Fayose jẹ agbẹjọ́rò rẹ̀ ní gbèsè ₦900m, ló bá dèrò iléẹjọ́

Oríṣun àwòrán, Google
Gomina ipinlẹ Ekiti tẹlẹri, Ayodele Fayose ti yọju si ileẹjọ giga ni ilu Ado-Ekiti, ni ipinlẹ Ekiti.
Fayose ni wọn gbe lọ si ile ẹjọ lori ẹsun pe ko lee san ẹẹdẹgbẹrun miliọnu naira to jẹ agbẹjọro rẹ, Owoseni Ajayi.
Ajayi yii si ni kọmisọnna fun eto idajọ, nigba ti Ayodele Fayose jẹ́ gomina ipinlẹ Ekiti.
Ajayi lo jẹ agbẹjọro agba ati kọmiṣọna fun eto idajọ ni saa kini ati ikeji ti Fayose jẹ gomina laarin ọdun 2003 si 2006 ati ni ọdun 2014 si 2017.
Bawo ni Fayose ṣe jẹ Owoseni Ajayi ₦900m naira?

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Lasiko igbẹjọ nile ẹjọ giga ipinlẹ Ekiti, ni adari eto idajọ tẹlẹ naa ti ni oun ba Fayose se ẹjọ mejidinlogun.
O ni owo ẹjọ ọkọọkan jẹ aadọta miliọnu naira owo iṣẹ oun amọ ti ko si san titi di oni.
O ni awọn ẹjọ yii lo da jẹ eyi ti Fayose ni si ileẹjọ laarin ọdun 2006 si 2014 lori bi wọn ṣe yọ ni ipo gomina nigba naa.
Bakan naa lo ni oun lọ ṣe agbẹjọro fun Fayose lasiko to n jẹjọ ẹsun iwa ajẹbanu ti ajọ EFCC pe mọ nigba naa lọhun.
Ninu iwe ẹsun naa ni Ajayi ti rọ ileẹjọ lati paṣẹ fun Fayose, pe ki o san owo to jẹ oun lai ni ifaṣẹyin rara.
Bakan naa ni Ajayi tun rọ ileẹjọ wi pe ki o paṣẹ ki Fayose san owo ele ida ogun lori gbese to jẹ oun lati Ọjọ Karun, Osu Kẹwaa, ọdun 2018.
O tun wa n beere ida mẹwaa miran lati ọjọ ti adajọ ba ti da ẹjọ ọhun.
Ki ni Ayo Fayosẹ sọ nile ẹjọ?
Gomina ipinlẹ Ekiti tẹlẹ naa lasiko igbẹjọ ṣe apejuwe ara rẹ gẹgẹ bi ẹni ti ko ni iṣẹ miran ju oṣelu lọ.
Fayose bura pe igbẹjọ ti arakunrin naa pe mọ oun ko ni ẹṣẹ nlẹ rara.
O ni lootọ ni oun mọ arakunrin naa gẹgẹ bi adari eto idajọ oun tẹlẹri, to si ṣe awọn ẹjọ kan fun oun laarin ọdun 2006 si 2017, amọ to fi awọn iwe idajọ ẹjọ naa to gba nile ẹjọ pamọ fun oun.
Nibayii, adajọ ti sun igbẹjọ si Ọjọ Kẹtala, Oṣu Kejila, nibi ti wọn ti lero pe awọn igun ti ọrọ kan yoo le sọrọ naa kuna.















