Ìdá 0.4% péré ló gba máàkì tó lé ní 300 nínú ìdánwò ọdún yìí – JAMB

Eaxm hall

Oríṣun àwòrán, getty images

Ajọ to n ri si idanwọ aṣewọle si ile ẹkọ giga ni Naijiria, JAMB ti kede esi idanwo ọdun 2024 ti awọn akẹkọ ṣe lẹnu lọlọ yii.

Ọga agba ajọ naa, Ishaq Oloyede, lo fi ikede naa sita ni olu ọọfisi ajọ ọhun niluu Abuja.

Gẹgẹ bii ohun to sọ, 1.4 miliọnu ni apapọ iye awọn to ṣe idanwo naa ni ojuko ti iye rẹ to 700 kaakiri Naijiria.

Ọjọ Ẹti, ọjọ kọkandinlogun, oṣu Kẹrin, ọdun 2024 ni idanwo naa bẹrẹ ti wọn si pari rẹ lọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Kẹrin kan naa.

Atupalẹ idanwo JAMB ọdun yii

Ninu awọn 1,989,668 to forukọsilẹ fun idanwo naa, 80,810 ni iye awọn to kuna lati yọju si gbagede idanwo, to n tumọ si pe awọn 1,904,189 lo ṣe idanwo ọhun.

Oloyede ni “ninu awọn 1,842,464 to ṣe idanwo, ida 0.4% pere lo gba maaki to le ni 300 nigba ti ida 24% gba maaki to le ni 200.”

O fi kun pe ida 76% awọn akẹkọọ naa lo gba maaki ti iye rẹ ko to 200.

Amọ o ni ajọ ọhun yoo kede orukọ awon ti maaki wọn pọ julọ ninu idanwo ọhun.

Awọn akẹkọọbinrin pọ ju ọkunrin lọ lọdun yii

Atupalẹ esi idnwo naa fi han siwaju si pe awọn akẹkọọ to jẹ obinrin pọ ju awọn ọkunrin to ṣe JAMB lọdun 2024.

Oloyede sọ pe obinrin 982,393, to jẹ ida 50.6% lo ṣe idanwo naa nigba ti ida 49.4% ṣe idanwo ọhun.

O ni eyii ni igba akọkọ lọpọ ọdun sẹyin ti iye obinrin to ṣe idanwo JAMB yoo pọ ju ọkunrin lọ.