Ẹ ò báà lu ìlù àtìlẹ́yìn fún Tinubu, ní t'èmi, Peter Obi ló kàn, ìdí sì rèé - Ayo Adebanjo

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Adari ẹgbẹ awọn ọmọ Yoruba kan, Afenifere, Pa Ayo Adebanjo ti ni ẹnikẹni o baa ni ki Tinubu maa jo lọ awọn wa lẹyin rẹ, oun ni toun ṣi duro lori ọrọ oun pe oludije ẹgbẹ oṣelu Labour Party, Peter Obi ni oun n gbaruku ti lẹyin fun ipo aarẹ Naijiria lọdun 2023.
Adebanjo sọ eyi gẹgẹ bi esi si ipade laarin oludije ẹgbẹ oṣelu APC, Bola Ahmed Tinubu ati adari ẹgbẹ Afenifere tẹlẹri, Pa Reuben Fasoranti ni ipinlẹ Ondo nibi ti Baba Fasoranti si ti gbe ọwọ le Tinubu lori to gbadura fun aṣeyọri rẹ.
Adebanjo lo tẹwọ gba eku ida ẹgbẹ Afenifere lọwọ Baba Fasoranti tori naa, ọpọlọpọ ti gbagbọ pe ibi kan lo yẹ ki awọn mejeji to si nipa oṣelu amọ ṣe ni Adebanjo kọjalẹ pe "igbagbọ baba ko gba ọmọ la" ati pe "ohun to wu mi ko wu ọ".
Ni ọjọ Aiku ni Tinubu ṣe ibẹwo si ile Fasoranti to wa nipinlẹ Ondo ti baba naa si kede atilẹyin rẹ fun un.
Ṣe ija wa laarin Adebanjo ati Fasoranti to gbe eku ida lee lọwọ ni?

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Ẹwẹ, Adebanjo ẹni ọdun mẹrinlelaadọrun nni sọ pe bo tilẹ jẹ pe oun ko fẹ ni fa ki n faa kankan pẹlu adari oun amọ, Peter Obi ṣi ni aayo oludije fun oun ninu idibo to n bọ ninu oṣu keji ọdun to n bọ.
O ti ṣe diẹ ti Adebanjo ti n tẹnu mọ oun to duro le lori ti oniruuru awọn Naijiria naa si ti n sọ ero wọn. Ni oṣu to kọja, Adebanjo ni bi orilẹede Naijiria yoo ba ṣi wa ni isọkan lọdun 2023, gbogbo ọmọ Naijiria lo yẹ ko ṣatilẹyin fun Obi ati Datti igbakeji rẹ.
Bakan naa lo ni oun ko ni gba ibọde rara lori idajọ ododo, idọgba ati gbigba gbogbo eeyan laye.
"Iha Iwọ Oorun-Guusu iyẹn ẹya Yoruba ti ni aarẹ ri, awọn tun ni wọn wa lori ipo igbakeji aarẹ lọwọlọwọ, iha Guusu-Guusu ti lo ipo aarẹ fun ọdun mẹfa ri amọ awọn ẹya Igbo lati Ariwa-Guusu ko ti fi ipo aarẹ tọ ẹnu wo rara ni Naijiria, nibayii ti asiko si ti to ki agbara lọ si Guusu, ẹtọ idọgba ni pe ko lọ si ọdọ awọn Igbo."
Adebanjo tun ni "a o le sọ pe ki awọn ẹya Igbo ṣi duro si Naijiria, ki a si tun wa tẹsiwaju lati maa fi ẹtọ wọn dun wọn ki wọn ma tọ ipo agbara wo."
O ni Peter Obi ẹya Igbo ni Peter Obi, Afenifere si fẹ tii lẹyin tori oun ni ẹni ti awọn nigbagbọ pe o lee ṣe atunto Naijiria pada si iru ilana to yẹ ko maa tẹle.
Bakan naa ni Adebanjo ni awọn ko ni "yi ẹsẹ kuro ni titẹle idajọ ododo, idọgba ati fifun gbogbo eeyan ni anfani nitori pe ọkan lara wa, Asiwaju Bola Tinubu wa lara awọn oludije".
Olùdíje tí Afenifere fẹ́, ni èmi náà faramọ́ bí ẹgbẹ́ òṣèlù wa tiẹ̀ yàtọ̀ - Makinde

