Mo ti di "born again" lọ́gbà ẹ̀wọ̀n! - Seun Egbegbe bá BBC sọ̀rọ̀
Lórí ọ̀rọ̀ Toyin Abraham, mi ò fẹ́ sọ ǹkankan àmọ́ ìhà tó kọ sí mi ...

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Lootọ ni Seun Egbegbe sọ pe ọpọlọpọ awọn to n pe ara wọn ni ọrẹ oun lo yipada ti wọn di ọta nigba ti oun de ọgba ẹwọn.
Amọ nigba ti a bere pe to ba ri Toyin Abraham lonii, ki ni yoo ṣe.
“Toyin, ko ki n fi oju oloore gun igi. Ko si nkan to ba ṣẹlẹ, too ba wa ninu iṣoro, ko le gbagbe ẹ”.
Seun Egbegbe wa sọ fun BBc Yoruba pe to ba ti kan ohunkohun nipa Toyin Abraham, oun ko fẹ sọ nkankan lori ẹ tori o ti wa nile ọkọ rẹ o si nilo apọnle.
“Ẹ jẹ ka pọn igbeyawo rẹ re. O ti ni ọkọ ati ọmọ, mo si gbadura fun un pe Eṣu ko ni ya wọn lagbara Ọlọrun”.
Mo ti di "born again" lọ́gbà ẹ̀wọ̀n! - Seun Egbegbe bá BBC sọ̀rọ̀
"100% iyatọ ti wa bayii laarin Seun Egbegbe ti tẹlẹ ati ti isinsiyi, mi o le laye laye gbe ọwọ mi soke na obinrin kankan mọ".
Gbajugbaja oṣere fiimu Yoruba, Seun Egbegbe gbalejo BBC Yoruba lẹyin to gba itusilẹ kuro lọgba ẹwọn.
Ninu ọrọ rẹ, o ni ọpọlọpọ awọn ti oun mọ gẹgẹ bi ọrọ timọ timọ nigba toun ṣi gbajumọ lagbo oṣere loun rii pe ọta gbaa ni wọn nigba ti oun yoo fi de ọgba ẹwọn. "Obinrin to ba ti n gbe ọwọ soke na obinrin, ọwọ yẹn ko le fi ṣe nkan rere mọ laye".
Ọjọ diẹ sẹyin ni Egbegbe ri itusilẹ gba lẹwọn lẹyin ọdun meje to lo nibẹ fun ijiya pe o ji foonu iPhone ni ọjọ Computer village ti wọn ti n ta foonu l’Eko atawọn ẹsun mii.
“Mi ko fẹ sọ nipa nkankan to ṣẹlẹ nibi ti mo lọ amọ ti a ba wo o, ọta pọ. Ko si nkan ti mo le sọ, ẹlomii a tun sọ pe ah, irọ lo n pa...”

O ṣe afiwe iṣẹlẹ tirẹ bii ki wọn sọ pe gbajumọ olowo nla kan lọ si ọja lọ ji ata oni igba naira, o ni awọn to jẹ ọta rẹ ma gbagbọ ni kiakia.
“Tori naa, mi o jẹ ẹnikẹni ni alaye kankan!”.
Ṣugbọn o n dupẹ lọwọ Ọlọrun pe oun lọ oun si bọ ni alafia.
Ọkan lára wọn wà, tó bá máa fún mi ní omi lásán, “Ọlọ́run mi” ló ń pè mí, ó ń kúnll fún mi ni àmọ́... Héééè!
“Mo ti wá ri ile aye tan bayii”
Seun Egbegbe ni nkan to ṣe pataki fun oun ju ninu ọgba ẹwọn ti oun lọ yii ni pe oun ti di atunbi, oun si ti fi aye oun fun Ọlọrun.
“Ìyàtọ̀ ti wà láàrin Seun Egbegbe tẹ́lẹ̀ àti ìsinsìyí, 100% ìyàtọ̀ ti wà."
Àkàìkàtán làwọn nǹkan tí Seun Egbegbe rí nínú òkun àti ọ̀sà ọgbà ẹ̀wọ̀n.
















