Kò sí nǹkan tó máa dá ìkọlù wa sí Rafah dúró - Netanyahu

Oríṣun àwòrán, Reuters
Olotu ijọba orilẹede Israel, Benjamin Netanyanhu ni orilẹede Israel yoo ṣe ikọlu si apa guusu Gaza, Rafah, ti ko si nkankan to le da ikọlu naa duro.
Eyi lo jade lasiko ti igbinyanju pe ki adehun waye pe ki awọn mejeeji juwọ ogun silẹ, ti wọn si tu awọn eeyan to wa ni ahamọ silẹ.
Ninu ipade to ṣe pẹlu mọlẹbi awọn eeyan to wa ni ahamọ, Netanyahu ni oun yoo ṣe ikọlu naa boya adehun waye tabi ti ko ba si adehun.
Ọrọ yii lo jade lẹyin ti US ṣe ikilọ pe ikọlu naa ko gbọdọ waye ayafi ti wọn ti pe bi ko ṣe akoba fun awọn araalu.
Aarẹ Joe Biden, lasiko to n ba Netanyahu lori ẹrọ ibaraẹnisọrọ lọjọ Aiku ni oun ko yi oun pada.
Kini Aarẹ Palestine n sọ lori nkan ti o ti ṣẹlẹ sẹ́yìn?
O le ni idaji eeyan 2.5m Gaza lo wa ni Rafah, to si jẹ pe pupọ wọn lo saa wa sibẹ lasiko ikọlu si agbegbe wọn. Ero pọ ninu ilu naa, ti ọpọ wọn si kigbe pe ko si ounjẹ, omi ati eto ilera.
Aarẹ Palestinian to wa ni West Bank, Mahmoud Abbas ni ikọlu si Rafah ni yo jẹ ajalu nla fun gbogbo ilẹ Palestine ati itan rẹ.
Awọn eeyan kan to ba Reuters sọrọ lọjọ Aje ni o ṣeese ki ikọlu naa ma waye ti adehun ba le waye ni kiakia laarin Hamas ati Israel.
Kini Aarẹ Isreal wa n sọ bayii?
Minisita fun ọrọ oke okun fin Israel, Israel Katz sọ fun ileeṣẹ iroyin Israeli Channel 12 pe ti adehun ba waye , awọn yoo da ikọlu naa duro
Sugbọn lọjọ Isẹgun, Netanyahu ni ko si nnkan to jọ mọ pe ogun ti pari, ati pe ogun naa yoo tẹsiwaju titi Israel yoo fi ri pe gbogbo erongba rẹ wa si imusẹ ni Rafah.
“Ero wọn pe ki a da ogun duro ki a to mu gbogbo erongba wa si imusẹ ni ko ṣeeṣe rara.
“A o wọle si Rafah, a o si ṣekupa gbogbo awọn ọmọ ogun Hamas, boya adehun wa nilẹ tabi ti ko ba si adehun, ti a yoo si ṣe aṣeyọri ni ipari,” gẹgẹ bi atẹjade kan to jade lati ọfiisi Natanyahu.
Ohun ti a tun ri gbọ ni pe awọn mọlẹbi naa rọ Olotu ijọba ati olubadamọran lori eto abo, Tzachi Hanegbi pe ki wọn tẹsiwaju nipa ogun, ki wọn si kọ ẹti ikun si gbogbo ohun ti ajọ agbaye n sọ.
Bakan naa ni ọpọ awọn mọlẹbi lo ṣe iwọde ita gbangba fun ijọba pe ko tọwọ adehun ti yoo ri pe awọn eeyan pada wa si ile.












