Ilé ìwòsàn já aláìsàn táwọn ẹbí rẹ̀ pa tì síwájú ṣọ́ọ̀bù ọkọ rẹ̀ ní Ibadan

Alaisan ti won ja siwaju soobu oko re

Oríṣun àwòrán, TribuneOnline

Báwo la fẹ́ ṣe èyí sí ni ọ̀rọ̀ tó gba ẹnu àwọn ará àdúgbò Desalu, Odo-Ona ní ìjọba ìbílẹ̀ Ibadan South-West, ìpínlẹ̀ Oyo nígbà tí àwọn òṣìṣẹ́ ilé ìwòsàn tí a kò tíì mọ orúkọ rẹ̀ ṣe gbé aláìsàn kan lọ sí iwájú ṣọ́ọ̀bù ọkọ rẹ̀.

Aláìsàn náà, tí wọ́n pè orúkọ rẹ̀ ní Blessing Ayeni ni àwọn òṣìṣẹ́ ilé ìwòsàn ọ̀hún lọ já kalẹ̀ síwájú ṣọ́ọ̀bù ọkọ rẹ̀ lọ́jọ́ Ẹtì, ọjọ́ Kọkàndínlógún oṣù Kìíní ọdún 2024.

Gẹ́gẹ́ bí ohun tí àwọn ènìyàn tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣojú wọn ṣe sọ, àwọn òṣìṣẹ́ ilé ìwòsàn náà ní láti ọdún tó kọjá ni ọkọ àti àwọn ẹbí Blessing kò wá bèèrè rẹ̀ ni ilé ìwòsàn mọ́.

Wọ́n ní ìdí nìyí tí àwọn fi gbe lọ sí ẹnu ọ̀nà ṣọ́ọ̀bù ọkọ rẹ̀ níbi tó ti ń ta ọtí nítorí kò sí nǹkan tí àwọn lè ṣe lórí ọ̀rọ̀ Blessing mọ́.

Ilé iṣẹ́ ìròyìn TribuneOnline ní ìwádìí àwọn fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé àwọn òṣìṣẹ́ ilé ìwòsàn ọ̀hún sọ fún àwọn ará àdúgbò náà pé ọ̀pọ̀ ìgbà ni àwọn tí yọjú sí ọkọ Blessing ní ṣọ́ọ̀bù pé kó wá san owó tí àwọn fi ń tọ́jú ìyàwó rẹ̀ àmọ́ tí kò ní yọjú sí àwọn rárá.

Wọ́n tún ní àwọn ẹbí Blessing kọ́kọ́ máa ń yọjú sí ilé ìwòsàn àmọ́ tí wọn kò wá mọ́ nígbà tó yá.

TribuneOnline ṣàlàyé pé nígbà tí àwọn dé àdúgbò náà, Blessing ṣì wà ní ilẹ̀ tí àwọn òṣìṣẹ́ ilé ìwòsàn náà ja sí lábẹ́ oòrùn, tí àwọn ará àdúgbò sì ń wò ó níran.

Àwọn ará àdúgbò ṣàlàyé pé ìdí tí àwọn kò fi súnmọ́ Blessing ni pé àwọn òṣìṣẹ́ ilé ìwòsàn tí wọ́n gbe kalẹ̀ ní kí àwọn súnmọ nítorí pé àìsàn tó ń ṣe é máa ń ràn.

Gbogbo ìgbìyànjú àwọn akọ̀ròyìn láti rí ọkọ Blessing ló já sí pàbó, ṣọ́ọ̀bù rẹ̀ wà ní títì pa lásìkò tí à ń kó ìròyìn yìí jọ.