"Ọṣẹ lọmọ mi lọ rà kí wọ́n tó fipá ba lopọ̀ dojú ikú"

Aworan ọmọdé tí wọn fi ọwọ di lẹnu
    • Author, Faoziyah Saanu-Olomoda
    • Role, Broadcast Journalist

Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ogun ní àwọn ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí, tí àwọn sì ń wá ọmọkùnrin kan tó ti ṣe ẹ̀wọ̀n rí, Mercy Orija fẹ́sùn wí pé ó fi ipá bá ọmọ ọdún méjìlá sùn dójú ikú.

Agbẹnusọ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ogun, Abimbola Oyeyemi sọ fún BBC Yorùbá lọ́jọ́ Ajé ọjọ́ Kẹrìnlélógún pé afurasí náà, Mercy Orija ti na pápá bora láti ọjọrú, ọjọ́ Kọkàndínlógún oṣù Kẹwàá tí ìṣẹ̀lẹ̀ láabi náà ti wáyé.

Oyeyemi ní afurasí ọ̀hún ti fi ìgbà kan wà lẹ́yìn ní ọdún tó kọjá nígbà tó lu ènìyàn kan ní agbègbè náà ní àlùbami.

Ó ní ó di dandan kí afurasí ọ̀hún fojú winá òfin ẹ̀ṣẹ̀ tó ṣẹ̀.

Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn tó tẹ iléeṣẹ́ wa lọ́wọ́ ní agbègbè Fehintoluwa ní Idiya, ìjọb ìbílẹ̀ Abeokuta-North ní ìpínlẹ̀ Ogun ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti wáyé.

Ọmọ ìkẹ́kọ̀ọ́ ìpele mẹ́ta àkọ́kọ́ ní ilé girama Army Day Secondary School, Alamala ní ìlú Abeokuta ni wọ́n pé ọmọdé náà kó tó kú.

Iléeṣẹ́ ìwé ìròyìn PREMIUM TIMES nínú ìjábọ̀ wọn ní àwọn ọ̀dọ́ ní agbègbè náà tí ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún kọ lọ́minú ti lọ dáná sun ilé àwọn mọ̀lẹ́bí afurasí náà.

Ọṣẹ lọmọ mi, ọmọ ọdún 12 fẹ́ fi fọ ìbọ̀sẹ̀ ìlé ẹ̀kọ́ ló lọ rà kí afurasí tó fipá ba lòpọ̀ dójú ikú

Bàbá olóògbé ọ̀hún, Sanjo Fakeye ní lẹ́yìn tí ọmọ òun dé láti ilé ẹ̀kọ́ lọ́jọ́rú ló ṣe iṣẹ́ àmúrelé rẹ̀, ló béèrè owó lọ́wọ́ òun láti fi lọ ra ọṣẹ láti fi fọ ìbọ̀sẹ̀ rẹ̀.

“Mo fun lówó láti lọ ra ọṣẹ ṣùgbọ́n mi ò ri kó padà wá sílé.”

“Nígbà tó pẹ́ tí mi ò ri kó wọlé wá lásìkò ni mo dìde láti wá a lọ.”

“Nígbà tí mo dé ibi tó ti lọ ra ọṣẹ, wọ́n sọ fún mi pé ó ti ra ọṣẹ, ó sì ti kúrò lọ́dọ́ àwọn tipẹ́tipẹ́.”

Fakeye ní láti ìgbà náà ni ọkàn òun ti dàrú, tí àwọn sì bẹ̀rẹ̀ sí ní wa káàkiri àdúgbò.

“Gbogbo ilé àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ ni mo wa dé ṣùgbọ́n nígbà tó di nǹkan bíi ago mẹ́jọ ni òun lọ fi ọ̀rọ̀ náà sùn ní àgọ́ ọlọ́pàá.”

Ó fi kun pé nígbà tí òun ń bọ̀ láti àgọ́ ọlọ́pàá ni òun gba ìpè láti ọ̀dọ̀ àwọn ará àdúgbò àwọn wí pé wọ́n ti rí òkú ọmọ òun.

Ó ní ilé àkọ́kù ni àwọn ti bá òkú ọmọ náà pẹ̀lú ọṣẹ tó lọ rà ní ọwọ́ rẹ̀ tí ẹ̀jẹ̀ sì wà ní gbogbo ara rẹ̀.

Fakeye ní ìdàjọ́ òdodo ni òun ń fẹ́ báyìí láti fojú ẹni tó hu ìwà náà jófin.