Kí ló dé táwọn àkàndá ẹ̀dá ṣe ń fẹ̀hónúhàn, èyí tó fa rògbòdìyàn l‘Eko?

Ọlọ́pàá yin gàásì tajútajú sáwọn àkándá ẹ̀dá tó ń fẹ̀hónú hàn

Lagos Police Beat, Tear Gas Disabled Athletes During Protest

Awọn ọlọpaa ti yin gaasi tajutaju si awọn to ni ipenija lati sọrọ atawọn abarapa mii ti wọn ṣe ifẹhonuhan niluu Eko.

Eredi ifẹhonuhan naa ko sẹyin igbesẹ ileeṣẹ to n ri si ọrọ awọn ọdọ ati ere idaraya lati yọ ọwọ awọn akanda ẹda naa kuro lawo idije ere idaraya ilẹ yii, National Sports Festival, ti yoo waye loṣu to n bọ nipinlẹ Delta.

Agbegbe Stadium, ni Surulere, niluu Eko ni ifẹhonuhan naa ti waye laarọ Ọjọru.

Wọn ni inu awọn ko dun bi ijọba ko ṣe ka awọn kun, ti ko si fẹ ki wọn kopa ninu idije ọhun.

Gẹgẹ bii ohun ti awọn aṣoju awọn eeyan naa sọ fun BBC Yoruba, wọn ni ere idaraya naa lawọn fi n tọju ara wọn atawọn ẹbi awọn.

Protest

"Awa ni a n gba wura to pọ ju, awa si ni wọn n fiya jẹ ju"

 Ẹni to gba ẹnu awọn oluwọde naa sọrọ, Sodipo Lateef, sọ pe awọn akanda naa lo n gba ami ẹyẹ wura to pọ ju ninu idije ọhun, amọ awọn naa ni ijọba n fi iya jẹ ju.

 O ni “Ọdun mejimeji ni a maa ṣe ere idaraya naa ti a si maa gba ọpọ ami ẹyẹ, ere idaraya yii si ni a fi n gbọ bukata mọlẹbi wa.

“Amọ lojiji ni a kan gbọ pe wọn ti yọ ere idaraya awa ti a wa lori kẹkẹ ‘wheelchair’ kuro, to fi mọ ti awọn eeyan to ni ipenija ipenija lati gbọran.

“Minisita ere idaraya wa sọ pe oun fẹ ke pe awọn eeyan ilẹ okeere lati wa kopa ninu idije naa nigba ti awọn ọmọ onilu gan ko tii yo, ṣe o daa bẹẹ?”

"Ijọba gbọdọ da ere idaraya wa pada bi bẹẹ kọ, iwọde n tẹsiwaju"

Lateef ni ọjọ Aje lawọn ti kọkọ bẹrẹ ifẹhonuhan naa amọ awon ọlọpaa pẹtu si awọn ninu.

O ṣalaye pe awọn ti kọ iwe si ijọba, lẹyin naa ni awọn dawọ iwọde naa duro amọ ijọba ko ṣe ohunkohun nipa ibeere awọn.

O fi kun pe ohun ti awọn n fẹ ni ki ijọba Naijiria pe awọn pada lati kopa ninu idije gbogbogbo ọhun.

O ni “Ohun ti a fẹ ni pe wọn gbọdọ da ere idaraya wa, ti wọn yọ wa kuro ninu rẹ pada sinu idije naa, ti wọn ba fẹ ki alaafia ko jọba. Nnkan ti a fẹ niyẹn.”

O pari ọrọ rẹ pe awọn yoo tẹsiwaju ninu iwọde ọhun titi ti ijọba yoo fi dahun ibeere awọn.

"A o gbe igbesẹ lori ọrọ naa laarin wakati mejidinlaadọta"

Ẹwẹ, alaga ijọba ibilẹ Surulere, Bamidele Suleiman Yusuf, yọju si awọn oluwọde naa, o si rawọ ẹbẹ si wọn lati ṣe suuru.

O ni ẹtọ wọn ni wọn n fẹhonuhan le lori, o si ti to ijọba leti pe wọn ko faramọ ohun ti ijọba ṣe amọ ijọba yoo ṣe atunṣe.

Yusuf bẹ awọn eeyan naa pe ki wọn fun oun ni wakati mejidinlaadọta lati yanju ọrọ naa pẹlu ọọfisi minisita to n ri si ọrọ ọdọ ati ere idaraya.

Amọ awọn oluwọde ọhun kọ jalẹ, lẹyin naa ni awọn ọlọpaa yin gaasi tajutaju si wọn lati tu wọn ka.

Lara awọn eeyan to kopa ninu ifẹhonuhan naa ni awọn abarapa to n gba bọọlu alapẹrẹ, bọọlu ẹlẹyin lawn tẹnis, awọn to n luwẹ, atawọn elere idaraya mii.