Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀kọ́ ni mo kọ́ lára bàbá mi - Abisola ọmọ Ajimobi

Gómìnà àná ìpínlẹ̀ Oyo, Abiola Abimobi àti ọmọbìnrin rẹ̀, Abisola

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Abisọla Kọla Daisi ti o jẹ ọkan lara awọn ọmọ Gomina tẹlẹri n'ipinlẹ Ọyọ, Oloogbe Sẹnetọ Abiọla Ajimọbi ti ṣe alaye ọrọ nipa iru ibaṣepọ ti o ni pẹlu baba rẹ ki o to jade l'aye.

Ninu ọrọ ti o fi lede lori ipa ribiribi ti baba rẹ ko ni aye rẹ, nibi ayẹyẹ ifami ẹyẹ danilọla fun Gomina tẹlẹri naa lẹyin ipapoda rẹ, eleyii ti ẹgbẹ awọn akọroyin lorilẹede Naijiria labẹ aburada 'Nigeria Union of Journalists', NUJ ẹka ti ipinlẹ Ọyọ ṣe agbekalẹ rẹ fun ọdun 2022,.

Abisọla ni, "Bi mo ba ronu nipa apẹrẹ adari rere to ko ipa ribiribi ninu aye mi, ẹni akọkọ ti o maa n wa si ọkan mi ni baba mi".

O ni oun maa n ni ero wi pe awọn ọmọ oun naa n ri awọn obi wọn gẹgẹ bi awokọṣe rere tabi apẹrẹ adari ti o tayọ, botilẹ jẹ wi pe gbogbo obi kọ ni o n fi iru ipilẹ to n mu ki awọn ọmọ hu iwa gidi lelẹ gẹgẹ bi baba oun ṣe fi lelẹ fun awọn ọmọ rẹ ati ọpọ eeyan.

Abisọla ni baba oun ṣe ohun ti o lero wi pe o tọna, eyii si mu ki o duro gẹgẹ bii olotitọ eeyan.

O ni, "Nipasẹ rẹ, mo kọ bi a ṣe n ni igbeaye to dara, bi a ti n kọ ipilẹ ara ẹni.

Gómìnà àná ìpínlẹ̀ Oyo, Abiola Abimobi àti ọmọbìnrin rẹ̀, Abisola

Oríṣun àwòrán, Others

Gómìnà àná ìpínlẹ̀ Oyo, Abiola Abimobi àti ọmọbìnrin rẹ̀, Abisola

Oríṣun àwòrán, Others

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

O kọ wa wi pe ohun ti awọn eeyan ba ro nipa wa ko ni itumọ, bikoṣe ohun ti awa gan ba ro nipa ara wa.

"Baba mi sọ fun wa wi pe awọn adari gbudọ fi ipinnu ati iṣe wọn lelẹ lorii awọn ilana antẹẹle, dipo bi wọn ṣe jẹ olokiki si".

O tẹsiwaju wi pe ni ọpọlọpọ igba ni oun rii bi baba oun ṣe di awọn ilana aatẹle rẹ mu, kodaa lasiko ti awọn eeyan kan sọ oko ọrọ sii.

O fi kun ọrọ rẹ wi pe Gomina tẹlẹri naa gbagbọ ninu agbara ibaṣepọ, pẹlu alaye wi pe oun le ka ọpọlọpọ igba ti awọn eeyan ti wa ba oun lẹyin ipapoda baba rẹ lọdun 2020 pẹlu ọkan o jọkan itan lorii bi wọn ṣe lọ rii lọfisi rẹ tabi ninu ile lati gba imọran tabi lati jọ fi ọrọ jomitoro ọrọ.

Abisọla sọ ẹkọ ti baba rẹ kọọ wi pe ko si ẹni to gbọn tan, gbogbo wa ni a nilo nnkan kan lọwọ ara wa. Ajọṣepọ yii lo si le mu aṣeyọri wa.

O ni Ajimọbi jẹ ẹnikan to fẹran otitọ, ti osi gbagbọ ninu ominira fun awọn akọroyin ati iṣẹ akọroyin fun ayipada rere.

O fi kun ọrọ rẹ wi pe awọn gbagbọ ninu iran baba awọn gẹgẹ bi idile, awọn yoo si tẹsiwaju lati maa ṣe atilẹyin fun ẹgbẹ NUJ nipasẹ ajọ ẹlẹyinju aanu ti wọn gbe kalẹ lorukọ Sẹnetọ Abiọla Ajimọbi.