Wọ́n so òògùn ìbílẹ̀ àti àgádágodo mọ́ ẹnu ọ̀nà ààfin ní Ikirun, ọba tuntun kò rọ́nà wọlé

Àwọn kàn fariga ní Ikirun, wọn kò jẹ́ kí Oba tuntun ríbi wọnú ààfin

Oogun ati aworan ọba tuntun

Oríṣun àwòrán, Vanguard

Wahala to n waye lẹyin iyansipo Akinrun tuntun ni ilu Ikirun tun ti gba ọna miran yọ.

Idi ni pe awọn eeyan kan tun ti dena de ọba tuntun naa lati wọ inu aafin rẹ.

Gẹgẹ bi iroyin to tẹ wa lọwọ, igbesẹ yii ni wn ni ko sẹyin atako si iyansipo ọba naa.

Ni nkan bi ọjọ meloo kan sẹyin ni ikede ọba tuntun yií ti mu ikunsinu wa laarin awọn kan ninu ilu.

Koda, laasigbo ti t'ẹyin atako naa jade, tawọn eeyan kan si fara gbọta.

Ohun táa gbọ bayi ni pé awọn kan ti lo n gbegi dina aafin, ti wọn kò sì jẹ kí ọba ribi wọ inú ààfin.

Awọn ọlọja ko le patẹ, gbogbo ọja da paro ni Ikirun

Iwe iyansipo akirun tuntun

Oríṣun àwòrán, Akirun

Gẹgẹ baa ṣe gbọ, wọn ti fi oògùn kọ ẹnu abawọle aafin, ti araalu kan tí o bá iwe iroyin Vanguard sọrọ, Sofiu Oladimeji sí ni wọn fi agadagodo ti ààfin lati ẹyin, ki ẹnikankan ma baa ríbi wọlé.

O ni oun ko le sọ pàtó awọn to ti aafin tabi ẹni tó pa aṣẹ pe kí wọn gbé kọkọrọ sí ẹnu ọnà aafin.

Igbesẹ yi gẹgẹ bi ti Sofiu ṣe sọ ko jẹ ki awọn ọlọja ríbi patẹ ọja wọn, ti ọja sí dà paro lọjọ Eti ati l'owurọ Àbámẹ́ta.

A kò ríbi fìdí rẹ múlẹ idi ti wọn fi ti ààfin ṣugbọn atẹjade kan lati ọdọ igbimọ awọn oloye ìlú rọ aráàlú lati faaye gba alaafia.

"Lootọ la gba pé àwọn èèyàn lẹtọ lati fi ẹhonu hàn nigba ti nkan ko ba lọ bi eeyan ba se fẹ ṣugbọn kò yẹ kí a fi ọwọ ara wa maa gbe ìdájọ kalẹ"

"Eleyi ko bojumu torí naa lati se wa kesi aráàlú lati jẹ ki alaafia jọba'

Saaju ni iwọde kan ti waye lọjọbọ nigba ti ijọba ipinlẹ Osun kede ọmọba Yinusa Olalekan Akadiri gẹgẹ bii Akirun tilu Ikirun tuntun.

Ìwọ́de gbòde nílú Ikirun lẹ́yìn tí ìjọba kéde ọba tuntun
Aworan afihan Akinrun tuntun

Oríṣun àwòrán, Oba Yinusa Olalekan Media Team

Saaju la ti mu iroyin wa fun yin pe awọn ọdọ kan nilu Ikirun ni ipinlẹ Ọṣun ti n ṣe iwọde kaakiri ilu naa lẹyin ti ijọba ipinlẹ Ọsun kede pe oun ti buwọlu orukọ Ọmọọba Olalekan Akadiri gẹgẹ bi Akinrun tuntun fun ilu Ikirun.

BBC Yoruba fidi rẹ mulẹ pe opopona agbegbe ỌjaỌba at'awọn agbegbe to pataki miran ni iwọde naa ti n waye.

Awọn afọbajẹ ilu Ikirun ja ewe oye le Ọmọọba Akadiri lori lojobo lẹyin ti ijọba ipinlẹ Ọsun kede rẹ gẹgẹ bi Akinrun tuntun.

Ijọba ipinlẹ Ọsun kede Akinrun tuntun

Ijọba ipinlẹ Ọsun kede Yinusa Ọlalekan Kadiri gẹgẹ bi Akinrun tuntun fun ilu Ikirun l’Ọjọru .

Ọmọọba Kadiri di Akinrun lẹyin ti pupọ awọn ọmọ igbimọ afọbajẹ ilu Ikirun fọwọsi orukọ rẹ nibi ipade wọn to waye lẹtin iku Akinrun ana.

Iroyin to tẹ BBC lọwọ sọ pe mẹfa ninu awọn afọbajẹ meje ilu naa lo fọwọsi orukọ rẹ.

Awọn afọbajẹ ilu Ikirun pe fun alaafia

Aworan Oba tuntun

Oríṣun àwòrán, Oba Yunusa Olalekan Media Team

Ninu atẹjade kan ti wọn fi sita, igbimọ afọbajẹ ilu Ikirun rọ awọn eeyan ilu Ikirun lati gba alaafia laaye nitori eto oye jíjẹ rẹ ti bẹrẹ.

Atẹjade naa sọ pe Odofin Ariwajoye Baba AbdulRasheed Diekola Ariwajoye, lo leawju awọn afọbajẹ naa ninu ilana gbofbo to yẹ fun Akinrun tuntun lati gori apere .

Bakan naa ni atẹjade naa tun rọ awọn agbaagba ilu naa lati gbe igbesẹ lati dẹkun awọn wahala to n waye nilu naa lọwọlọwọ nitoei oye naa.

Idile oye Ọba Ara ni Akinrun tuntun, Yinusa Ọlalekan Kadiri ti jade wa, awọn mẹtadinlogun lo si baa du oye naa ko to ja mọ ọ lọwọ.

Itẹ Akinrun tilu Ikirun ṣofo lọjọ kẹjọ oṣu keji ọdun 2021 lẹyin ti Ọba Rauf Ọlawale Adedeji gbesẹ lẹyin to lo ọgbọn ọdun nipo