Wo ọmọ Yorùbá yìí tó lè sọ èdè mẹ́jọ míràn

Ọgbẹni Adedeji Odulesi jẹ ọmọ ilẹ Yoruba ti o le sọ ede mẹjọ gbako.
Lara awọn ede ti Ọgbẹni Odulesi n sọ yekeyek ni ede Gẹẹsi, Pidgin, Yoruba, Igbo, Hausa ati French,iyẹn ede awọn ara faranse.
Bakan naa lo tun le sọ ede Geran to jẹ ede awọn ara orilẹede Germany, ede Spanish to jẹ ede awọn eeyan orilẹede Spain ati ede ilu ibinibi rẹ, iyẹn Ijẹbu.
Ninu ifọrọwerọ rẹ pẹlu BBC News Yoruba, Ọgbẹni Adedeji Odulesi ni ilu Warri ni awọn obi oun bi oun si ni ipinlẹ Delta, lẹkun aringbungbun gusu Naijiria.
Bi iṣẹ ṣe n gbe awọn obi mi kaakiri ilu lo mu ki n gbọ awọn ede kan – Adedeji Odulesi

Oríṣun àwòrán, others
O fi kun un pe gbigbe ti iṣẹ n gbe awọn obi oun kiri lo ṣokunfa bi oun ṣe gbọ pupọ ninu awọn ede ti oun gbọ.
Fun apẹrẹ, o ni nigba ti iṣẹ gbe ilu Sokoto ni oun kọ ede Hausa; nigba ti iṣẹ si tun gbe wọn lọ si ipinlẹ Imo ni oun gbọ ede Igbo.
Amọṣa ifẹ oun si ede lo mu ki oun kọ awọn ede bii French, Spanish ati German.
Amọṣa ede ibinibi rẹ ni ede Ijẹbu.
Oríṣiríṣi èdè tí mo lè sọ ló sọ mí di ìlúmọ̀ọ́ká

O ni lootọ ko rọrun lati kọ awọn ede yii ṣugbọn oun n rii pe oun sa ipa lati sọ awọn ede naa nitori pe oun ko raye fun ẹyamẹya.
O ni sisọ ede pupọ fun oun ni anfani lati ba awọn eekan ṣe pọ. Bakan naa lo fun oun ni anfani lati lowo lọwọ pẹlu.
O fi kun un pe o ti sọ oun di ilumọọka ti ọpọ si ti pade ti wọn si kan sara si oun nitori ọpọ ede ti oun sọ ri loju wọn nibi kan tabi nibi ayẹyẹ kan.






