Ìbúgbàmù gáàsì pa obìnrin tó ń dáná lọ́wọ́ nílùú Omu-Aran

Oríṣun àwòrán, Kwara fire service
Idamu ba awọn ara ilu Omu-Aran lalẹ ọjọ Aiku gẹgẹ bi ara obinrin kan ṣe gba iná lasiko to n dáná alẹ fun ẹbi rẹ.
Iroyin naa sọ pe arábìnrin Adeola Adewale toun ati ẹbi rẹ n gbe ni agbegbe Tebanacle 2c, Egbe Garage niluu Omu-Aran n se oúnjẹ lọwọ ni nnkan bii ago mẹwa kọja ìṣẹ́jú marunle-lọgbọn ti gaasi to fi n dana si bugbamu.

Oríṣun àwòrán, Kwara fire service

Oríṣun àwòrán, Kwara fire service
Atẹjade ti Ileeṣẹ panapana Ìpínlẹ̀ Kwara fi ṣọwọ si awọn oniroyin eyi ti alukoro wọn Hassan Hakeem Adekunle fọwọ́ si ṣàlàyé pé awọn oṣiṣẹ panapana ribi kapaa ina ọhun ti wọn si tete doola ọkọ arabinrin naa ti ibugbamu ina yii ka oun naa mọ inu ile.
Awọn oṣiṣẹ naa gbe e lọ sileewosan ko lè tete ri itọju gba.
Àmọ́ ni ti ìyàwó, kò ye e rara.
Iroyin ni àwọn ibi ti ina ọhun ṣe ijamba si ninu ile wọn ni ibi igbalejo, ile idana ati ibi ìjẹun.
Ẹwẹ, oludari Ileeṣẹ panapana ni Ìpínlẹ̀ Kwara, Omooba Falade John Olumuyiwa gba awọn aráàlú paapaa awọn obinrin nimoran lati lọ kọ nipa ọna ti wọn le maa gba lo gaasi idana lai lewu.










