Abiodun, Sule, Sani, Oborevwori, àtàwọn gómìnà méjì míràn borí ìgbẹ́jọ́ ìbò ní ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ ní Nàìjíríà

awon gomina to wole ibo pelu idajo kootu to ga julo

Oríṣun àwòrán, others

Afi bi ẹni pe ajọdun idajọ igbẹjọ awọn ẹsun gbogbo to jẹyọ lori idibo gomina to kọja lorilẹede Naijiria waye loni ni iwaju ile ẹjọ to ga julọ lorilẹede Naijiria.

Ọjọ Ẹti ni ile ẹjọ to ga julọ lorilẹede Naijiria fi idajọ rẹ si lori awọn ẹjọ kotẹmilọrun to de iwaju rẹ tako ibo to gbe awọn gomina ipinlẹ mẹrin kan de ipo lasiko eto idibo apapọ to waye lorilẹede Naijiria lọdun 2023.

Idajọ lori ẹjọ to tako iyansipo awọn gomina ipinlẹ Ogun, Kaduna, Delata ati Nasarawa waye niwaju adajọ agba Kudirat Kekere-Ẹkun.

Adajọ agba Kekere Ẹkun ni ko si idi lati doju ibo to gbe Abiodun, Sule, Sani, Oborevwori wọle gẹgẹbi gomina ni ipinlẹ Ogun, Nasarawa, Kaduna ati Delta ni ṣiṣẹ n tẹle bolẹ nitori awọn ẹri to wa niwaju ileẹjọ agba naa fihan pe lootọ awọn laaralu dibo yan.

Uba Sani bori gẹgẹ bi gomina Kaduna

gomina ipinle Kaduna

Oríṣun àwòrán, others

Lori ẹjọ tani gomina ipinlẹ Kaduna?, ile ẹjọ to ga julọ lorilẹede Naijiria fọwọ si idajọ ile ẹjọ kotẹmilọrun to ni Uba Sani lo wọle sipo gomina ni ipinlẹ naa.

Isah Ashiru ti ẹgbẹ oṣelu PDP tako idajọ naa lo fi kọri si ile ẹjọ agba naa.

Ile ẹjọ to ga julọ ni Naijiria ni Nasir Idris bori lo bori ni Kebbi

Gomina Nasir Idris ti Kebbi

Oríṣun àwòrán, others

Bakan naa ni ile ẹjọ to ga julọ ni Naijiria tun da ẹjọ kotẹmilọrun ti Aminu Bande ti ẹgbẹ oṣelu PDP pe tako Gomina Nasir Idris gẹgẹbi gomina Kebbi nu.

Ile ẹjọ naa ni ẹjọ naa ko lẹsẹ nilẹ rara ati rara ni.

Ipinlẹ Gombe: Gomina Inuwa Yahaya f’ẹyin PDP janlẹ

Lẹyin gbogbo awuyewuye ati bi Gomina Yahaya Inuwa ṣe paara kootu lori atako ti Jibrin Barde, ondupo gomina ninu PDP foju rẹ ri, kootu to ga julọ ti fonté lu u pe Inuwa , ọmọ ẹgbẹ APC ni gomina Gombe tootọ.

Jibrin Barde fẹsun kan Inuwa Yahaya pe o ṣe magomago ibo nijọba ibilẹ mẹsan-an ninu mọkanla to wa ni Gombe, lasiko ibo to waye lọjọ kejidinlogun oṣu kẹta ọdun 2023.

Adajọ Kudirat Kekere Ẹkun nigba to n gbe idajọ kalẹ, ṣalaye pe ẹjọ ti Jibrin Barde pe ko lẹsẹ nilẹ, o si da a nu bii omi iṣanwọ.

Ipinlẹ Nasarawa: Gomina Abdullai Sule gba ipo rẹ pada

Gomina Sule ati alatako rẹ Ombugadu

Oríṣun àwòrán, others

Alatako ti Gomina Abdullai Sule ni, nipinlẹ Nasarawa ko ju oludije fun ipo gomina ninu ẹgbẹ PDP, David Ombugadu.

Gbara ti Sule jawe olubori ninu ibo ọdun to kọja ni Ombugadu ko ti gba.

Tribuna ipinlẹ naa da Ombugbadu lare pe oun lo bori,ṣugbọn ile-ẹjọ Ko-tẹ-mi-lọrun yi i pada, o ni Sule lo bori.

Ombugadu ko tun gba, o gba kootu to ga ju lọ.

Adajọ Kudirat Kekere Ekun dajọ naa lọjọ Ẹti, o si paṣẹ pe ki Sule Abdullahi maa jẹ gomina rẹ lọ ni Nasarawa.

Ipinlẹ Delta: Sheriff Oborevwori, PDP, ṣẹgun APC

Gomina Sheriff Oborevwori

Oríṣun àwòrán, others

Gomina yii naa koju atako latọdọ awọn ẹgbẹ oṣẹlu alatako ni ipinlẹ Delta ti wọn gbe e lọ si Tribuna ati ileẹjọ Kotẹmilọrun, wọn si pada pari ẹ si kootu to ga julọ.

Ibo to le ni ẹgbẹrun mẹrindinlogoji (36,0234) ni Sherriff ni, Senetọ Ovie Omo-Agege, ọmọ ẹgbẹ APC ti wọn jọ dije ni ibo 24,0229, nigba ti Kennedy Pela, ọmọ ẹgbẹ Labour ni ibo 48,047.

Pẹlu eyi, wọn pe ẹjọ si kootu nipele-ipele, ṣugbọn lopin gbogbo rẹ, Sheriff Oborevwori, ọmọ ẹgbẹ PDP bori wọn nile ẹjọ to ga julọ.

Dapọ Abiọdun jawe olubori nileẹjọ to ga julọ, Adebutu fìdírẹmi
Gomina Dapo Abiodun

Ile-ejọ to ga julọ lorilẹ-ede yii ti paṣẹ pe Gomina Ọmọọba Dapọ Abiọdun lo jawe olubori ninu idibo sipo gomina Ogun to waye lọjọ kejidinlogun, oṣu kẹta ọdun 2023.

Adajọ Tijani Abubakar to gbọ ẹjọ naa, fidi ẹ mulẹ pe Ọladipupọ Adebutu, ondije dupo gomina Ogun ninu ẹgbẹ PDP to pe ẹjọ yii kọ lo wọle ibo naa.

Ninu idajọ to waye lọjọ Ẹti, ọjọ kọkandinlogun oṣu kin-in-ni 2024, ni Adajọ Abubakar ti sọ pe ẹjọ ti Adebutu pe ko lẹsẹ nilẹ.

Igbimọ adajọ ẹlẹni marun-un, ti Onidajọ Inyang Okoro ṣaaju wọn lo jokoo lori ẹjọ naa, k’Adajọ Tijani Abubakar too da a.

Tẹ o ba gbagbe, Oloye Adebutu to pe Gomina Abiọdun lẹjọ lori ibo naa, ka awọn ẹsun bii ibo rira, aikunju oṣuwọn ati aiṣododo si Dapọ Abiọdun lẹsẹ.

Adebutu ni ki wọn fagile ibo to gbe Dapọ depo gomina Ogun lẹẹkeji.

Oṣu kọkanla ọdun 2023 ni ile-ẹjọ Ko-tẹ -mi-lọrun fagile ẹjọ ti Adebutu pe, kile-ẹjọ to ga julọ too paṣẹ pe k’Abiọdun maa ba ijọba rẹ lọ bayii.