Ẹ̀ wo ànàmọ́ tó ń lé òṣì àti ìṣẹ́ jìnnà sí ẹ̀dá

Aworan

Ara meeriri, mo ri ori olowo lori atẹ ni ọrọ Anamọ to n le isẹ ati osi wọgbẹ yii.

Aarẹ Orilẹede China to n lo saa kẹta lọwọ, ti salaye bi anamọ ti awọn oloyinbo n pe ni Potato, se tan iṣẹ ati aini owo lọwọ ni awọn ilu kereje lorilẹede naa.

Eto adojuti oṣi naa nipa ṣiṣe ọgbin anamọ kekeke ni o n waye ni agbegbe Heibei, lorilẹede China

Lasiko ti akọroyin BBC lọ sibẹ lati lọ ṣe ayẹwo boya lootọ ni opin ti de ba oṣi ati iṣẹ lorilẹede ọhun paapaa ni awọn ilu kereje.

Aarẹ Xi Jinping lo sọ fun wọn nigba naa pe opin yoo de ba iya to n jẹ wọn ti wọn ba le ṣe ipeṣe anamọ.

‘’Lootọ ni anamọ n fopin si iya ati iṣẹ ni agbegbe wa, ti a si dupẹ lọwọ Aarẹ Xi ''

Aarẹ Xi gba wọn nimoran lati ta anamọ naa ni iye owo to gara .

Awọn agbẹ to wa ni ilu Heibei ni lọọtọ ni ohun ti yipada fun awọn ni ilu naa lẹyin ti wọn bẹrẹ si ni ta anamọ.

‘’Lootọ ni anamọ n fopin si iya ati iṣẹ ni agbegbe wa, ti a si dupẹ lọwọ aarẹ Xi to gba wa ni imọran lati ṣe bẹẹ.

‘’Awọn anamọ kekeke naa n mu owo wọle fun wọn paapaa pẹlu bi ijọba ṣe n ṣe ipese awọn ohun ti awọn agbẹ nilo.’’

‘’Owo to wọle ni mo fi n tọju awọn ọmọ mi to wa ni fasiti lati igba ti ọkọ mi ti ku.’’

‘’Nitori awọn ọmọ mi gbọdọ ka iwe de oju ami lai wẹyin wo’’

Amọ awọn araalu naa ni nkan ko fibẹ lọ deede ni ọdun yii nitori ọ gbẹlẹ ko fun wọn ni aaye lati gbin anamọ lọpọ.’’

Bakan naa ni iroyin fi lede pe labẹ ijọba aarẹ Xi ni wọn ti kede opin si iya ati iṣẹ lorilẹede China