Funke Akindele ṣàlàyé àjọṣepọ̀ láàrín sinimá 'A Tribe called Judah' àti ìyá tó bíi lọ́mọ

Ilumọọka oṣere sinima ni Naijiria, Funkẹ Akindele ti ọpọ eeyan mọ si ‘Jẹnifa’ ti ṣalaye pe kii ṣe itan iya oun loun fi kọ sinima ‘A Tirbe called Judah’ to n mi igboro lọwọ kaakiri agbaye bayii.
Funkẹ Akindele ni baba ọtọtọ ni Jedidah to wa ninu sinima naa bi ọmọ Marun un to bi fun.
O ni ni ti iya to bi oun o, awọn mẹrin lo bi, ọkọ kan ṣoṣo lo si bi awọn mẹrẹrin fun; nitori naa iyatọ gedegbe wa nibẹ.
“Idi niyẹn ti mo fi fi sinima naa sọri iranti iya mi nitori iya mi jẹ ẹni to fẹran ọmọ gan.”
Amọṣa o ni afarajọ to wa laarin Jedidah ati iya oun ni pe awọn mejeeji ni kii fi ọmọ wọn ṣere.
Funkẹ Akindele sọ ọrọ yii ninu ifọrọwerọ pẹlu BBC News Yoruba nipa aṣeyọri sinima naa.
‘A Tribe called Judah’ ni sinima akọkọ lorilẹede Naijiria ti yoo pa biliọnu kan naira wọle.
Funkẹ Akindele ni inu oun dun pupọ pe sinima naa ṣe aṣeyọri. O fi kun un pe gbogbo sinima ti oun ba kọ ni oun ti ni i lọkan pe o gbọdọ ṣe aseyọri.






