Àwọn òṣìṣẹ́ kan tẹ̀lé àṣẹ Akeredolu lórí wíwọ aṣọ ìbílẹ̀ lọjọ́ Ẹtì àmọ́...

Awọn oṣiṣẹ ijọba ati akẹkọ nilu Akure to jẹ olu ilu ipinlẹ Ondo ko tii fi gbogbo ara tẹle atẹjade ijọba ipinlẹ naa lati maa wọ aṣọ ibilẹ ni gbogbo Ọjọ Ẹti.
Abẹwo akọroyin BBC Yoruba se abẹwọ si awọn ile ẹkọ kan ni ilu Akure bii Fiwasaye Girls Grammar School, Oyemekun Grammar School ati C.A.C Grammar School fihan pe.
Ohun ta ri ni pe ko si akẹkọọ kankan lawọn ile ẹkọ naa to wọ aṣọ ibilẹ, to si jẹ pe aṣọ ile-iwe ni gbogbo wọn wọ si ọrun.

‘’Mo nigbagbọ pe eyi yoo jẹ ki aṣa ati iṣe Yoruba o tunbọ gbinlẹ si”- Olukọ
Ọga agba ile-iwe girama Fiwasaye, arabinrin Omobola Ojoge ti gboriyin fun ijọba latari igbeṣẹ naa.
Ojoge ni ṣaaju eyi ni oun ti pa laṣẹ fun awọn olukọ lati maa wọ asọ ibilẹ ni gbogbo Ọjọ Ẹti, ki wọn si maa sọ Ede Yoruba, ni ọjọ naa.
“Lati ọjọ ti mo ti de ile-iwe yii ni mo ti fi ofin lelẹ pe ki gbogbo oṣiṣẹ o maa wọ aṣọ ibilẹ wa si ẹnu iṣẹ ni gbogbo Ọjọ Ẹti, ki wọn si maa fi Ede Yoruba kọ awọn ọmọ ni ọjọ yii.
‘’Mo nigbagbọ pe eyi yoo jẹ ki aṣa ati iṣe Yoruba o tunbọ gbinlẹ si”
Olukọ agba naa fikun pe bo tilẹ jẹ pe ijọba ko tii fi iwe idari ranṣẹ sawọn ọga agba ile- iwe lori ọrọ naa, oun ati awọn olukọ oun ti ṣepade lori ilana tawọn akẹkọọ ko fi nii tabuku igbesẹ naa nipa wiwọ aṣọ ti ko bofin mu.

Amọ ṣe awọn akẹkọọ ko nii tabuku aṣẹ yii nipa wiwọ aṣọ alarabara?
Ojoge wipe ni kete tawọn obi ba fi ọwọ si ọrọ naa nibi ipade ti awọn fẹ pe nitori eyi, awọn yoo da irufẹ aṣọ kan naa fun gbogbo awọn akẹkọọ ti wọn yoo si sọ bi wọn yoo ṣe ran aṣọ ọhun.
Ẹwẹ, ọga agba ile-iwe girama CAC, arabirin Oluwapelumi Adetimehin to kọminu lori bi awọn akẹkọ ko ṣe nii tabuku ilana naa nipa wiwọ aṣọ alarabara.
O ni eyi ko nii fiwọn han bi akẹkọọ, ti o si le fa ifigagbaga laarin awọn akẹkọọ ati olukọ, wipe ọpọ olukọ ko tii tẹle ilana naa.
‘’Idi ti wọn ko tii tẹlẹ aṣẹ ijọba nipe, ijọba ko tii fi iwe idari ranṣẹ sawọn ọga agba ile-iwe.’’
Adetimehin to juwe idari ijọba naa bii ohun to wuyi fikun pe ilana naa yoo ran aṣa Yoruba lọwọ gidi tawọn oṣiṣẹ ba le tẹle.

Oríṣun àwòrán, Other
Ijọba ipinlẹ Ondo ti kede pe àwọn oṣiṣẹ ijọba ati awọn akẹẹkọ nipinlẹ naa ni anfaani lati wọ aṣọ ibilẹ lọjọ Ẹti.
Ninu atẹjade to fi sita ni ọjọ Iṣẹgun, ijọba ipinlẹ Ondo sọ pe eyi ko yọ awọn ile ẹkọ aladani silẹ.
Wọn ni eyi jẹ ọna lati gbe àṣà ati ìṣe larugẹ.
Kọmisanna fun eto iroyin nipinlẹ naa, Arabinrin Bamidele Ademola-Olateju, to kede àṣẹ tuntun naa sọ pe igbimọ alaṣẹ ipinlẹ Ondo fẹnuko lati pa a ni dandan, bẹ̀rẹ̀ ni kiakia, fun awọn oṣiṣẹ ijọba lati ma a wọ aṣọ ibilẹ lọ si ibi isẹ ni gbogbo ọjọ Ẹti.
"A ṣakiyesi pe àṣà wa ti n parun, a si gbọdọ ri daju pe a daabo bo o lọwọ iparun"
'Bakan naa ni awọn akẹ́kọ̀ọ́ to ba wu naa le ṣe bẹẹ.'
Ninu ọrọ ti ẹ, kọmisanna fun àṣà ati irinajo igbafẹ, Ọgbẹni Adewale Akinlosotu, salaye pe ijọba pàṣẹ naa gẹ́gẹ́ bi ọna lati dáàbò bo àṣà Yoruba.
"Nkan to tumọ si ni pe a kede ọjọ Ẹti gẹ́gẹ́ bi ọjọ àṣà.
" A ṣakiyesi pe àṣà ti n parun, a si gbọdọ ri daju pe a daabo bo àṣà wa lọwọ iparun."
Ijọba ipinlẹ Ondo ni ipinlẹ kejì to paṣẹ fún awọn òṣìṣẹ́ rẹ lati ma a wọ asọ ibilẹ wa si ibi iṣẹ.
Oṣù Keje, ọdun 2021, ni gomina ipinlẹ Osun, Gboyega Oyetola, kede ọjọ́ Ọjọru gẹgẹ bi ọjọ́ ti awọn oṣiṣẹ ijọba ati awọn oṣiṣẹ ìlú gbọdọ ma wọ aṣọ Adirẹ lọ si ibi iṣẹ.
O ni o jẹ ọna lati gbe àṣà lárugẹ ati ipese isẹ fun awọn ọdọ.












