Àfikún 25% àti 35% gorí owó oṣù òṣìṣẹ́ ìjọba àpapọ̀ kọ̀ọ̀kan

Oríṣun àwòrán, Bola Tinubu
Ijọba apapọ Naijiria ti ṣe afikun owo oṣu awọn oṣiṣẹ kan ni ida 25% ati 35%.
Awọn ti afikun owo oṣu naa kan lawọn oṣiṣẹ to n gba owo oṣu wọn labẹ eto CONPSS, CONRAISS, CONPOSS, CONPASS, CONICCS ati CONAFSS.
Alukoro ajọ to n ri si ọrọ owo oṣu oṣiṣẹ ijọba apapọ, National Salaries, Incomes and Wages Commission (NSIWC), Emmanuel Njoku, lo fi ọrọ naa lede.
Atẹjade naa ni afikun ọhun ti bẹrẹ lati ọjọ kinni, oṣu Kinni, ọdun 2024 yii.
Ṣaaju ni ijọba apapọ ti kọkọ ṣe afikun awọn oṣu oṣiṣẹ to wa ni ẹka eto ẹkọ ati eto ilera, iyẹn CONUASS ati CONTISS.
Bẹẹ naa lo tun ni oun ti ṣafikun owo oṣu awọn to n gba owo labẹ ẹka CONPCASS ati CONTEDISS.
Awọn oṣiṣẹ eto ilera mii tun n gba owo oṣu tiwọn ;abẹ eto CONMESS ati CONHESS.
Kini ijọba tun ṣe fun awọn osise-feyinti?
Yatọ si afikun owo oṣiṣẹ yii, ijọba apapọ tun ti buwọlu afikun owo oṣu awọn oṣiṣẹfẹyinti ni ida 20% ati 28%.
Afikun ọhun lo bẹrẹ lati ọjọ kinni, oṣu Kinni, ọdun 2024 fun awọn to wa labẹ ẹka CONPSS, CONRAISS, CONPOSS, CONPASS, CONICCS ati CONAFSS.
Lara awọn oṣiṣẹ to wa labẹ eto CONPSS, CONRAISS, CONPOSS, CONPASS, CONICCS ati CONAFSS ọhun ni awọn ọlọpaa, ologun atawọn agbofinro mii wa.
Ọpọ araalu lo ti bẹrẹ si n fi erongba wọn lede lori iroyin naa ti pupọ ninu wọn si n sọ pe igbesẹ naa dara latari ọwọngogo to gbode ni Naijiria lasiko yii.
Amọ awọn araalu mii n sọ pe afikun naa ti kere ju nitori nnkan ti wọn ju afikun owo oṣu ọhun lọ.
Awon wo ni ọ̀rọ̀ tun kan?
Bakan naa ni wọn tun sọ pe ẹkunwo ida ogun titi de ida mejidinlọgbọn ti wa lori owo oṣu awọn oṣiṣẹ-fẹyinti.
Ipele to kẹyin ree ninu agbekalẹ mẹfa ti wọn fi n ṣeto owo oṣu.
Lara awọn ilana ati agbekalẹ ọhun ni wọn pe ni “Consolidated Public Service Salary Structure, Consolidated Research and Allied Institutions Salary Structure Consolidated Police Salary Structure, Consolidated Para-military Salary Structure, Consolidated Intelligence Community Salary Structure, ati Consolidated Armed Forces Salary Structure.”
Bi ẹ ko ba gbagbe, awọn oṣiṣẹ ijọba lawọn ile-ẹkọ giga ati lẹka eto ilera ni wọn ti kọkọ gba ẹkunwo lori owo oṣu ti wọn.












