A kò sọ pé kí Nàíjíríà má pìn-ín, ọ̀rọ̀ wa ti di òrìṣà bó ò le gbè mí, ṣe mi bó o ṣe bá mi – Sowore

Àkọlé fídíò, Omoyele Sowore: Ìgbà méjì ni mo gba Peter Obi sílẹ̀ nígbà tí wọn fẹ́ yọ ọ́ nípò gómìnà
A kò sọ pé kí Nàíjíríà má pìn-ín, ọ̀rọ̀ wa ti di òrìṣà bó ò le gbè mí, ṣe mi bó o ṣe bá mi – Sowore

Ìgbà méjì ni mo gba Peter Obi sílẹ̀ nígbà tí wọn fẹ́ yọ ọ́ nípò gómìnà – Sowore

Gbajugbaja ajafẹtọẹni ati oludije fun ipo aarẹ labẹ ẹgbẹ oselu African Action Congress, AAC, Omoyele Sowore ti salaye ohun to mu ko fẹ dije fun ipo aarẹ lorilẹede Naijiria.

Sowore, ninu ifọrọwerọ rẹ pẹlu BBC Yoruba salaye pe iwa ọjẹlu, adanikanjẹ ati aikaato olori lo mu ki orilẹede yii ba ara rẹ nibi to de bayii.

O ni pẹlẹpẹlẹ tawọn baba wa se, lo si jẹ ki orilẹede yii wa ni ẹyọ kan soso to wa yii.

Sowore wa woye pe afọwọfa ati asasi gan kun awọn ohun to gbe wa de ibi ta wa yii nitori pe awọn ohun ti ko yẹ ko maa da Naijiria laamu, lo n jẹ isoro wa.

O wa n kọminu pe pẹlu iya to si n jẹ wa yii, awọn ọmọ Naijiria ko si tii ronu nipa awọn eeyan to yẹ ki wọn dibo fun.

Omoyele Sowore

“Emi ko ni ki Naijiria ma pin, ọrọ wa ti di orisa bo le gbe mi, se mi bo se da mi”

Oludije sipo aarẹ fẹgbẹ AAC naa tun fikun pe oun ko sọ pe kawọn eeyan to n beere fun pinpin Naijiria se ohun ti wọn fẹ se.

Amọ o ni ibeere to n kọ oun lominu ni pe se ti Yoruba Nation ba de, se a ko ni wa adari ti yoo dari wa ni.

O ni ọrọ Naijiria ti di orisa bo le gbe mi, se mi bo se ba mi, to si ni yatọ si pe ka pin, awọn eeyan miran tuin n pe fun ilana atunto ati atunse Naijiria, eyiun Restructuring.

“Se wọn ko ni ni olori to dara nibẹ naa ni? To ba jẹ pe Naijiria ni olori to dara ni, awn eeyan ko ni maa beere fun iyapa orilẹede yii.

Aini eto fun ilọsiwaju ni Naijiria ni inu se bi ọpọ eeyan pe ka maa lọ

Amọ bi wọn ba pin Naijiria si wẹwẹ, amọ ọmọ ale ilẹ Yoruba yoo si tun pada wa sile, ki wa lẹ fẹ se fun wọn?

Ko si ẹni to le sọ pe bi Naijiria se ri yii, Yoruba, Igbo ati Hausa ko lọwọ ninu rẹ, gbogbo wa la dijọ jẹbi asise to ba Naijiria.”

Sowore ni ti wọn ba fẹ mu awọn oniwa ibajẹ lorilẹede yii, gbogbo ẹya lo wa nibẹ, kii se ọrọ ẹya kan soso.

Sowore wa yan pe oun kii se Emilokan, oun ko si si fun iwa ẹlẹyamẹya.

Atọkun ifọrọwanilẹnuwo BBC ati Omoyele Sowore

“Ominira ni mo n ja fun, n ko ‘Cash Out’ tabi ‘Clout Chase’”

Nigba to n tako ero awọn eeyan kan pe oogun awọro ni igbesẹ rẹ lati dibo aarẹ jẹ tabi lati na owo sita, Sowore ni eyi ko ri bẹẹ rara.

O ni oun kii se olowo yalumọ to n fọn owo sita, oun maa n ja fun ẹtọ ọmọ Naijiria ni, to ba si jẹ pe awọro ni oun n se, oun ko ni maa naka sawọn aleebu ti ijọba n se.

“Ẹni ba fẹ Cash Out, ko ma se oselu olootọ ti awa n se, ẹyin naa mọ awọn eeyan to n cash out pẹlu oselu.

Ta ba fẹ cash out, a lọ dara pọ mọ ẹgbẹ wọn ni amọ ẹni ti wọn n ba ja lojoojumọ, to n lọ sẹwọn ni ojoiojumọ, to n gbena woju ijọba lojoojumọ.

Ẹni to n ja, to n sọ otitọ, to n sọ fun aarẹ orilẹede pe ohun to n se ko dara, se iyẹn ni Cash Out ni tabi o n se olootọ?

Iyẹn kii se Cash Out, isẹ iku ni, ominira laawa n ja fun kii se omi inira tawọn ọmọ Naijiria fi n wẹ nisinyi.”

“Emi ni mo ṣe atọna bi Peter Obi se di oludije aarẹ, mo si tun gba silẹ nigba meji ti wọn yọ nipo gomina.”

Nigba to n salaye ajọsepọ rẹ pẹlu oludije sipo aarẹ fẹgbẹ oselu Labour Party, Peter Obi, Sowore ni olugbala ni oun jẹ fun Obi.

O ni Peter Obi ko le sẹ pe oun ko gba oun silẹ tabi se iranwọ fun oun lati di oloselu ti aye n tẹle bayii.

“Peter Obi ko le sọ pe ko ri bẹẹ, o mọ ninu ọkan ara rẹ lootọ pe ẹẹmeji ni wọn le oun kuro lori oye.

Idi ti mo se sọ pe emi ni mo gba silẹ ni pe mo sisẹ takuntakun fun pẹlu iwe iroyin mi, Sahara Reporters, ti mo n tu asiri bi wọn se n ditẹ mọ.

Igba meji ni wọn ditẹ mọ Peter Obi lati yọ bii gomina amọ emi ni mo gba silẹ.”