MC Oluomo sọ̀rọ̀ sòkè lórí ìyànṣẹ́lódí àwọn awakọ̀ Dáńfó l‘Eko
Ìjọba Eko ránṣẹ́ pe ẹgbẹ́ àwọn awakọ̀ Dáńfò tó ń woṣẹ́ níran sí ìpàdé

Alaga igbimọ to n se akoso awọn ibudokọ nipinlẹ Eko, Alhaji Musiliu Akinsaya, ti ọpọ eeyan mọ si MC Oluomo ti sẹ lori ahesọ ọrọ kan to n ja ranin ranin lọwọ.
Ọrọ naa lo nii se pẹlu bawọn eeyan kan se n sọ kiri pe awọn eeyan kan n se ikọlu sawọn ọmọ ẹgbẹ awakọ ero to n wosẹ niran.
Atẹjade kan ti MC Oluomo fisita lati ipasẹ akọwe igbimọ alamojuto gareeji ọkọ ni Eko, Olayiwola Lemboye, lo sisọ loju ọrọ yii.
Saaju ni awọn awakọ ero nipinlẹ Eko ti n wosẹ niran lori ẹsun pe awọn ọmọ igbimọ alakoso gareeji n gba owo kotọ loju popo lọwọ awọn.
Amọ atẹjade ti igbimọ naa fisita ni awọn ọna alaafia wa nilẹ ninu ẹgbẹ naa lati yanju awọn aawọ to ba suyọ.
O ni sisi gbaragada ni ilẹkun olu ile igbimọ alakoso gareji naa wa fun awọn ọmọ ẹgbẹ to ba n fi apa jane lati mu ẹsun wọn wa.
Ẹ ma ti ọrọ oselu bọ isẹ awakọ ero - MC Oluomo sekilọ
“A ko gbọ ohunkohun lati ẹnu awakọ kankan lori sisan owo kotọ loju popo. O si yẹ ki wọn ti lọ fi ẹjọ sun alaga ẹka ẹgbẹ naa to wa ni agbegbe wọn.
Bẹẹ ni wọn si le wa si olu ile ẹgbẹ, ti alaga ẹka ẹgbẹ wọn ko ba gbe igbesẹ to yẹ lori ọrọ naa.
Eeyan jẹjẹ ni MC Oluomo, ko si le fara mọ iru iwa irẹjẹ bii eyi rara, to si ti n kan sawọn alaga ẹka ẹgbẹ ọlọkọ ero naa lati wa bi wọn yoo se bu omi pa ina aawọn naa.”
Atẹjade naa wa n fi ewe ọmọ mọ awọn awakọ ero leti lati mase ti ọrọ oselu bọ isẹ awakọ ero nipinlẹ Eko.
Ijọba Eko ransẹ pe ẹgbẹ awakọ Danfo si ipade lati yanju awọn aawọ to fa iyansẹlodi
Wayi o, ijọba ipinlẹ Eko ti ransẹ pe awọn ẹgbẹ ọlọkọ danfo to n jẹ JDWAN.
Bakan naa ni awọn ọmọ ẹgbẹ alakoso gareji ati awọn ọlọkọ ero RTEAN yoo bawọn peju sibi ipade naa.
Atẹjade kan ti oludamọran si gomina lori igboke-gbodo ọkọ, Hon Sola Giwa fisita lo sisọ loju ọrọ naa.
Atẹjade naa ni ijọba ti n boju wo ibeere awọn awakọ Danfo to n fi apap janu naa lọna ati wa ojutuu laelae sawọn aawọ naa.
Ọla Ọjọru ni ipade naa yoo waye lati yanju aawọ to n fa iyansẹlodi naa.
JDWAN ní àwọn ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ ni bí ìjọba Eko kò bá ṣe ohun tó tọ́
Ọ̀pọ̀ èrò há sí ibùdókọ̀ l‘Eko torí ìyanṣẹ́lódì àwọn àwakọ̀ Danfo

"A n reti ki ijọba pe wa fun ijiroro lori ọrọ awọn agbero to fẹ gba ẹmi wa, bibẹẹkọ iyanṣẹlodi wa yoo ṣi maa tẹsiwaju."
