Màmá Davido, Veronica ni kò jẹ́ kí ọmọ mi, tó di dókítà lónìí, kú sínú ‘Swimming Pool’ lọ́dún 25 sẹ́yìn - Orangun Oke Ila
Ó dùn mí pé kò sẹ́ni tó dóòlà Ifeanyi lọ́wọ́ ikú bí màmá bàbá rẹ̀ ti ṣe fọ́mọ mi – Orangun Oke Ila

Oríṣun àwòrán, Davido
Oriade kan nilẹ Yoruba, Orangun tilu Oke Ila, Ọba Adedokun Abolarin ti salaye bi ori se ko ọmọ rẹ yọ lọdun mẹẹdọgbọn sẹyin, lọwọ iku inu omi swimming pool.
Ọmọ ọba naa sisọ loju isẹlẹ yii lasiko to n kẹdun si iku Ifeanyi, ọmọ Davido to ku sinu omi Swimming Pool lọjọ Aje, eyi ti iroyin rẹ gbalẹ kan.
Nigba to n ki Davido ku irọju iku ọmọ rẹ loju opo ayelujara, si ni agba akọroyin kan, Dele Momodu gbe ọrọ ba naa sita, eyi ti ọpọ eeyan n gba yẹwo lori ayelujara.
Gẹgẹ bi oriade naa ti wi, ọmọ rẹ yii lo jẹ ọrẹ Abraham , tii se ọmọ awọn mọlẹbi Adeleke, tii se ẹbi gbajumọ akọrin Takansufe nni, David Adeleke, ta n pe ni Davido.
Bawo ni isẹlẹ naa se waye:
Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ lori isẹlẹ naa, Ọba Abolarin ni ọmọ oun lo lọ sere pẹlu awọn ọrẹ rẹ, ti Abraham si wa lara awọn ọrẹ oun.
O ni lootọ ni Abraham dagba ju ọmọ oun lọ amọ ọrẹ ni wọn.
Ọba Aboolarin ni eti adagun omi iluwẹ, swimming Pool kan si ni wọn wa, ti ọmọ oun si ti re sinu omi naa.
Abraham yii wa n nawọ si, to si n gbinyanju lati yọ jade ninu omi to ko si.
“Ọmọ mi Abraham ko ba ba omi lọ lọjọ naa lọhun, ti kii ba se mama Davido, Veronica, to de sasiko lati ibi isẹ nigba ti isẹlẹ naa n waye.
O kan bọ bata ẹsẹ rẹ ni, lo ba bọ sinu omi, ibẹ lo ti gbe ọmọ mi jade.
Obinrin naa lo tete yọ ọmọ mi kuro ninu omi yii, bi bẹẹ kọ, ohun ta n wi yii kọ ni a ba maa wi.
Ọmọ mi ti mama Davido doola ẹmi rẹ, ti ko fi ku sinu adagun omi iluwẹ naa, ti wa di dokita onisegun oyinbo lonii.”

Oríṣun àwòrán, Dele Momodu
“O dun mi pe ko si ẹni to le doola Ifeanyi, ọmọ ọmọ Veronica nigba to ko sinu omi”
Ọba Abolarin, ẹni to wa gbarata pe ko si ẹnikẹni to wa ni arọwọto lati san oore ti mama Davido se ni ọdun mẹẹdọgbọn sẹyin naa, pada fun Ifeanyi.
O ni ọmọ ọmọ ni Ifeanyi jẹ si oun, ti iku rẹ si dun oun jọjọ.
“Mo ba n ki Davido, Chioma ati baba Davido, tii se ọkọ Veronica ku atẹmọra, Ọlọrun ko ni jẹ ka ri iru rẹ mọ.
Ko dara ki eeyan padanu ọmọ amọ to ba ti waye, ki wa la fẹ se si, a ko le pe Ọlọrun lẹjọ lori rẹ.
Ko si ohunkohun to le waye, ti Oluwa ko mọ si amọ Ọlọrun yoo tu gbogbo wa ninu.
Ọlọrun yoo si ba mi fun wọn ni ọmọ alaubarika, ọtun miran ti yoo duro ni Ọlọrun yoo fun wọn.”
Ọba alaye naa wa gba awọn obi atawọn osisẹ alagbatọ nimọran lati maa tẹle awọn ọmọde kiri nibi ti wn ba n lọ.
Bakan naa lo dupẹ lọwọ awọn ọmọ Naijiria lori bi wọn se duro ti ẹbi Adeleke lasiko isẹlẹ buruku yii.

