Àwọn gómìnà ilẹ̀ Yorùbá ṣe àgbékalẹ̀ ìgbìmọ̀ kan fún ètò ìsìnkú Akeredolu

Aworan Rotimi Akeredolu atawọn gomina ilẹ Yoruba

Oríṣun àwòrán, Arakunrin Rotimi Akeredolu/Facebook

Awọn gomina ipinlẹ Yoruba lapa iwọ-oorun guusu Naijiria ti gbe igbimọ kan dide ti yoo ṣiṣẹ pọ pẹlu ẹbi gomina ipinlẹ Ondo to di oloogbe, Arakunrin Rotimi Akeredolu.

Gomina Dapo Abiodun ipinlẹ Ogun lo fidi ọrọ yii mulẹ nigba to ṣabẹwo ibanikẹdun si ile oloogbe pẹlu awọn akẹgbẹ rẹ niluu Ibadan lọjọ Ẹti.

Nigba to n sọrọ lorukọ awọn gomina ipinlẹ Yoruba yoku, Ọmọba Abiodun ṣapejuwe Akeredolu gẹgẹ bi ẹni to ṣe fi ọkan tan, ati pe ki i beṣu bẹgba lati sọ eyi to jẹ otitọ ọrọ lori ohun to ba n lọ lawujọ.

‘’Akinkanju ọkunrin ni Akeredolu, o ja fun fita fita pe ki aarẹ Naijiria wa lati apa guusu.

Kii figba kan bọ ikan ninu, o ṣiṣẹ takun takun lori igbiyanju lati ri pe ẹgbẹ awọn gomina ilẹ Yoruba fidi mulẹ daadaa.

Oun gan an ni alaga ẹgbẹ awọn gomina ipinlẹ Yoruba titi to fi dagbere faye.

Olori gbogbo wa ni o jẹ, a o si ṣe afẹri rẹ gan an,’’ gomina Abiodun lo sọ bẹẹ.

Oloye Abiodun ko ṣai sọ fun ẹbi Akeredolu wi pe ‘’a fẹ ki ẹ ri wa gẹgẹ bi ara yii lori ọrọ iku Akeredolu.

O wu wa lati kopa ninu gbogbo eto isinku Akeredolu, a o gbe igbimọ kan dide ti yoo ni aṣoju lati ipinlẹ ilẹ Yoruba kọọkan.

Ohu n ti a fẹ ni pe a fẹ fun olori wa to di oloogbe ni eto isinku to yẹ.

Awa gomina ilẹ Yoruba wa sibi lonii ni orukọ idile wa, lorukọ ijọba ti n ṣe akoso rẹ ati lorukọ gbogbo ọmọ ilẹ Yoruba lati kẹdun pẹlu ẹbi Akeredolu atawọn eeyan ipinlẹ Ondo.

Adura wa ni pe ki Eleduwa fori ẹṣẹ rẹ jin in ki o si sun laya Olugbala rẹ.

Bakan naa ni a gbadura pe ki Ọlọrun tu iyawo, awọn ọmọ, ẹbi atawọn eeyan ipinlẹ Ondo ninu.’’