Adeboye, Oyedepo, àti àwọn pásítọ̀ mìí sọ àsọtẹ́lẹ̀ lórí bí ọdún 2024 yóò ṣe ri

ADeboye, Oyedepo ati Olukoya

Oríṣun àwòrán, Others

Bi ọdun 2023 ṣe kasẹ nilẹ, ti ọdun tuntun 2024 wọle wẹrẹ, awọn ojiṣẹ Ọlọrun, paapaa ninu ijọ awọn ọmọlẹyin Kristi, ti sọ asọtẹlẹ nipa awọn nnkan ti wọn ni igbagbọ pe yoo ṣẹlẹ ninu ọdun tuntun.

Nibi eto isin aisun ọdun tuntun ni pupọ ninu wọn ti kede awọn asọtẹlẹ naa fun awọn ọmọ ijọ wọn.

Lara awọn ojiṣẹ Ọlọrun to sọ asọtẹlẹ ni Pasitọ Agba ijọ RCCG, Enoch Adeboye, oludasilẹ ijọ Living Faith, Biṣọọbu David Oyedepo, ati awọn miran.

Eyi ni diẹ niju awọn asọtẹlẹ wọn:

*Nǹkan yóò kọ́kọ́ le kò tóó dẹ̀rọ̀ ní 2024 yìí ní Nàìjíríà- Pásítọ̀ Adébóyè

Pasitọ agba ijọ Irapada, The Redeemed Christian Church Of God, Pasitọ Enoch Adejare Adeboye, ti sọ pe nnkan yoo kọkọ nira ni 2024 lorilẹ-ede Naijiria ko too dẹrọ pada.

Ninu isin irekọja sinu ọdun tuntun 2024 to waye ni ilẹ ipagọ Irapada ṣọọṣi naa to wa ni Mowe ni Adeboye ti sọ pe 'nnkan yoo kọkọ le ni 2024'.

‘’Iji n ja, ẹ gbadura s’Oluwa ko jẹ kiji naa fẹ rere fun yin’’

Pasitọ Adeboye
Àkọlé àwòrán, Pasitọ Adeboye

Awọn aṣiri ikọkọ yoo tu

Yatọ si ti ọrọ aje, Pasitọ Adeboye sọ asọtẹlẹ pe awọn aṣiri ikọkọ kan yoo di mimọ, bẹẹ lo ni ọna yoo la fawọn eeyan kan ti wọn ko jẹ nnkan kan bayii, ṣugbọn ti wọn yoo lu aluyọ kọdun 2024 too pari.

‘’Oluwa yoo da si gbogbo ibi to nira.

Ẹ gbaradi lati ri ọna abayọ rẹpẹtẹ lọdun yii.

Alaafia yoo de fawọn eeyan ti wọn ni aisan ikọ seemi-seemi, jẹjẹrẹ, ifunpa giga ati itọ ṣuga gẹgẹ bi Baba Adeboye sẹ sọ.

2024 lawọn eeyan yoo bọ loko ẹru gbogbo -Biṣọọbu Oyedepo

Bisoobu Oyedepo

Biṣọọbu David Oyedepo, ti ijọ Living Faith naa ti gbe asọtẹlẹ rẹ jade, eyi to si fi ṣiwaju ni pe gbogbo ogun imunilẹru ati imunisin yoo dopin ni 2024.

Oyedepo sọ awọn asọtẹlẹ rẹ ni olu ijọ naa to wa ni Ota, nipinlẹ Ogun.

Oyedepo sọ pe ọdun tawọn eeyan yoo bọ loko ẹru wọn ree.

Bakan naa lo sọ pe 2024 yii ni Oluwa yoo mu awọn eeyan rẹ lọ sibi giga ti wọn ti n reti tipẹ.

Yatọ si asọtẹlẹ, Biṣọọbu Oyedepo tun gba awọn eeyan ni imran lati ma sẹ ro aropin lori igbeaye wọn.

O ni "igba ti ile ijọsin mi ṣi kere, mi o ki n ri i bii pe o kere. Ohun teeyan ba n ri ni yoo sọ bo ṣe maa to laye. Asiko ti to fun ọ bayii lati maa ri ara rẹ nibi giga.

"Ẹni to n foju oniya wo ara rẹ ko ni i ri nnkan ọpọ jẹ.

‘’Ọdun yii l’Ọluwa yoo mu gbogbo aṣẹgun to pamọ han sita gbangba. 2024 yii lopin aisan ati idaamu, ko ni i si awọn aarẹ buruku mọ’’

Tibi-tire lo wa ninu 2024 – Pasitọ Olukọya

Ibi ati ire ni yoo rin papọ lọdun 2024 gẹgẹ bi aṣotẹlẹ ti Pasitọ agba ijọ Mountain of Fire and Miracles Ministries, Dokita Daniel Olukọya fi sita.

Ọdun to ya kankan to si kun fun iyọnu ni 2024 gẹgẹ bi Pasitọ Olukọya ṣe ṣapejuwe rẹ.

O rọ awọn ọmọ Naijiria pe ki wọn tẹlẹ ilana ti wọn yoo fi la ọdun yii ja.

Bakan naa ni Olukọya sọ pe daadaa n bẹ ni 2024, eyi ti yoo ṣilẹkun anfaani fawọn ọmọ ijọ rẹ.

‘’ Ọpọlọpọ nnkan lo wa ni 2024 yii ta a le dunnu nipa ẹ, ọpọ lo si tun wa lati kọminu nipa ẹ pẹlu.

‘’Ọrọ 2023 dabi ẹni to n sare ijẹ ni, ti 2024 waa gbagi lọwọ rẹ, iyatọ to wa nibẹ naa ni pe 2024 yoo ni lati sare ju 2023 lọ.

"Fun idi eyi, gbogbo iṣẹlẹ tẹ ẹ ri ni 2023 naa ni yoo wọ 2024, afi ka ronu ka si rin ilana ẹmi lati ṣẹgun. "

Pasitọ Daniel Olukọya

Igbiyanju Tinubu lorii Naijiria ko ni i yọ to bo ṣe ro pe yoo ri- Primate Elijah Ayọdele

Primate Elijah Ayodele (Inri)

Oríṣun àwòrán, @Facebook

Ṣaaju awọn asọtẹle awọn ile ijọsin yooku ni Primate Elijah Ayọdele, ti ṣọọṣi INRI ti gbe tiẹ jade.

Ninu rẹ lo ti sọ pe igbiyanju Aarẹ Bọla Tinubu lati yi Naijiria pada si rere lẹka ọró-aje ko ni i yọ to bo ṣe lero.

O ni ajẹbanu yoo pọ ninu iṣakoso yii, ojuṣaaju yoo wa pẹlu ẹlẹyamẹya.

Primate Ayọdele sọ ninu asọtẹlẹ rẹ pe awọn igbimọ ọlọtẹ kan yoo tilẹ fẹẹ gba ijọba mọ Aarẹ Tinubu lọwọ. Ko ma baa ri bẹẹ, pasitọ yii sọ pe adura gidi ni.

Bakan naa lo ni ki awọn eeyan gbadura tako aisan ati iku laarin awọn oloṣelu ati awọn to n ṣe ijọba, to fi mọ ijinigbe jakejado Naijiria.