Àwọn àjẹ́ ń yọ sí mi lójú oorun láti wá dara pọ̀ máwọn - Ìyá Gbonkan

Oríṣun àwòrán, Facebook
Gbajúgbajà òṣèré Margaret Bándélé Olayinka tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Ìyá Gbonkan tí ṣàlàyé àwọn nǹkan tí ojú rẹ̀ máa ń rí fún ipa tó máa ń kó nínú eré sinimá.
Ìyá Gbonkan nígbà tó ń ṣàlàyé ara rẹ̀ nínú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò lórí ètò kan ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà ni àwọn àjẹ́ máa ń yọ sí òun lójú orun.
Ìgbà àkọ́kọ́ kọ́ nìyí tí gbajúmọ̀ òṣèré yìí máa sọ wí pé àwọn àgbà ti ń da òun láàmú láti wá darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ àwọn.
"Lati aago mejila ni n ki le sun mọ, orogun ni mo maa n yọ lati le ẹni to ba yọ si mi"
Nínú fídíò náà ni ìyá Gbongan tí ń sọ àwọn ìpèníjà to ń kojú nípa ipa tó máa ń kó nínú iṣẹ́ tó yàn láàyò.
"Nígbà tí ṣe eré Kòtò Ọ̀run ni mi ò bá ti sá kúrò láti máa ṣe eré sinimá nítorí ohun tí ojú mi rí."
"Kódà àwọn àgbà máa ń wá bá mi lójú orun lójoojúmọ́ ni."
Ó ní tó bá ti di ago méjìlá òru ni òun kò ti ní lójú orun mọ́ àti pé orógùn ni òun máa ń yọ sí àwọn ẹni náà.

Oríṣun àwòrán, Facebook
Ó fi kun pé òun dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run wí pé ó mú òun borí gbogbo ìpèníjà náà nítorí kò pẹ́ rárá tí àwọn ṣe eré Kòtò Ọ̀run tí àwọn àgbà fi ń yọ sóun.
Ìyá náà tẹ̀síwájú pé ohun tí kò mú òun sá kúrò nídìí eré sinimá ṣíṣe nígbà náà kò kọjá wí pé òun rí wí pé iṣẹ́ ńlá ni òun ṣe nínú eré náà.
Ìyá Gbonkan ṣàlàyé pé nítorí òun ní ìgbàgbọ́ pé Ọlọ́run fẹ́ fi sinimá Kòtò Ọ̀run gbé òun dìde ni òun kò ṣe fi iṣẹ́ sinimá sílẹ̀ lásìkò náà àmọ́ òun kọ́kọ́ sá sẹ́yìn fún ìgbà kan ná.
"Mo ri pé iṣẹ́ ńlá ni mo ṣe nínú eré yìí mi ò sì ṣe é rí, Ọlọ́run lè gbémi dìde àmọ́ mo kọ́kọ́ sá sẹ́yìn."
"Ṣé ní ọjọ́ tí wọ́n lù mí láti ojú orun ni, tí gbogbo ojú mí wú ni mo fẹ́ sọ ní, Ọlọ́run ló ní kí bàbá ọmọ mi wà láyé nígbà náà."
"Wọ́n lù mí pé sẹ̀ àwọn ní kí n wá gba akọ̀yà èmi ń bá àwọn lérí pé èmi ò gbà."
"Mo ní kò sí ní ìran wa, tabiyamọ ló wà ní ìran tiwa."
Nígbà tí a ṣe Kòtò Ọ̀run tán, ti kálukú ló ba
Ìyá Gbonkan tún ṣàlàyé pé kìí ṣe òun nìkan ni ojú òun rí tó lẹ́yìn tí àwọn ṣe sinimá náà tán. Ó ní gbogbo àwọn tí àwọn kópa nínú eré náà ni àwọn rí ìpèníjà kan tàbí òmíràn kódà tó fi mọ́ olóòtú sinimá náà, olóògbé Alhaji Ajileye.
"Wọ́n fì wá ṣùgbọ́n Alhaji Ajileye ní a ò ní dẹ̀yìn àyàfi tí a bá ṣe é débi èrè."
Ó ní òun gbàgbọ́ wí pé àforíjì tí òun ní ni Ọlọ́run fi gbọ́ àdúrà òun tí orúkọ òun fi wá tàn káàkiri ayé nítorí kìí ṣe sinimá yìí ni òun fi bẹ̀rẹ̀ eré.















