiṣẹ sọ koko mejidinlogun ti awọn n fẹ ki ijọba ṣe, eyi ti N615,000 gẹgẹ bi owo oṣu oṣiṣẹ to kere julọ jẹ ọkan gboogi lara wọn.

Kini ẹgbẹ́ òṣiṣẹ n sọ bayii?

Wọn ni awọn ko ni beṣu bẹgba lati gunle iyanṣẹlodi, ti ijọba ko ba ṣe ohun ti awọn fẹ ni ipari oṣu Karun un yii.

Ẹgbẹ oṣiṣẹ duro lori N615,000 gẹgẹ bi owo oṣu oṣiṣẹ to kere julọ

Aarẹ ẹgbẹ oṣiṣẹ NLC, Joe Ajaero ati Festus Osifo ti ẹgbẹ TUC fi aidunnu wọn han lori bi igbe aye awọn oṣiṣẹ ko ṣe rọrun ni bii ọdun kan sẹyin.

Wọn ni N30,000 owo oṣu oṣiṣẹ to kere julọ ti ijọba n san tẹlẹ ti dopin lati ọjọ kejidinlogun oṣu Kẹrin to kọja labẹ ofin.

Wọn ni o ti yẹ ki ijọba ti bẹrẹ si ni san owo oṣu tuntun fawọn oṣiṣẹ bayii.

Awọn adari ẹgbẹ oṣiṣẹ naa ni awọn ko ni gba owo to din ni N615,000 gẹgẹ bi owo oṣu oṣiṣẹ to kere julọ.

"N615,000 ni owo to le to fun awọn oṣiṣẹ lati gbe iye aye to gbadun pẹlu bi nnkan ṣe wọn gogo bayii.

A ti jiroro lori bi nnkan ṣe ri ni Naijiria, a ṣi ti ri pe N615,000 lo le to oṣiṣẹ ti ipo rẹ kere julọ na loṣu kan.

Awọn adari ẹgbẹ oṣiṣẹ ni arumọjẹ lasan ni afikun 25% ati 35% ti ijọba apapọ kede, wọn ni owo osu to kere julọ tawon n beere fun lo ṣe koko.

Tinubu kede afikun 25% ati 35% owo oṣu fawọn oṣiṣẹ ijọba apapọ

Ijọba apapọ Naijiria ti ṣe afikun owo oṣu awọn oṣiṣẹ kan ni ida 25% ati 35%.

Awọn ti afikun owo oṣu naa kan lawọn oṣiṣẹ to n gba owo oṣu wọn labẹ eto CONPSS, CONRAISS, CONPOSS, CONPASS, CONICCS ati CONAFSS.

Alukoro ajọ to n ri si ọrọ owo oṣu oṣiṣẹ ijọba apapọ, National Salaries, Incomes and Wages Commission (NSIWC), Emmanuel Njoku, lo fi ọrọ naa lede.

Atẹjade naa ni afikun ọhun ti bẹrẹ lati ọjọ kinni, oṣu Kinni, ọdun 2024 yii.

Ipinlẹ Eko ṣetan lati san owo oṣu oṣiṣẹ to kere julọ ti ijọba apapọ ba kede - Sanwo-Olu

Gomina ipinle Eko, Babajide Sanwo-Olu ti sọ pe ijọba oun ṣetan lati san owo oṣiṣẹ to kere julọ ti ijọba apapọ ba kede.

Sanwo-Olu seleri yii nigba ti o b'awọn oṣiṣẹ ipinlẹ Eko sọrọ nibi ayajọ ọjọ awọn oṣiṣẹ lọjọ kinni oṣu Karun un.

"Mo ki awọn oṣiṣẹ fun ifarajin wọn lẹnu iṣẹ, mo ṣi n fi dawọn loju pe ijọba ipinlẹ Eko yoo mu igbayegbadun wọn lọkunkundun.

Bakan naa, ijọba mi yoo tẹsiwaju lati maa ṣe idanilẹkọ ati oriṣiiriṣii eto fawọn oṣiṣẹ lati le jẹ ki wọn maa fakọyọ sii lẹnu iṣẹ wọn," Sanwo-Olu lo sọ bẹẹ.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post