Èdè Gẹ̀ẹ́sì tó wà lórí owó ilẹ̀ Algeria ń bí ilẹ̀ Faranse nínú

Owo Dinar ti ilẹ Algeria

Apapọ beba ti banki agba Orilẹede Algeria gbe jade tí fa ọpọlọpọ awuyewuye, to si n bi awọn oloṣelu lorilẹede France ninu.

Owo titun ọhun to jẹ ẹgbẹrun meji Dinar alapapọ ni wọn gbe jade níbi ipade gbogbo awọn orilẹede Arab to waye lorilẹede Algeria lọjọ kini ati ìkejì oṣu kọkanla.

Ohun to fa awuyewuye naa fun Orilẹede France ko sẹyin bí wọn kọ èdè Gẹẹsi ati lalubawa sì ara owo naa.

Wọn ní o han gbangba pe wọn fẹran èdè Gẹẹsi ju French lọ.

Ninu oṣu keje, Aarẹ ile Abdelmadjid Tebboune kede pe awọn yoo bẹrẹ lati ma kọ awọn ọmọ ile ẹkọ alakọbẹrẹ ni èdè Gẹẹsi.

Koda ko si ede French lara owo Algeria lati ọdun 1964, sugbọn awọn oloselu kan rí gẹgẹ bii arinfin si ede wọn.

Alaga ẹgbẹ alatako, Jean Lic Mélenchon ni Aarẹ Emmanuel Macron lo fa idi ti Orilẹede Algeria ṣe gbe igbesẹ naa lati yoo ede French kuro

"Owo Algeria. Ede tí ọpọ mọ ko si nibẹ. O buru. Gbogbo ọna ni Marcon ti fidi janlẹ."

Awọn sọrọsọrọ lórí redio ati telifisan nigbagbọ pe ìgbésẹ Algeria naa lo fi n paroko oṣelu ransẹ si Orilẹede France.

Lọdun 1962 ni Algeria gba ominira lọwọ Orilẹede France lẹyin ọpọlọpọ ọdun tí wọn fi labẹ isakoso won.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post

Àkọlé fídíò, Celebrity Education: Latin, Igwe, Imalian Boy àtàwọn òṣèré míì kẹ́kọ̀ọ́jáde ní fásitì

Awuyewuye tẹle bí North Korea ṣe jù ado olórò tó parẹ́ sójú òfurufú

Ado Oloro

Ileesẹ ologun lorilẹede South Korea ti kede pe North Korea ju ado oloro ti wọn n pe ni Intercontinental ballistic Missile (IBM) amọ to kuna loju ofurufu.

Ileesẹ ologun naa ni igba keje ree ninu ọdun yii ti North Korea yoo yin ado oloro naa, to si ni ara n fu oun pe ko ni pẹ yin ado iku Nuclear weapon.

Igbesẹ North Korea yii si lo ti mu awuyewuye lọwọ lori erongba rẹ lati ju Ado ohun ija iparun to lagbara (Nuclear Weapon) laipẹ.

Jiju ado olooro IBM yii waye lẹyin ọjọ kan ti awọn North ati South Korea ju oriṣiriṣi ado oloro eyi ti o mu ki aisifọkanbalẹ tẹsiwaju ni agbegbe naa.

Paṣipaarọ yiyin ado oloro yii lo jẹ eyi to tii pọ julọ ti North Korea yin ni ọjọ kan ṣoṣo.

North Korea ju awọn ado oloro naa lẹyin ti orilẹ-ede Amẹrika ati orilẹ-ede South Korea nse igbaradi eyi ti o tobi julọ ni agbegbe naa eyi ti Pyongyang koro ọju sii.

 Ile ise BBC ri gbọ wipe lọjọbọ ni North Korea ju ado oloro (IBM) na ni bii aago mẹjọ ku ogun isẹju eyiti o fo fun bii kilomita ọtalelẹẹdẹgbẹrin.

 Ni ibẹrẹ, Orilẹ-ede Japan sọ pe ohun ija naa ti fo kọja lori orilẹ-ede oun, ṣugbọn Minisita feto aabo, Yasukazu Hamadan sọ pe “ko kọja awọn erekuṣu orilede naa, ti o si parẹ lori okun Japan”.

 Olori orilẹ-ede Japan, Fumio Kishida wa bu ẹnu atẹ lu bi North Korea se n ju ado oloro lemọ-lemọ .

Orilẹ-ede America ninu ọrọ re sọ wi pe ifilọlẹ awọn ado oloro lati North Korea ṣe afihan ewu ti ẹto jiju Ado oloro (IBM) ti ni.

 Aarẹ Kim Jong-un fẹ àkíyèsí Orilẹ-ede Amẹ́ríkà

Jiju ado Oloro (ICM) yii wa ni oṣu kan lẹhin ti Ariwa Korea ṣe ifilọlẹ ohun ija oloro ballistic kan lori Japan igba akọkọ ti o si ṣe bẹ ni ọdun marun.

 Laibikita awọn ijẹniniya ti o rọ mo jiju awọn ogu oloro, Pyongyang ti ju awọn ohun ija oloro mẹfa laarin ọdun 2006 ati 2017 ati pe ohun ngbero lati ju ohun elo iparun elekeje. 

 Ọkan ninu awọn Ado oloro ti Ariwa Korea ju ni orekọja aala to wa laarin awọn orilede korea mejeji

Eyi ti o mu ki Guusu Korea yin ohun ija oloro pada si Ariwa korea lojoru ti o kọja.

 Ojogbon Kim Jong Dae ti ile iwe giga yonsei Institute for North Korea ṣalaye pe orilẹ-ede Ariwa Korea ṣẹṣẹ ko dawo jiju ado oloro duro lẹyin ti o ba ti ju elekeje lati fi han pe ohun naa ni agbara lati ju ado oloro Nuclear Bomb lati ibikibi lori ile Ariwa Korea .