Iléeṣẹ́ Ọlọ́pàá rántí òṣìṣẹ́ 37 tó kú àti ọkọ 346 tó jóná lásìkò ìwọ́de EndSARS
- Author, Olubayode Alebiosu
- Role, Broadcast Journalist
- Reporting from, Lagos
"Àwa náà ń ṣe ìrántí ọlọ́pàá 37 tó kú lásìkò ìwọ́de EndSARS lọ́dún 2020"

Bi awọn ọmọ Naijiria ṣe ṣe iranti iwọde EndSARS to waye lọdun 2020 pẹlu wahala to tẹyin rẹ yọ.
Ni paapaa julọ ti iṣẹlẹ to waye lagbegbe iloro Lekki, awọn ọlọpaa Naijiria naa ti sọ pe oju meji lowo ṣile ni ọrọ naa nitori pe bi o ṣe kan araalu, naa lo kan awọn ọlọpaa.
Ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Eko ni awọn pẹlu n fi ayajọ ogunjọ oṣu kẹwaa ṣe iranti awọn ọlọpaa to fi ẹmi wọn la iku, to si padanu ẹmi wọn lasiko iwọde EndSARS to waye lọdun 2020.
Ninu atẹjade kan to fi sita loju opo Twitter rẹ, alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Eko, SP Benjamin Hundeyin sọ pe ọlọpaa mẹtadinlogoji ni wọn pa lasiko iwọde naa.
"Titi lae laa maa bu ọla fawọn akọni ọlọpaa to fẹmi wọn lelẹ lasiko iwọde EndSARS"
“Mo ba awọn mọlẹbi ati ọrẹ awọn ọlọpaa ti wọn dẹmi wọn legbodo lasiko iwọde #endsars lọdun 2020 daro.
Wọn fi ẹmi wọn lelẹ. Titi lae la o si maa bu ọla fun wọn.”
Ninu atẹjade naa, alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Eko tẹsiwaju pe olu ileeṣẹ ẹkun ọlọpaa (Area commands) mẹsan an lawọn oluwọde bajẹ.
O fi kun un pe, agọ ọlọpaa mẹrindinlọgọrin, ati agọ ọ̀lọpaa agbegbe (police post) mejidinlaadọta naa tun ba iwọde EndSARS lọ.
O ni bareke ọlọpaa mẹrindinlogun lawọn oluwọde kọlu, ti wọn si bajẹ lasiko iwọde naa.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1
"Igba din meji ọkọ iṣẹ patrol ọlọpaa ati ọkọ mẹrindinlaadọjọ to jẹ tawọn osisẹ ọlọpaa ni wọn bajẹ"
Ẹwẹ, SP Hundeyin ko ṣai tun mẹnuba bi awọn oluwọde ENdSARS ṣe tun ba ọkọ ayẹta (Armoured Personnel Carrier, APC) jẹ.
Bakan naa lo ni wọn ba igba din meji ọkọ iṣẹ patrol ọlọpaa ati ọkọ merindinlaadọjọ to jẹ eyi ti awọn ọlọpaa fi owo ara wọn ra jẹ lasiko iwọde manigbagbe naa lọdun 2020.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa naa ni ati araalu, atọlọpaa lo kọ ẹkọ lasiko iwọde naa.
Sugbọn o ni gbogbo ọmọ Naijiria lo gbọdọ mọ daju pe ajumọṣe gbogbo-gbo ni idagbasoke ati ilọsiwaju orilẹede Naijiria jẹ.

Ìwọ́de Endsars kò nííṣe pẹ̀lú óṣèlú tàbí ẹgbẹ́ òsèlú kankan, ẹ yé parọ́ mọ́ wa – Falz

Ọkan lara awọn adari ikọ Endsars, Folarin Falana ti ọpọ mọ si Falz ti kede pe iwọde Endsars ko niiṣe pẹlu awọn oloselu tabi ẹgbẹ oselu kankan.
Falz lọ sọ bẹẹ nibi ayajọ ọdun keji ti awọn ologun da ibọn bo awọn afẹhọnuhan ni Lekki Tollgate lasiko ti wọn pe fun opin si ifiyajẹni lọna aitọ ti awọn ọlọpaa Naijiria ra ọwọ le.
Ninu ọrọ rẹ, Falz ni ki ẹnikẹni ma rọ pe ikọ Endsars niiṣe pẹlu oṣelu tabi oloṣelu kankan.
‘’Titi di asiko yii, ko i tii si idajọ ododo nipa ikọlu Endsars ni 2020’’

