"Sìgá, Maltina, Milk, Bournvita àti Bisikí làwọn ajínigbé gbà fún ìtúsílẹ̀ ọmọọba Onpetu Ijeru"
Àwọn ajínigbé tó gbé ọmọ mi kìí ṣe Yorùbá, ọ̀kan péré ló ń sọ èdè Yorùbá tá tà tá - Olorì Onpetu

Oríṣun àwòrán, Screen shot
Ọkan lara ọmọ Onpetu tilu Ijeru, Ọba Sunday Oladapo Oyediran, Osekun Keji naa wa lara awọn eeyan ti ajinigbe gbe pamọ lopopona marosẹ Ibadan si Eko lọjọ Ẹti to kọja.
Temi Oyediran ni awọn agbebọn naa fi tipa tipa ti wọnu igbo pẹlu igbakeji ọga agba fun fasiti Ibadan, Ọjọgbọn Adigun Agbaje ati awọn akẹkọ meji miran nile ẹkọ gbogbonse Poly Moshood Abiola MAPOLY, to wa nilu Abeokuta.
Amọ iroyin ti wa gbalẹ kan pe ori ti ko Temi naa yọ lọwọ awọn ajinigbe naa, to si ti pada si aafin Baba rẹ.
Alẹ ọjọ Aiku si ni awọn ajinigbe naa da ọmọọbabinirn naa pada.
Awọn ajinigbe gba Maltina, Milk, Siga, bisikiti lọwọ wa, ki wọn to tu ọmọ mi silẹ - Ayaba Onpetu Ijeru
Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ Mama Temi, Olori Subuola Oyediran fidi rẹ mulẹ pe lootọ ni wọn ti fi ọmọ oun silẹ, to si ti pada wa sile.
Ayaba ni oun dupẹ lọwọ Ọlọrun to yọ ọmọ oun kuro lọwọ awọn agbebọn naa, to si ni wọn ko gba owo itusilẹ kankan lọwọ awọn.
“Awọn ajinigbe naa ko gba nnkan lọwọ wa amọ sápá buruku lo mu wọn nitori wọn gba nnkan miran lọwọ wa yatọ si owo.
Lara awọn eroja itusilẹ ti wn gba ni Maltina, Milk, Bournvita, Siga, bisikiti ati provisions.
Koda, wọn mọọmọ darukọ irufẹ siga ti wọn n fẹ ni, ti wọn si ni Rothmans ni ka ra fun awọn.
Bi aanu ba n sọrọ lori aye eniyan, o maa n da bi idan, o maa n da bi ala ni, Ọlọrun si maa n se awọn nnkan to tayọ ero tabi alaye awa ẹda”
“Ajinigbe kan soso lo gbọ ede Yoruba ta ta ta, awọn yoku kii se Yoruba”
Olori Subuola, ẹni to salaye pe oun ko fẹ sọrọ pupọ lori isẹlẹ naa lati bo asiri ọmọdebinrin ti wọn ji gbe ọhun, wa salaye iriri ọmọ rẹ ni akata awọn ajinigbe ọhun.
Olori ni awọn ajinigbe naa kii se ọmọ Yoruba rara amọ ọkan ninu wọn lo gbọ ede Yoruba ta ta ta.
Awọn ajinigbe naa ni wọn sọ fun wa pe wọn wọ asọ ologun ati tawọn ọlọpaa kogberegbe.”
O wa fikun pe wọn ko se ọmọ oun nise kuse, bẹẹ ni awọn ajinigbe naa ko na awọn ti wọn ji gbe rara.
O fikun pe awọn laanu kan to nifẹ awọn, tii se ibatan awọn lo gbe awọn ẹru naa lọ.
Ọmọ oniwa tutu ni ọmọ mi, ti wọn si se wọn daadaa, paapaa awọn ọmọbinrin to wa laarin awọn ti wọn ji gbe.
















