‘Ọ̀pọ̀ ìyá àwọn “boyfriend” mi ń lé mi, wọ́n ní Grandma ni èmi tí wọ́n mú wálé’

Àkọlé fídíò, Damilola Adeyemi: Ọ̀pọ̀ ìyá àwọn “boyfriend” mi ń lé mi, wọ́n ní ìyá-ìyá ni èmi tí wọ́n mú
‘Ọ̀pọ̀ ìyá àwọn “boyfriend” mi ń lé mi, wọ́n ní Grandma ni èmi tí wọ́n mú wálé’

“Mo ti níi lọ́kàn pé mo ti máa bímọ tán ni ọdún 27 àmọ́ gbogbo ìyá àwọn “boyfriend” mi lo n le mi danu”. Ọpọlọpọ eeyan lo maa n sọ pe riro ni teniyan ṣugbọn ṣiṣe ni ti Ọlọrun. Pe Damilola Adeyemi tilẹ ro ero daadaa nipa ara rẹ lati kekere dara to amọ aiwa si imuṣẹ rẹ ni ohun to gba ọkan rẹ so bayii. “Mo gbiyanju ki emi naa tete ṣe igbeyawo ki n dẹ ṣe abiyamọ kiakia amọ tori pe mo jẹ ẹni to lomi lara...”

Damilola Adeyemi

Oriṣiriṣi ni Damilola n ri nigbakuugba ti ọkunrin afẹsọna rẹ ba ti mu u lọ ile lati fi han awọn obi rẹ. O sọ fun BBC Yoruba pe awọn iya mii a sọ fun afẹsọna oun pe iya iya rẹ lo gbe wale torinaa, afẹsọna ko ni mọ bi yoo ṣe gbe ọrọ̀ naa kalẹ fun Damilola. Ọpọlọpọ iya awọn afẹsọna rẹ lo ti kọ ọ ti wọn si fi ọgbọn le e danu kuro lọdọ ọmọ wọn nitori titobi ara rẹ ti wọn ni o ti pọ ju fun apọn ti ko tii si nile ọkọ. Ẹwẹ kii wa ṣe pe oun naa joko tẹtẹrẹ, Damilola ni oun ti lo oniruuru oogun to lee mu ara ru amọ pabo ni gbogbo igbiyanju rẹ n ja si. Damilola ṣi n ni ireti wipe nnkan yoo yipada fun oun.