Falz ni awọn tilẹ fi to awọn oluwọde leti wi pe ki wọn maṣe wa pẹlu asia kankan to niiṣe pẹlu oṣelu.
‘’Oun ti a ṣe ni lati bun ọla fun awọn oluwọde to ku nibi ifẹhọnuhan Endsars ni ọdun 2020.
‘’Emi ati awọn to wa si ibẹ wa lati wa sọ fun awọn eniyan to ni igbẹkẹle ninu wa pe, idajọ otitọ yoo leke lori awọn ọdọ ti awọn ọlọpaa n fi iya jẹ.’’
O ni idi ti awọn fi wa nibẹ ni wi pe ko i tii si idajọ otitọ lori awọn to ku lasiko Endsars nigba naa lọhun.
‘’Ko si ẹni to tii fi oju wina ofin, ohun ti wọn n ṣe ni lati sọ pe awọn ko pa ẹnikẹni tabi ṣe ẹnikẹni ni ijamba.’’
Bakan naa lo fi ẹsun kan ijọba wi pe titi di asiko yii wọn ko jẹwọn nkan to ṣẹlẹ ni Lekki tollgate, ki otitọ le jọba.
Ìdí rèé ta ṣe yin afẹ́fẹ́ tajútajú ní Lekki, kìí ṣe ìbọn - Ọlọ́pàá

Ileeṣẹ ọlọpaa ti sọ ipa ti wọn ko ninu iwọde iranti Endsars to waye ni Lekki toll gate.
Eyi ko ṣẹyin iroyin to n kaakiri loju opo ayelujara pe wọn yin ibọn lasiko ti awọn afẹhọnuhan naa pejọ lati ṣeranti ayajọ ọjọ ifẹhọnuhan tako aṣemaṣe awọn ọlọpaa ni Naijiria, Endsars.
Ninu atẹjade ti alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Eko, Benjamin Hundeyin fi lede, o ni awọn ko yin ibọn kankan lasiko ifẹhọnuhan naa.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 2
‘’A ko lo ponpo tabi sun mọ awọn afẹhọnu han naa.''
Bakan naa ni ko si akọsilẹ ọlọpaa kankan to yin ibọn, amọ ti ẹnikẹni ba gburo ibọn ki wọn fi awọn ẹri wọnyii lede ki gbogbo aye ri.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 3
A ko kọlu awọn to n rin irin wọn lai si idiwọ -
Bakan naa ni Hundeyin fikun un pe awọn ko da ẹnikẹni to n lọ ni alaafia duro.
O ni awọn ti awọn yin tajutaju lu ni awọn ti wọn fẹ maa gun tollgate.
‘’Eleyii le da omi alaafia ilu ru ohun ni a ṣe yin afẹfẹ tajutaju lati tu wọn ka.’’
‘’Iwọde alaafia lo yẹ ko jẹ, ko yẹ ki awọn eniyan maa gun tollgate abi ki wọn maa to apele sibẹ.’’
‘’Ti a ko ba tete tu wọn ka, niṣe ni wọn a da rogbodiyan silẹ ni agbegbe naa.’’
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 4
Bakan naa lo fikun un pe irọ ni iroyin pe awọn fi panpẹ ọba mu awọn afẹhọnuhan ti wọn si wa ni panpẹ wọn.
Hundeyin ni gbogbo awọn ti awọn mu ni ibi iwọde naa ni awọn fi silẹ lẹṣẹkẹṣẹ ati pe ko si ẹnikẹni ni ahamọ wọn.
‘’Ni kete ti alaafia pada si agbegbe naa ni a fi awọn ti a mu silẹ.’’
‘’Iṣẹ wa ni lati pese aabo to daju fun awọn araalu ati lati ri daju pe awọn eniyan bọwọ fun ofin ilu.’’
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 5
Tó bá wù yín, ẹ dìbò fáwọn tó pa yín lásìkò ìwọde EndSARS – Sowore

