Àwọn èèyàn kan faraya bí Peter Obi ṣe ṣe àbẹ̀wò sí Gumi

Oríṣun àwòrán, @Peter Obi
Gbajugbaja onimọ nipa ẹsin Islam, Sheik Gumi ti sọ ohun ti o ba oludije lẹgbẹ oṣelu Labour party, Peter Obi sọ lasiko to ṣabẹwo si.
Ọjọ Aje ni Peter Obi ṣabẹwo si ni ile rẹ ni ilu Kaduna.
Ninu ọrọ ti Gumi ba BBC sọ, o ni Obi wa ba oun lori erongba rẹ lati tukọ orilẹede Naijiria.
Gumi ni amọran ti oun fun naa ni oun fun awọn oloṣelu miran to ti wa ṣabẹwo si oun.

Oríṣun àwòrán, @Peter Obi
Ẹni ti yoo tukọ Naijiria gbọdọ gba alaafia laaye, ko si sọ orilẹede Naijiria di ọkan - Gumi
‘’Ọjọ Aje ni igba akọkọ ti n o ma ṣepade pẹlu Peter Obi lori ero rẹ lati jẹ aarẹ orilẹede Niajiria.’’
O sọ fun mi idi to fi wa si Kaduna ati ero rẹ fun orilẹede Naijiria.
Gẹgẹ bi mo ṣe ṣe fun awọn to ku, mo gbaa ni imọran pe ẹni ti yoo tukọ Naijiria gbọdọ gba alaafia laaye, ko si sọ orilẹede Naijiria di ọkan.
Lasiko ti wọn bi leere boya o ti ni ẹnikan to fẹ ko di ipo aarẹ mu ni Naijiria, Gumi ni oun ko ṣetan lati fi ero naa han ni asiko yii.
Ni tirẹ, Peter Obi fi fọto to ya ni ile rẹ lasiko to ṣabẹwo si Gumi han si gbangba.
Ero awọn eniyan ṣe ọtọọtọ lori Peter Obi to ṣabẹwo si Sheik Gumi
Lati igba ti Peter Obi ti fi aworan han lori ayelujara nibi to ti sabẹwo is Sheik Gumi, ni awọn eniyan si bẹrẹ si ni sọrọ nipa ẹ.
Bi awọn kan ṣe n gboriyin fun pe o ṣe daradara, ni awọn miran n bu ẹnu atẹ lu abẹwo naa.
Awọn to bu ẹnu atẹ lu ni ko tọsi Obi lati ṣabẹwo si Gumi, to jẹ wi pe oun lo n duna dunra pẹlu awọn agbebọn to n pa awọn ọmọ Naijiria.
Bẹẹ ni wọn sọ pe Gumi si n ṣe atilẹyin fun awọn agbebọn nipa ọrọ rẹ.
Amọ awọn to faramọ abẹwo naa ni ọpọlọ ni Peter Obi n lo lati ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn alẹnulọrọ pẹlu awọn araalu lorilẹede Naijiria.

Ẹ wo ohun ti a mọ nipa iru eniyan ti Sheik Gumi jẹ

- Onimọ nipa ẹsin Islam ni Sheik Ahmad Gumi jẹ, oun si ni akọbi Shaykh Abubakar Gumi, ti wọn bi ni ilu Kano,
- Oun ni Mufti ati Mufassir Mọsalasi gbogboogbo ni ilu Kaduna
- Fulani ni ni Gumi, to si jẹ onimọ ati ajagun tẹlẹ pẹlu ileeṣẹ ologun Naijiria,
- Ọmọ ọdun mọkanlelọgọta ni Ahmad Abubakar Gumi, to si lo si ileewe Sadauna Memorial College ati fasiti rẹ ni Ahmadu Bello University to ti kọ iṣẹ gẹgẹ bi dokita,
- Lẹyin naa lo darapọ mọ ileeṣẹ ọmọọogun Naijiria, Nigeria Defence Academy to si ṣiṣẹ de ipo Captain pẹlu ikọ ọmọogun Naijiria ko to fẹyinti lẹnu iṣẹ,
- Oun lo fi apeja ọrọ ''My Vote, My Pride'' ni ọdun 2014.
- Oun lo duna dura pẹlu awọn agbebọn nigba ti wọn ji awọn akẹkọọ ileẹkọ Kagara lọdun to kọja.
- Lẹyin naa lo tun dunna dura lati fi awọn akẹkọọ fasiti imọ nipa eto ọgbin.
- Laipẹ yii ni ijọba Niajiria kede pe awọn ti mu agbẹnusọ rẹ, Tukur Mamu lori ọrọ ti wọn ni o niṣe pẹlu eto aabo.