Oríṣun àwòrán, Other
Gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde, ti sọ oludije to faramọ́ fun ipo aarẹ lọdun 2023.
Makindeti igbakeji rẹ, Bayo Lawal ṣoju fun nibi ipade ti Bola Ahmed Tinubu ṣe pẹlu awọn agba ilẹ̀ Yoruba lọjọ Aiku, sọ pe ipinnu ẹgbẹ́ naa ni oun faramọ.
Ọjọ Aiku ni aṣiwaju ẹgbẹ́ ọmọ Yoruba, Afenifere, Pa Reuben Fasoranti ati awọn agba ilẹ̀ Yoruba kan, buwọlu oludije ẹgbẹ́ oṣelu All Progressives Congress, si ipo aarẹ, Bola Tinubu.
Nibi ipade ti Tinubu ṣe pẹlu awọn adari ẹgbẹ́ Afenifere nile Fasoranti, n'ilu AkuIkede Makinde yii waye lasiko ti wahala n ṣẹlẹ̀ nini ẹgbẹ́ oṣelu rẹ, Peoples Democratic Party, PDP, níbi ti Atiku Abubarka ti n dije fun ipo aarẹ.
"Nitori naa, nkan to ni kí n fi da yín loju (Makinde) ni pe nkan ti ẹ ba faramọ lati ṣe, ni emi naa faramọ.
Ikede Makinde yii waye lasiko ti wahala n ṣẹlẹ̀ nini ẹgbẹ́ oṣelu rẹ, Peoples Democratic Party, PDP, níbi ti Atiku Abubarka ti n dije fun ipo aarẹ.
Àwọn gomina kan, lara eyi ti Seyi Makinde wa, n fẹ́ ki alaga ẹgbẹ́ PDP, Iyorchia Ayu fi ipo naa silẹ.
Adebanjo ko lọ si ipade ti Afenifere ti buwọlu Tinubu
Awọn ọmọ ẹgbẹ́ naa bii Oloye Ayo Adebanjo, ati Akọwe Agba fun ẹgbẹ́ naa, Oloye Sola Ebiseni, ko si nibi ipade naa. Adebanjo, gẹgẹ bi iwe iroyin Punch ṣe sọ lootọ ni agba Yoruba, Pa Reuben Fasoranti pe oun si ipade naa, sugbọn oun jẹ ko mọ iha ti ẹgbẹ́ Afenifere kọ si ọrọ idibo 2023.
O ni "Afenifere ti yan iha to fẹ, lati ti Peter Obi lẹyin. Sugbọn mi o ni sọ ohunkóhun nipa ẹgbẹ́ kankan to ba yapa, nitori idiwọ ni yoo jẹ́."
"Nkan to kàn ni lati mojuto bi ao ṣe bori ninu idibo."
Osu bii meji sẹ́yìn ni Oloye Adebanjo kede pe oludije fun ipo aarẹ lati inu ẹgbẹ́ oṣelu Labour ni Afenifere yoo ṣe atilẹyin fun.

Oríṣun àwòrán, @ThisIzOVO
Ẹ̀yìn Tinubu ni a tò sí, òun nìkan ló lè ṣé – Afenifere
Awọn agba ẹgbẹ Afẹnifẹre ti sọ pe awọn yoo ṣatilẹyin fun oludije sipo Aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APC, Asiwaju Bola Tinubu, lati di Aarẹ Nigeria.
Atilẹyin yi ni wọn ṣe ipinnu rẹ niluu Akure to jẹ olu ilu ipinlẹ Ondo lakoko ti wọn gbalejo Tinubu nile adari ẹgbẹ naa, alagba Reuben Fasoranti.
Gbajugbaja onkọwe to tun jẹ akọwe agba tẹlẹ ri fun ẹgbẹ Afẹnifẹre, Basorun Sehinde Arogbofa, lo gbẹnusọ fawọn adari ẹgbẹ naa nibi ipade ọhun.
Arogbofa sọ pe o di dandan ki awọn ṣatilẹyin fun Tinubu toripe o lagbara lati mu irẹpọ ba gbogbo ẹya to wa ni Naijiria, ti yoo si mu ilọsiwaju ba ilẹ yii.
Arogbofa ni Tinubu kii ṣe ọmọ Yoruba nikan, amọ o tun jẹ ojulowo ọmọ Nigeria.
O sọ fun Tinubu pe ko mojuto eto abo, ọrọ aje ati atunto iṣejọba to ba ti di Aarẹ Naijiria.
Onkọwe ọhun ni “Ko si eto aabo to peye fun wa mọ lorilẹ-ede yii, bẹẹ ni ọrọ aje ti dẹnu kọlẹ, a n fẹ ọlọpaa ipinlẹ lati le mu ki eto aabo o nipọn gidi”.
A ti ṣetan lati ti ọ lẹyin – Olu Falae
Ẹni to ti fi igba kan ri jẹ akọwe ijọba apapọ Naijiria ati oludije sipo aarẹ nigba kan ri, Oloye Olu Falae ninu ọrọ tirẹ sọ pe “Ti o ba ti di Aarẹ, dakun ṣiṣẹ lati tun orilẹ-ede yii ṣe.”
“A wa nibi lati fun ọ ni imọran to jọju toripe a ti dagba kọja ẹni ti ko ni iṣẹ kan lati ṣe, amojuto ọrọ aje ṣe koko toripe owo Naira ko niyi mọ, ko si ni pẹ di ẹgbẹrun kan Naira si owo dollar kan.”
“A si ṣetan lati ti ọ lẹyin koo le yi eleyii pada. Oju wa ni yoo si ṣe nigba too ba gba ife ẹyẹ ipo Aarẹ pada wale”.
Igbakeji gomina ipinlẹ Oyo, Bayo Lawal, to ṣoju gomina rẹ nibi ijoko naa ni tirẹ ni gbogbo ohun to ba jẹ mọ idagbasoke ilẹ Yoruba lawọn maa n lọwọ si nipinlẹ wọn, o fikun pe awọn ko nii da duro yatọ sawọn ipinlẹ toku nilẹ Yoruba.
Tinubu ninu ọrọ rẹ dupẹ lọwọ awọn adari ẹgbẹ Afẹnifẹre, paapaa julọ Alagba Reuben Fasoranti fun atilẹyin rẹ to si wip e oun wa mu ẹjẹ oun ṣẹ lati pada wa ti oun ba gba ipo oludije lẹgbẹ oṣelu APC.
Oludije sipo Aarẹ naa waa rọ awọn adari Afẹnifẹre naa lati wa laaye titi ti oun yoo fi wọle bi Aare Naijiria lọdun to n bọ toripe oun yoo pada wa dupẹ lọwọ wọn lẹyin iburawọle












