Àwọn tó kó owó jọ lọ́nà èrú ni yóò ní ìṣòro pẹ̀lú Naira tuntun - Buhari

Oríṣun àwòrán, Presidency/Twitter
Aarẹ Muhammadu Buhari ti sọ pe oun faramọ erongba Banki Agba Naijiria, CBN, lati tun àwọn owo Naijiria tẹ̀.
Ninu atẹjade kan to fi sita ni oju opo ayelujara Twitter ileeṣẹ aarẹ lọjọ Aiku, ni Buhari ti sọ eyi.
Buhari sọ pe awọn owo tuntun naa yoo ko ìdààmú ba awọn to ko owo pamọ.
"Àwọn ọmọ Naijiria to ni owo lọ́nà aitọ, ti wọn ko pamọ sinu ilẹ yoo ni ìṣòro pẹlu awọn owo Naira tuntun."
Ṣugbọn ṣa, o ni anfaani to pọ̀ ni awọn ọmọ Naijiria yoo jẹ nigba ti wọn ba ṣe ifilọlẹ awọn owo tuntun.
Buhari ni awọn oṣiṣẹ ati awọn oniṣowo to n pa owo lọ́nà to yẹ nikan ni ko le ni ìṣòro pẹlu owo tuntun.
Ọjọ Ẹti to kọja ni Gomina banki CBN, Godwin Emefiele kéde pe awọn yoo tẹ owo tuntun.
Àwọn owo naa ni N200, 500, ati N1000.
Ọjọ kẹẹdogun, oṣu Kejila, ọdun 2022, sì ni wọn o ko wọn jade.
Àmọ́ ọjọ o di ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Kinni, ọdun 2023 ki àwọn owó atijọ ma jẹ itẹwọgba mọ.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Buhari ati minisita eto isuna tako ara wọn lori Naira tuntun
Sugbọn ṣa, ọrọ ti Buhari sọ yii tako nkan ti minista fun eto iṣuna Naijiria, Zainab Ahmed, sọ lori igbesẹ CBN.
Arabinrin Ahmed ti kọkọ sọ pe oun ko mọ nipa atunṣe owo Naira, to si ni ileeṣẹ eto iṣuna ko fọwọ́ si.
Lati igba ti Godwin Emefiele ti kede awọn owo tuntun naa, ni ọpọ ọmọ Naijiria ti n fi erongba wọn han.
Bi àwọn kan ṣe sọ pe kii ṣe nkan ti ọ̀rọ̀ Naijiria kàn lasiko yii, ni awọn miran ń sọ pe igbeṣẹ naa yoo ba nkan jẹ fun awọn oloselu to ko owo pamọ.















