APC ló máa tẹ̀síwájú ìṣejọba yìí lọ́dún 2023 lágbára Ọlọ́run, ìdí ni pé ... - Aisha Buhari
Arabinrin Aisha Buhari ti kẹnu bọ adura to si n gbaa wipe ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC ni ọkọ oun yoo tun gbe ijọba le lọwọ lẹyin idibo ọdun 2023.
Aisha Buhari sọ pe iṣẹ daadaa gbudọ tẹsiwaju, bi yoo ba si ri bẹẹ afi ki APC gbe ijọba le APC lọwọ ni.
"Ki lo de tẹ n bere iru ibeere yẹn lọwọ mi (o rẹrin musẹ), lagbara Ọlọrun, APC ni yoo wọle ipo Aarẹ lọdun 2023".
Iyawo aarẹ orilẹede Naijiria, Aisha Buhari tun ṣalaye idi ti oun fi tọrọ aforiji lọwọ awọn ọmọ Naijiria lori iṣejọba ọkọ oun.
Aisha Buhari lo sọ eleyii lasiko to n jiroro pẹlu ileeṣẹ iroyin BBC lori igbeaye rẹ gẹgẹ bi eniyan ati iriri rẹ gẹgẹ bi iyawo aarẹ Buhari.
Ọrọ aforiji ti iyawo aarẹ naa sọ da ọpọlọpọ awuyewuye silẹ nigba naa, eleyii to tọka si pe o mọ pe ijọba aarẹ Buhari ko dẹrun ni ara awọn ọmọ Naijiria.

''Ìdí tí mo fí tọrọ àforíjì lọ́wọ́ àwọn Naijiria nítorí ìjọba ọkọ mi''

Amọ ninu ọrọ rẹ, Aisha Buhari salaye pe ẹda kan ko lee tẹ gbogbo eniyan lọrun ni oun ṣe tọrọ aforiji lọwọ awọn ara ilu.
Laiko ifọrọwanilẹnuwo naa, Aisha ni ero oun ni pe oun ko ro pe ijọba aarẹ Buhari ṣe to fun awọn araalu.
O ni ero oun ni wi pe ọpọlọpọ nkan ti wọn sọ pe wọn yoo ṣe lasiko ti wọn ṣe ipolongo idibo ko wa si imusẹ.
‘’Bio tilẹ jẹ pe ijọba ṣiṣẹ takun takun ni ipa ti wọn, amọ wọn ko le tẹ gbogbo araalu lọrun.’’
‘’Bakan naa ni o ṣeeṣe ki wọn ma ṣe ohun ti awọn araalu n fẹ ki ijọba ṣe fun wọn.’’
‘’Eyi lo mu mi tọrọ aforiji lọwọ awọn ara ilu, kii ṣe pe wọn ko gbiyanju rara.’’
''Iṣẹ mi gẹgẹ bi iyawo aarẹ...''
Aisha Buhari ninu ọrọ rẹ ni iṣẹ oun gẹgẹ bi iyawo aarẹ ni lati ṣiṣẹ iranwọ fun ijọba lai wo ẹyin.
Buhari ni ọfisi iyawo aarẹ lo n gbọ ọrọ awọn obinrin, ọmọde ati ipese iṣẹ fun awọn obinrin to fi mọ idokowo.
O ni titoju bọ ọrọ oṣelu ko ki n ṣe iṣẹ ti oun, iṣẹ oun ni lati ṣe iranwọ fun awọn obinrin lorilẹede Naijiria nipa ajọ Future Assured ti oun gbe kalẹ.
Amọ o ni ko si isuna fun ileeṣẹ oun gẹgẹ bi iyawo aarẹ.
‘’Ohun ti ileeṣẹ mi n ṣe ni lati ran awọn eniyan lọwọ, a ma n gba awọn eniyan to ba nilo iranwọ wọle lai fi ti ẹnikẹni sẹ.’’
‘’Iranwọ nipa eto ẹkọ ati eto ilera lo jẹ wa logun julọ.
Ki ni yoo ṣẹlẹ lẹyin ti aarẹ Buhari ba kuro ni ijọba?
Iyawo aarẹ ni oun yoo kọkọ fi gbogbo nkan silẹ lọ simi nitori ara n fẹ isinmi.
O ni oun ko ni ero ni bayii lati du ipo oṣelu kankan, ati pe oun yoo lo asiko oun pẹlu awọn ẹbi ati ara oun.
Bakan naa lo ni ko si otitọ ninu iroyin gbe Dubai ni oun n gbe kii ṣe Naijiria.
O ni awọn mọlẹbi oun, paapaa awọn ọmọ oun ni oun fẹ kọjumọ ni gba ti oun ba fi osẹlu silẹ.
Amọ o ni ero oun nipe ẹgbẹ oṣelu APC ni yoo jawe olubori ni idibo to n bọ ni ọdun 2023.
Ta ni Aisha Buhari?
- Aisha Buhari ti orukọ abisọ rẹ jẹ Aisha Halilu ni iyawo aarẹ orilẹede Naijiria, Muhammadu Buhari
- Ọjọ Kẹtadinlogun, Oṣu Keji, ọdun 1971 ni wọn bi iyawo aarẹ naa.
- Osu Kejila ọdun 1989 ni o fẹ ọkọ rẹ gẹgẹ bi iyawo keji.
- Wọn ni ọmọ ati awọn ọmọ-ọmọ.
- Gẹgẹ bi ọrọ rẹ, ilu Yola ni wọn ti bii ni ipinlẹ Adamawa
- Fasiti to lọ ni Ambrose Alli ni Ekpoma, nipinlẹ Eko nibi to ti kọ imọ eto ( administration).
- Bakan naa lo ni ilwe ẹri lati ileẹkọ awọn ologun Naijiria, Nigeria Defence Academy.
- O ṣiṣẹ gẹgẹ bi olukọ imọ awujọ( social studies), to si n tọju awọn ọmọ rẹ nigba naa.
- Bakan naa kọ iṣẹ imọ nipa oge ṣiṣẹ ni ilu London.
