Oríṣun àwòrán, Oba Adedokun Abolarin
Ta ni Veronica Imade Adeleke, tii se mama Davido?
Orukọ ọkọ rẹ, to jẹ baba Davido ni Adedeji Adeleke.
Ọmọ bibi ilu Benin nipinlẹ Edo nii se, to si dele aye lọjọ Kẹtalelogun osu Kkanla ọdun 1963.
Lẹyin to se igbeyawo pẹlu Baba Davido, o tun gbe fun igba diẹ ni Atlanta, Georgia lorilẹede Amẹrika, ko to dari wa sile.
Atlanta yii si lo bi ọmọ rẹ, Davido si lẹni ọdun mọkandinlọgbọn.
Veronica gba oye Ọmọwe, PHD, nile ẹkọ fasiti Babcock nilu Illishan Remo nigba to de lati Amẹrika.
Lẹyin naa lo wa bẹrẹ isẹ olukọ nile ẹkọ naa.
Bakan naa lo n fi isẹ ori kikọ pawọ da, to si ẹgbẹ ẹgbẹ olorin rẹ, David‘s Band sọri ọmọ rẹ, Davido
A si le ni ara rẹ mama rẹ, Veronica ni Davido ti mu ẹbun orin to n kọ.
Amọ ọjọ kẹfa osu Kẹta ọdun 2003 ni Veronica Imade adeleke jade laye nigba ti ọmọ rẹ, Davido wa lọmọ dun mẹwa.
Aisan ọkan lo pa obinrin naa lọjọ ti ọkọ rẹ n se ayẹyẹ ọjọ ibi ogoji ọdun.
Nigba to n sọ iru eeyan ti Veronica jẹ, Ọba Adedokun Abolarin ni arẹwa obinrin, eeyan dardara to maa n mura bii oyinbo ni obinrin naa.
O wa gbadura pe ki Ọlrun tubọ fi ọrun kẹ.

Oríṣun àwòrán, Davido
Ki lo ti sẹlẹ saaju nipa iku Ifeanyi, ọmọ Davido
Alẹ ọjọ Aje ni iroyin gbalẹ kan pe Ifeanyichukwu tii se ọmọkunrin kan soso ti gbajumọ akọrin takansufe, Davido bi ti jade laye.
Ọpọ eeyan naa ni iroyin ọhun n se ni kami kami kami, ti wọn ko si fẹ gba ikede iku ọmọ naa gbọ.
Amọ nigba to di aarọ ọjọ keji ni agbẹnusọ ọlọpaa nipinlẹ Eko, Benjamin Hundeyin fidi isẹlẹ naa mulẹ fun awọn akọroyin pe lootọ ni Ifeanyi ti jade laye.
O ni ọmọ naa lo ko sinu omi ti wọn fi n luwẹ to wa ni ile Davido lasiko ti baba ati iya rẹ ko fi si ninu ile.
O ni o si pẹ ki wọn to sakiyesi pe ọmọ naa ti ku sinu omi, ti ọlọpaa si ti ko awọn osisẹ mẹjọ to n sisẹ ninu ile Davido fun ifọrọwanilẹnuwo.
Amọ nigba to di aarọ ọjọru, ileesẹ ọlọpaa Eko ni oun ti fimẹfa ninu awọn osisẹ naa silẹ, ti meji to ku si ni ẹjọ lati jẹ lori iku ọmọ ọdun mẹta naa.
Bakan naa lo ni o seese ki wọn se ayẹwo oku ọmọ naa lati tubọ mọ ọna to ba l si ọrun aibaamọ ejo le lọwọ ninu.
Isẹlẹ iku ọmọde yii lo dun awọn eeyan de ọkan, paapaa na to ba ku, ti ọpọ awn osere tiata, akọrin, awọn oloselu atawọn agbaagba lawujọ si ti n ransẹ ibanikẹdun si ẹbi Adeleke.
