Eyi lọrọ ti akọwe ẹgbẹ to n risi igbayegbadun awọn ọ̀lọkọ ero nipinlẹ Eko, JDWAN, Adedapọ Feyiṣayọ sọ fun BBC News Yoruba lori iyanṣẹlodi ti awọn ọmọ ẹgbẹ naa n gunle bayii.
O ni ipade to yẹ ko waye lọjọ Ẹti to kọja ko lee waye nitori awọn aṣoju ijọba ipinlẹ Eko ni awọn pẹ de kọja akoko ti wọn fun awọn.
O ni agogo meji ni wọn da ṣugbọn agogo mẹta abọ ọsan ni awọn to de ibi ipade naa, eyi ti awọn aṣoju ijọba fi sọ pe ipade naa ko ni lee waye mọ nitori pipẹ de e wọn.
O ni ijọba kọ lawọn n fẹ ko loju bikoṣe pe ki ijọba pe igun mejeeji lati wa ojutu si ọrọ naa nitori awọn ko lee maa ṣe iṣẹ erin ki awọn si maa jẹ ijẹ ẹliri.
Bawo ni igbokegbodo ọkọ ṣe ri l’Eko lọjọ Aje?
Àlàyé rèé lórí ìdí táwọn awakọ̀ Dáńfó l‘Èkó ṣe fẹ́ woṣẹ́ níran fọ́jọ méje
Ọpọ araalu lo bọ ha sinu wahala airọkọ wọ lọjọ Aje pẹlu bi awọn ọmọ ẹgbẹ to n risi igbayegbadun awọn ọ̀lọkọ ero nipinlẹ Eko, JDWAN ṣe gbe ọkọ wọn kuro loju popo gẹgẹ bi ara imuṣẹ ileri wọn lati gunle iyanṣẹlodi ọlọjọ meji lori iwa agbalọwọ meri baalẹ jontolo tawọn agbero n hu si wọn eyi ti wọn ni o ti de gongo ẹmi wọn.
Iyanṣẹlodi naa fi ẹsẹ mulẹ daadaa lawọn agbegbe bii Agege, Alimọṣọ, Ifakọ Ijaye ati ikẹja nibi ti ọpọ ero ti n le ati wọ iwọnba ọkọ to wa nilẹ ti awọn pẹlu si ti fi kun owo ọkọ wọn lonigọbọi.
Ọpọ awọn ero ti ko lagbara awọn owo naa ni wọn ku giri si ẹsẹ wọn ti wọn si n rin lọ si ibi gbogbo ti wọn fẹ lọ.
Amọṣa, lawọn agbegbe miran iyanṣẹlodi naa ko rinlẹ rara.
Ki ni ẹhonu awọn awakọ ero yii?
Ni ọsẹ to kọja ni ẹgbẹ naa gbe ikede sita pe awọn fun ijọba ni gbedeke ọjọ meje lati fi yanju ẹbẹ ti wọn gbe ka iwaju wọn.
Lara ohun ti wọn n beere fun naa ni:
- Pe ki ijọba tẹle aṣẹ ile ẹjọ kan ti wọn ni o ni ki wọn ṣẹwọ ro lori owo gbigba lawọn idikọ gbogbo l’Eko.
- Ki awọn tọọgi ye gba owo lọwọ awọn ọlọkọ ni gbogbo ibudokọ ero nipinlẹ eko.
- Idukuku lajamọni latọdọ awọn agbofinroo ati LASTMA
- Ki ijọba ipinlẹ Eko kọ awọn ibudokọ tuntun kun awọn to wa nilẹ tẹlẹ
Ẹgbẹ JDWAN ni ẹbẹ awọn ko lọwọ oṣelu ninu gẹgẹbi awọn kan ṣe n sọ ọ kiri ati pe nitori pe ijọba ipinlẹ Eko ti gba awọn ẹgbẹ awakọ ero si abẹ rẹ gẹgẹ bii Park Managers lati igba to ti fi ofin de ẹgbẹ ọlọkọ ero NURTW.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ẹgbẹ awọn awakọ Danfo ni ipinlẹ Eko ti kede pe awọn yoo gunle iyanṣẹlodi ọlọjọ meje jake jado ipinlẹ naa.
Wọn ni eyi ko sẹyin bawọn alamojuto ibudoko ati gareeji ṣe n gba owo lọwọ awọn laibikita.
