'Kàkà ká fi ààyè gba àwọn Gay, ẹ yá a di ìrànlọ́wọ́ yín mú'

Oríṣun àwòrán, AFP
Aarẹ orilẹede Burundi, Evariste Ndayishimiye ti ni ki awọn araalu ma sọko mọ awọn ọkunrin to n kopa ninu ibasepọ akọ si akọ ati pe igbesẹ yii ko ni lodi si ofin.
Ninu ifọrọwerọ kan to se pẹlu awọn akọroyin lọjọ Ẹti, ọjọ kọkandinlogun, oṣu Kejila, ọdun 2023, Aarẹ Ndayishimiye jẹ ko di mimọ pe ki awọn orilẹede to lagbara lagbaye di iranlọwọ ti wọn ba fẹ ṣe fun Burundi mu, ti o ba jọmọ pe ki wọn fi aye gba ibalopọ akọ si akọ ni orilẹede naa.
Aarẹ ni iwe mimọ Bibeli fi di rẹ mulẹ pe Ọlọrun lodi si iru ibasepọ bẹ, ti oun ko si ni fi aye gba iwa naa lorilẹede Burundi.
“Fun emi, mo ro pe ti a ba ri irufẹ awọn eeyan bẹ ni Burubdi, o yẹ ka mu wọn lọ paapa isere, ka si sọ wọn loko, ti eyi ko si ni lodi sofin,” Aarẹ salaye.
Ndayishimiye ni ibasepọ akọ si akọ yii lo da bi pe ki eeyan mu ọkan laarin Ọlọrun ati satani.
“To ba fẹ mu Satani, lo si orilẹede mii, ko si lọ ma gbe nibẹ ati fun awọn to n tiraka lati lọ si awọn orilẹede yii lati kọ awọn iwa yii, ki wọn gbiyanju lati wa si ile pada pẹlu iwa naa.
Ibaṣepọ akọ si akọ ati abo si abo lo jẹ ibaṣepọ to lodi sofin orilẹede Burundi, ti ijiya rẹ si jẹ ẹwọn ọdun meji gbako.
Ninu oṣu kẹjọ, eeyan meje ri ẹwọn he lẹyin ti ile ẹjọ kede pe wọn jẹbi ẹsun ibasepọ akọ si akọ.
Bakan naa, ni ila oorun Afrika ninu oṣu Karun un, Uganda gbe ofin to tako ibaṣepọ akọ si akọ tabi abo si abo, ti ijiya rẹ si jẹ iku.
Awọn ẹgbẹ ajafẹtọ ọmọniyan ti gbe ijọba lọ si ile ẹjọ lori ofin naa.















