Wo ọjọ́ tí ìjọba yóò ti apá kan afárá Third Mainland pa l’Eko lóṣù tó ń bọ̀

Aworan afara Third Mainland

Oríṣun àwòrán, BBC/AYO BELLO

Ijọba apapọ yoo ti apa kan afara Third Mainland lati Iyana Oworonshoki si Adeniji Adele pa fun atunṣe lọjọ kẹsan an oṣu Kinni ọdun 2024.

Adari akanṣe iṣẹ fun ijọba apapọ, Onimọ-ẹrọ Arabinrin O.I. Kesha lo fọrọ yii lede ninu atẹjade kan to fi sita.

Arabinrin Keisha ni titipa apa kan afara naa ṣe pataki lati le ṣe iṣẹ naa daadaa.

Ni ago mọkanla aarọ ọjọ Iṣẹgun ni ijọba yoo ti afara naa ti iṣẹ yoo si bẹrẹ ni pẹrẹu.

Wo awọn ọna mii ti o le gba nigba ti wọn ba ti apa kan afara Third Mainland pa

i. Ijọba rọ awọn olugbe ilu Eko ti wọn n lo afara Third Mainland lati gba Ojota lopopona Ikorodu lọ si Funsho Williams Avenue si afara Eko Bridge si Apogbon lọ si CMS.

ii. Ẹ tun le gba Ojota lọ si Jibowu si Yaba, Oyingbo lọ si Iddo si Carter Bridge lọ si CMS.

iii. Ọna mii ti ẹ tun le gba ni Gbagada si Anthony lọ si Funsho Willaims lọ si Eko Bridge-Apogbon lọ si CMS.

Ijọba tun rọ awọn awakọ lati fọwọ sowọpọ pẹlu awọn oṣiṣẹ to n dari ọkọ lasiko naa ki inira maa baa le pọ fawọn eeyan lasiko naa.

Nigba ti o n ki awọn olugbe ilu Eko fun ifọwọsowọpọ wọn ati ifarada wọn lati ẹyin wa, Arabinrin Keisha rọ wọn pe wọn tun ni lati ni ifarada naa sii lasiko yii.

Afara Third Mainland ni afara to tobi julọ ṣikeji ni ilẹ Afirika eleyii to so iyangbẹ ilẹ ilu Eko mọ erekusu ilu naa.

Mẹẹli meje ati abọ ni afara Third Mainland fi gun eyi to jẹ ki o jẹ afara to gun julọ ni apa guusu ilẹ Afirika.

Ọdun 1990 ni ijọba ologun Naijiria labẹ aṣẹ Ọgagun fẹhinti Ibrahim Babangida kọ afara naa.