Àbúrò mẹ́wàá ni mo pàdánù nínú ìkọlù Israel sí gúúsù Gaza

Aworan obinrin ti wọn pa awọn eeyan rẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Bi ikọlu Israel si Gaza ṣe n tẹsiwaju lojoojumọ ni wọn n paṣẹ fun awọn eeyan lati kuro nilẹ awọn ara Palestine.

Israel jẹ ko di mimọ pe ẹru ẹmi awọn eeyan n ba oun pupọ, nitori pe ko si ibi kankan ti wọn le salọ lati fi ori wọn pamọ si mọ bayii.

Ọsibitu Al Aqsa to wa ni Deir al-Balah, ti sọ pe ko din ni eeyan mọkanlelogun to ku ninu ikọlu to waye laarin gbungbun Gaza.

Obinrin kan to n gbe ni Rafah, iyẹn lẹkun Guusu jẹ ko di mimọ pe ohun ija oloro ti wọn ju lati oke pa mọlẹbi oun mẹwaa.

Bakan naa lawọn ọmọ ogun ilẹ Israel sọ pe awọn ti ṣawari ọna kan ti wọn gbe gba abẹ ilẹ, nibi ti awọn agbebọn n gba ni Rafah, lati fi wọ ilẹ Egypt.

Alakoso ajọ European Union, Charles Michel, ti wa bu ẹnu atẹ lu bi wọn ṣe n ko awọn eeyan maa kuro nilu, nitori pe ibi ti ko si eto aabo ni wọn n dari wọn lọ.

Israel paṣẹ ki wọn ko awọn eeyan kuro nilu, bi ikọlu Rafah ṣe peleke sii

Awọn alaṣẹ ilẹ Israel ti sọ fun ogunlọgọ awọn ara Palestine lati fi Rafah silẹ lai fi asiko ṣofo, pẹlu bi ikọlu awọn ọmọ ogun ṣe n tẹsiwaju ni Guusu Gaza.

Awọn alẹmode ati awọn ọrọ ti wọn n kọ sori awọn ikanni ayelujara ni wọn ti n sọ fawọn araalu lati lọ si awọn ilu to sunmọ wọn bii al-Mawasi, iyẹn nibi ti Israel sọ pe awọn ti ya silẹ fun awọn eeyan lati gbe.

Apa kan ni Rafah, nibi adugbo ti wọn ko awọn ti ogun le kuro si lo ti wa dabi iboju oku pẹlu bi ibẹ ṣe pa lọlọ.

Israel ti wa sọ pe awọn yoo tẹsiwaju lati ṣiṣẹ ni Rafah, lai wo ti ikilọ ti ilẹ Amẹrika ati awọn orileede miran ṣe.