Oludije sipo Aarẹ ninu ẹgbẹ oṣelu AAC, Omoyele Sowore ti sọ pe awọn to ran awọn ọmọ ogun lati dana ibọn ya awọn oluwọde EndSARS, wa lara awọn to n dije du ipo Aarẹ lọdun 2023.
Sowore lo sọ ọrọ naa lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ nibi iwọde iranti EndSARS to waye nilu Eko.
Gẹgẹ bii ohun to sọ, irọ ni ijọba n pa pe ko si ẹnikankan to ku ni Lekki Toll Gate lasiko iwọde naa lọdun meji ṣeyin.
Amọ o ni awọn ti ṣetan lati tu aṣiri ijọba.
Sowore sọ pe “Ninu awọn ti wọn pa, wọn ti gbe oku wọn pamọ, ti awọn obi wọn ko si mọ ibi ti wọn wa.”
“O ṣe pataki ki awọn ọdọ mọ awọn ọrẹ wọn atawọn ọta wọn, awọn ọta wọn lo n pa wọn ni Toll Gate.”
“Lara awọn ọta wọn wa lara awọn to n gbe apoti ni 2023, ẹ ṣa mọ wọn.”
“To ba wu yin, ẹ lọ dibo fun awọn apaayan, o ku sọwọ yin.”
Ki lo ti ṣẹlẹ sẹyin?
Ọlọ́pàá ti ń yin gáàsì tajútajú sáwọn olùwọ́de ní Lekki Toll Gate

Awọn ọlọpaa kogberegbe ti yin gaasi tajutaju si awọn olwọde EndSARS niluu Eko.
Ṣaaju ji awọn oluwọde naa ti kọkọ ṣe iwọde kọja ni iloro naa, ti ko si si wahala kankan.
Lẹyin ti awọn eeyan ọhun kọja ni Toll Gate naa, wọn ṣe iwọde lọ si agbegbe ile itura Oriental, nibi bi ti Falze ti ba wọn sọrọ ni ṣoki.
Amọ lẹyin iṣẹju diẹ ni wọn pada si ẹnu iloro naa lati gbe posi ọwọ wọn kalẹ ni awọn ọlọpaa yin gaasi tajutaju si wọn lati tu iwọde naa ka.
Titi di asiko ti a n ko itoyin yii jọ, a ko tii le sọ boya ẹnikẹni farapa nibẹ.
Olùwọ́de EndSARS gbé pósí lọ ìloro Lekki fún ìrántí àwọn aláìsí lásìkò ìwọ́de

Lẹyin ọdun meji ti awọn ọmọ ogun ṣina ibọn bolẹ fun awọn oluwọde EndSARS ni iloro Lekki Toll Gate, niluu Eko, awọn oluwọde kan tun ti n ṣe iwọde mii nibẹ.
Awọn eeyan naa ti kọkọ kede pe awọn yoo ṣe iwọde ni iloro ọhun, amọ wọn ni ṣe ni awọn yoo ṣe iwọde kọja ni iloro naa dipo ki wọn korajọ nibẹ.
Ṣaaju ni awọn ọlọpaa ko gberegbe, Mopol, atawọn ẹka ileeṣẹ ọlọpaa mii ti kọkọ korajọ si iloro ọhun lati ri daju pe ẹnikẹni ko da ilu ru tabi ba dukia ijọba jẹ lorukọ iwọde naa.

Akọroyin BBC Yoruba to wa nibẹ jabọ pe awọn oluwọde ọhun gbe awọn posi kan dani bi wọn ṣe n wọde lati kẹdun awọn to ba iwọde naa lọ lọdun meji sẹyin.
Bẹẹ naa ni wọn n kọ oniruru orin aro lati ṣe idaro awọn ọmọ Naijiria to ku lati ọwọ awọn ọlọpaa.
Lara awọn gbajumọ to wa nibi iwọde ọhun ni ajafẹtọ to tun jẹ olorin takasufe, Folarin Falana, ti ọpọ mọ si Falz, Adebowale "Debo" Adedayo, ti ọpọ mọ si Mr Macaroni, atawọn eeyan mii.

Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ nibi iwọde naa, Mr Macaroni sọ pe awọn n ṣe iwọde yii lati jẹ ki ijọba mọ pe awọn ọdọ ko tii gbagbe ohun to ṣẹlẹ lọdun 2020.
Ẹwẹ, ohun to bẹrẹ iwọde EndSARS ko ṣẹyin bi awọn ọlọpaa to n gbogun idigunjale, SARS, ṣe n fi iya jẹ awọn aralalu lọna ti ko ba ofin mu.












