Ọbalayé fi owó dá àlàbọrùn fún K1, àjọ NOA bá ní kó ṣe pẹ̀lẹ́, títàbùkù Naira ń rán ni lọ s’ẹ́wọ̀n

Kwam 1

Oríṣun àwòrán, Abiola Orisile

Ajọ to n ṣe idanilẹkọo fun araalu lori iwuwasi, National Orientation Agency (NOA), ti fi ohun ranṣẹ si Olu ti Owode Egba nipinlẹ Ogun, Ọba Aremo Sowemimo lẹyin to ni o ṣe owo naira baṣubaṣu.

Ṣaaju ni fidio kan ti kọkọ ṣafihan bi ori ade naa ṣe n na owo naira fun olorin kan lasiko to n ṣajọyọ ọdun kẹtala rẹ lori alefa.

Owo N1,000 ni ori ade naa so pọ, eyii to gbe si ọrun olorin ọhun bii ẹgba ọrun.

Ẹwẹ, ninu atẹjade kan, ọga agba NOA, Lanre Issa-Onilu, bu ẹnu atẹ lu ohun ti Olowode Egba ṣe.

Issa-Onilu sọ pe ko bojumu bi ọba naa ṣe n na owo nitori o jẹ abuku fun owo Naijiria, o si lodi si ofin.

Gẹgẹ bii ohun to sọ, ninu owo loju agbo bayii le gbe eeyan de ọgba ẹwọn.

Atẹjade naa jẹ ọkan lara ọna ti NOA fi n fa araalu leti lati bọwọ fun owo naira, eyii to jẹ ọkan lara awọn ohun apejuwe orilẹ-ede Naijiria.

NOA wa kilọ fun awọn ọba alade, to fi mọ ọba Sowemimo, lati ri gẹgẹ bii ojusẹ wọn lati maa bọwọ fun owo naira.

Gẹgẹ bii ohun ti ọga agba NOA sọ, ijiya nla lo wa fun ẹnikẹni to ba n tabuku owo naira.

Lara titabuku naa si ni nina owo ọhun loju agbo.

Bo tilẹ jẹ pe o ni ọba alade ọhun jẹbi titabuku owo naira, o rọ ori ade naa lati ṣe idanilẹkọọ fun awọn eeyan rẹ nipa ijiya to wa fun ṣiṣe bẹẹ lọjọ iwaju.