Ninu atẹjade kan ni agbarijọpọ ẹgbẹ to n mojuto igbayegbadun awọn awakọ JDWAN fi sita lopin ọsẹ, ni ikede naa ti jẹyọ.
''Inu wa ko dun nitori ohun to n sẹlẹ yii ti bi a ṣe gbajumọ iṣẹ wa, owo gbigba laibikita, ihalẹ ati idunkoko awọn agbero ati awọn agbofinro ti pọju''
JDWAN tẹsiwaju pe owo gọbọi tawọn n san lawọn gareeji ti mu ki owo ọja gbowo lori ni Eko''
Olori ẹgbẹ naa Comrade Akintade Abiodun sọ pe, owo yii jẹ ki ọja wọn pupọ ni Eko lafiwe pẹlu awọn ipinlẹ Naijiria miran''
O ni owo tawọn agbero n gba loju ọna mu ki awọn to n gbe ọja wọ Eko naa gbe owo lori nkan.
Idaji owo ta n pa, lawọn agbero n gba, o ti su wa - Awọn awakọ Danfo
Gẹgẹ bo se wi, pupọ awọn awakọ lo ti padanu ere ojojumọ nitori bawọn agbero se n gba owo lọwọ wọn nigba ti wọn ba ja tabi gbe ero ni gareeji.
JIDWAN tun fi kun pe awọn lawọn n wa irin ọkọ mọya lojojumọ, ti awọn agbero si n pa owo ju awọn tawọn n sisẹ lọ.
''O kere tan lojumọ kan, idaji owo wa lawọn agbero maa n gba .
Wọn maa n gba orisi owo lọwọ wa ni gareeji tabi ibudokọ kọọkan yala ta ba ja ero tabi taa gbe ero.Ati aarọ, ọsan ati alẹ, ko si igba ti wọn kii gba owo''
O ni ''ọrọ ti doju ẹ bayi tawọn yoo si gunle iyansẹlodi ọlọjọ meje lati fehonu bawọn adari union se n gba oo nigbakugba lọwọ wa''
Ninu awọn ti ireti wa pe yoo darapọ mọ iyansẹlodi naa fun ọsẹ kan ni awọn awakọ korope, bọọsi akero nla ati awọn ọkọ nla ti ijọba gbe kalẹ lati mu aye dẹrun faraalu, Mass Transit.
Ki ni awọn nkan tawọn awakọ Danfo Eko n beere fun?
Awọn nkan ti wọn lawọn fẹ ree
- Wọn ko fẹ ki awọn Union maa gba owo ero mẹta lẹyin tawọn ba kero ni gareeji.
- Owo ero kan ni wọn lawọn fẹ maa san bayii
- Wọn lawọn ko fẹ maa san owo tikẹẹti agbero mọ, tijọba nikan ni wọn lawọn fẹ maa san
- Ki ijọba wọgile awọn owo ti ko lẹtọ mii tawọn n san lẹyin ti wọn ba gbero tan ni gareeji
- Ki ijọba fopin si ihalẹ, idunkoko lọwọ awọn task force, LASTMA ati RRS
- Ki ijọba pese ibudoko to lojutu lagbegbe kọọkan, ki wọn ma ba maa mu awọn ọmọ ẹgbẹ wọn ni ọna ti ko tọ
A ti n bawọn awakọ Danfo sọrọ lati jami lori iyansẹlodi ti wọn n gbero - Ijọba Eko
Ẹgbẹ awakọ wa fohun silẹ pe bi ijọba ko ba da awọn lohun, awọn yoo yanṣẹlodi patapata.
Ẹwẹ kọmisana feto ibaraẹsirọ ni Eko sọ pe awọn ti n ba awọn awakọ yii jiroro ati pe awọn yoo yanju ọrọ naa.
Gbenga Omotosho sọ pe ''Kii ṣe ohun to yẹ ko mu ijaiya wa.''.
''Wọn ti ba ijọba sọrọ. Ijiroro mii yoo si tun waye''
O fikun pe ijọba ipinlẹ Eko ti ṣeto awọn eto irinna lorisi ni ipinlẹ naa.
Fun idi eyi, bi ede aiyede ba waye lẹka kan, ko tumọ si pe gbogbo ipinlẹ Eko ni ko ni ribi maa lọ tabi bọ ni irọrun.














