Ìrírí mi pẹ̀lú àwọn ọlọ́pàá lójú pópó ló sọ mi di 'Adisa o ní Taxi'

Àkọlé fídíò, Iṣẹ́ agbóhùnsáfẹ́fẹ́ ni mo n ṣe kí n tó di Adisa o ni Taxi
Ìrírí mi pẹ̀lú àwọn ọlọ́pàá lójú pópó ló sọ mi di 'Adisa o ní Taxi'

Ilumọọka alawada ori ayelujara, ti a tun mọ si 'skit maker', Ọgbẹni Musiliu Adisa Sanni, ti sọ pe iṣẹ agbohunsafẹfẹ ni oun n ṣe, ki oun to o di alawada.

Ọgbẹni Sanni to jẹ ọmọ bibi ilu Abeokuta nipinlẹ Ogun, sọ fun BBC ninu ifọrọwanilẹnuwo kan pe aimọye ọdun ni oun fi ṣe iṣẹ naa, ki oun to pa ọna da.

O ni ile ẹkọ fasiti ti oun ti n kẹkọọ ni oun ti n bọ lọjọ kan, nigba ti oun ṣe kongẹ awọn ọlọpaa to n yẹ ọkọ wo lojupopo.

Sanni ti awọn ololufẹ rẹ mọ si 'Adisa o ni Taxi' bayii, sọ pe awada ti oun da pẹlu ẹni ti awọn jọ wa ninu ọkọ lọjọ naa, nipa bi ọlọpaa ṣe da wọn duro, lo pada sọ oun di ẹni to n fi awada ṣiṣe ṣiṣẹ aje.

Adapọ ede Ẹgba ni Adisa o ni Taxi fi ma n ṣe awọn awada rẹ, paapaa awọn iparojẹ to ma n wa ninu bi awọn eniyan ilẹ Ẹgba ṣe ma n sọrọ, eyi to ma n mu ki ẹlomii gbọ nnkan to yatọ si nnkan ti ẹni to n sọrọ ni lọkan.

O ma n fi awọn awada rẹ sọrọ lori bi igbeaye awakọ takisi ṣe n ri lojoojumọ ati awọn iriri wọn pẹlu ero ọkọ, lẹnu iṣẹ oojọ wọn.

Oriṣirisi awọn gbajumọ oṣere Nollywood, ni Ọgbẹni Sanni ti ba ṣe 'skit' papọ.