Adegboye Onigbinde akọ́nimọ̀ọ́gbá Super Eagles tẹ́lẹ̀ jáde láyé lẹ́ni ọdún 88

Akọnimọọgba Super Eagles tẹlẹ, Adegboye Onigbinde, wọ aṣọ akọnimọọgba lori papa pẹlu awo loju rẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Akọnimọọgba ẹgbẹ agbabọọlu Super Eagles orilẹede Naijiria tẹlẹ, Adegboye Onigbinde, ti jade laye lẹni ọdun mejidinlaadọrun un.

Bolade Adesuyi to jẹ ọkan lara ẹbi baba Onigbinde lo kede iku rẹ.

Adesuyi sọ ninu atẹjade kan to fi sita wi pe ''pẹlu ọpẹ si Ọlọrun ni a kede iku Oloye Modakeke, akinkanju ọkunrin, akọnimọọgba Super Eagles akọkọ to jẹ ọmọ Naijiria, baba, ọkọ, baba-baba, ẹgbọn ati ọrẹ wa.

A dupẹ lọwọ Ọlọrun fun igbe aye to dara ti wọn gbe ati ipa ti wọn ko ninu idagbasoke orilẹede Naijiria ati gbogbo agbaye gẹgẹ bii akọnimọọgba ere bọọlu.''

Ẹbi Onigbinde sọ ninu atẹjade naa wi pe awọn yoo maa kede eto isinku laipẹ.

Onigbinde lo ko ẹgbẹ agbabọọlu Super Eagles lọ si idije ife ẹyẹ agbaye ọdun 2002 to waye ni orilẹede Japan ati Korea.

Onigbinde ti kọkọ dipo akọnimọọgba ẹgbẹ agbabọọlu Naijiria ti wọn n pe ni Green Eagles tẹlẹ mu lọdun 1982 si 1984.

Lọdun 1984 ni Onigbinde gbe Naijiria wọ abala aṣekagba idije AFCON eyi ti Cameron ti fagba han Green Eagles pẹlu ami ayo mẹta si ẹyọkan.

O tun ṣiṣẹ pọ pẹlu ajọ FIFA ati CAF gẹgẹ bi akọṣẹmọṣẹ akọnimọọgba.