Àlàyé rèé lórí bí 20,000 ṣe dá wàhálà sílẹ̀ láàrín àwọn akẹ́kọ̀ọ́ àti aláṣẹ MAPOLY

- Author, Adedayo Owolabi
- Role, Senior Broadcast Journalist
- Author, Emmanuel James
- Role, Video Journalist
Awọn adari ile ẹkọ gbogboniṣe ilu Abeokuta, MAPOLY, ati adari awọn akẹkọọ, SUG ile ẹkọ naa ti ba BBC Yoruba sọrọ nipa ifẹhonuhan to waye nibẹ ninu ọsẹ yii.
Agbẹnusọ ile ẹkọ MAPOLY, Yemi Ajibola sọ pe owo kekere kan ti awọn fi kun owo ile ẹkọ naa lo fa awuyewye ọhun.
O ṣalaye pe eredi afikun naa ko ṣẹyin awọn atunto kan ti wọn ṣe si ile ẹkọ naa.
Ajibola ni “Ile iwe fi owo kekere kan kun owo awọn ọmọ ti a ṣẹṣẹ fẹ gba wọle, nitori ikanni ti wọn ti n ṣe akọsilẹ orukọ wọn ti kuro ni eyii ti a n fi ọwọ kọ si ori afẹfẹ.”
Gẹgẹ bii ohun to sọ, igbesẹ naa ko dun mọ awọn akẹ́kọọ ninu lo mu ki wọn bẹrẹ ifẹhonuhan bo tilẹ jẹ pe awọn akẹkọọ to ṣẹṣẹ fẹ wọle ni ọrọ naa kan.
Ọrọ aje Naijiria ti dori kodo, ko si yẹ ki MAPOLY fi kun owo ile ẹkọ lasiko yii - SUG
Ẹwẹ, nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, aarẹ ẹgbẹ awọn akẹkọọ, SUG, Sodiq Ajani sọ pe eto ọrọ aje Naijiria ti dori kodo, ko si yẹ ki MAPOLY fi kun owo ile ẹkọ ọhun lasiko yii.
Ṣaaju ni awọn alaṣẹ ile ẹkọ naa ti kọkọ fi ẹgbẹrun lọna ogun naira kun owo wọn, ti awọn akẹkọọ ọhun si kọ jalẹ.
Amọ lẹyin o rẹyin, gomina Dapo Abiodun da si ọrọ naa, eyi to mu ki awọn alaṣẹ ile ẹkọ ọhun wọgile afikun owo naa patapata.
Wo fidio to wa loke yii fun ẹkunrẹrẹ ohun ti agbẹnusọ MAPOLY ati Aarẹ SUG ba BBC Yoruba sọ.
















