Àwọn ajínigbé yabo mọ́ṣálááṣí l’Ogun, wọ́n jí Imaamu àti ẹnìkan gbé lọ

Aworan CP Alamutu Abiodun

Oríṣun àwòrán, Ogun Police Command/X

Iroyin to tẹ wa lọwọ lo fidi rẹ mulẹ pe awọ ajinigbe mẹjọ yabo mọṣalaaṣi kan nipinlẹ Ogun nibi ti wọn ti ji Imaamu ile ẹkọ ede Larubawa Muhadul-iftai-wa-sadah Institute of Arabic and Islamic studies, Murithador Sadullahi Akanho Olamide, lọ.

Bakan naa ni wọn tun ji oniṣowo kan, Olayemi Arasi, kan naa lọ pẹlu.

Ni agbegbe Lufuape lẹgbẹ ilu Sagamu ni a gbọ pe iṣẹlẹ ọhun ti waye.

Amọ, iroyin ti fidi rẹ mulẹ pe Imaamu ati oniṣowo ọhun ti gba ominira lẹyin ti wọn ti wa nin akata awọn ajinigbe fun ọjọ mẹta.

Awọn ẹbi awọn eeyan ti wọn ji gbe sọ pe awọn ajinigbe fi wọn silẹ lẹyin ti wọn gba owo.

Ṣugbọn agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Omolola Odutola ni oun ko mọ nknakan nipa sisan owo ransọọmu.

Odutola fi dawọn araalu loju pe iṣẹ iwadii ọlọpaa ti bẹrẹ lati fi ọwọ ofin mawọn ajinigbe ọhun.

O fikun ọrọ rẹ pe ileeṣẹ ọlọpaa ko ni sinmi nipa gbigbogun ti iwa ọdaran nipinlẹ Ogun.

Lori ọrọ tawọn eeyan kan sọ pe o ṣeeṣe ko jẹ pe ẹya Fulani lawọn ajinigbe ọhun lati ipinlẹ Niger, Odutola ni ko si ohun kan ileeṣẹ ọlọpaa pẹlu ẹya ọdaran.

O ni iṣẹ ọlọpaa ni lati mu ọdaran to ba ṣiṣẹ laabi lawujọ.