Liz Truss ní olóòtú ìjọba tí sáà rẹ̀ kéré jùlọ nínú ìtàn ilẹ̀ UK, ọjọ́ 45 ló lò nípò

Oríṣun àwòrán, PA Media
- Author, Olubayode Alebiosu
- Role, Broadcast Journalist
- Reporting from, Lagos
Eyi ni olootu ijọba kẹta ti ilẹ Gẹẹsi yoo maa ni larin ọdun kan.
Bi o tilẹ jẹ wi pe lọjọru ni Truss ṣi n sọ fun awọn araalu pe oloogbo ni oun, ẹyin oun kii balẹ bọrọbọrọ, amọṣa wahala to gbẹrẹgẹjigẹ ninu ijọba, igbimọ aṣofin ati ẹgbẹ oṣelu Conservative party to n ṣe’jọba ti mu ko ju ọwọ silẹ nigba ti ọrọ naa de oju ipo toun funrarẹ ti mọ pe oun ko lee tẹsiwaju mọ.
Liz Truss sọ ninu ọrọ rẹ pe oun ṣe ipade pẹlu Ẹniọwọ Graham Brady to jẹ alaga igbimọ 1922, awọn mejeeji si fi ẹnu ko peeto idibo lati yan adari yoo waye lọdun to n bọ.
O ni eyi yoo rii daju “pe a duro ṣinṣin lojuna ati mu ki awọn ipinnu wa fun iṣuna ati lati ṣe ato eto ọrọ aje ati eto abo orilẹede wa .”
Truss ni oun yoo ṣi di ipo olootu ijọba mu titi di igba ti wọn ba yan olotu ijọba tuntun ti yoo rọpo oun.

Oríṣun àwòrán, Reuters
Truss ni olootu ijọba ti saa rẹ kere ju ninu itan ilẹ Gẹẹsi
Liz Truss lo ọjọ marundinlaadọta nipo – saa to kere ju ti olotu ijọba kankan yoo lo nipo nilẹ Gẹẹsi. George Canning ni saa rẹ kere ṣekeji. Ọjọ mọkandinlọgọfa lo lo nipo ki o to ku lọdun 1827.
Wahala bẹrẹ fun iṣejọba Truss nigba ti minisita rẹ akọkọ Kwasi Kwarteng da họwuhọwu silẹ ni ọja iṣuna pẹlu eto iṣuna gba koo jẹ to fi lede lọjọ kẹtalelogun oṣu kẹsan an.
Lati igba naa, rukerudo ti n waye laarin ẹgbẹ oṣelu Conservative eyi to di wahala.
Ikọwefipo silẹ rẹ loni waye lẹyin oniruuru iṣẹlẹ nileegbimọ aṣofin keji nilẹ Gẹẹsi lalẹ ana nibi ti ọpọ awọn aṣofin nibẹ ti n pariwo pe ko maa lọ.
Starmer n bere fun eto idibo bi Truss ṣe n fipo silẹ

Oríṣun àwòrán, Robert timothy/bbc
Adari ẹgbẹ oṣelu Labour, Keir Starmer ti pe fun eto idibo apapọ tuntun “bayi” lẹyin ti Liz Truss kede pe oun fẹ fipo silẹ gẹgẹ bi olootu ijọba orilẹede naa.
Ẹniọwọ Starmer sọ pe o han gedegbe bayii pe: “Ẹgbẹ oṣelu Conservative party ti fihan pe awọn ko lẹnu lati ṣe ijọba.”
Adari ẹgbẹ oṣelu Labour naa sọ pe lẹyin ọdun mejila ni ijọba, awọn eeyan ilẹ Gẹẹsi lẹtọ si iṣejọba to gbadun ju eleyi ti a n ri yi lọ.
“A gbọdọ wa ọna fun ibẹrẹ lakọtun. A nilo eto idibo apapọ - bayii.”
Amọṣa, ọkan lara awọn minisita rẹ, Jeremy Hunt ti sọ pe oun ko ni dije fun ipo olori Conservative Party ati olotu ijọba ilẹ Gẹẹsi lẹyin ti Truss fi ipo silẹ.
Awọn olori orilẹede Lagbaye ti n sọrọ

Oríṣun àwòrán, Reuters
Awọn olori orilẹede kaakiri agbaye naa ti n sọrọ nipa iṣẹlẹ ikọwefiposilẹ olootu ijọba ilẹ Gẹẹsi yii.
Aarẹ orilẹede France, Emmanuel Macron sọ pe o ṣe pataki kiilẹ Gẹẹsi wa ọna “fun iduroṣinṣin rẹ ni kopẹkopẹ.”
Macron sọ fawọn akọroyin lasiko to gunlẹ si ilu Brussels fun apero ajọ awọn orilẹede Yuroopu nibẹ.
“Nitemi, ibanujẹ lo maa n jẹ fun mi lati rii oluku mi kan ko fi iṣẹ silẹ.
Liz Truss, Olóòtú ìjọba ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì kọ̀wé fipò sílẹ̀
Olotu ijọba ilẹ Gẹẹsi, Liz Truss ti kọwe fi ipo rẹ silẹ lẹyin ọjọ marundinlaadọta lori oye.
Nigba to n sọrọ niwaju ile ijọba ilẹ Gẹẹsi ni Downing Street, Liz Truss sọ pe oun ti fi ọrọ naa to Ọba Charles ti ilẹ Gẹẹsi pe oun n fi ipo silẹ gẹgẹ bi olori ẹgbẹ oṣelu Conservative party.
Liz Truss sọ pe asiko ti ọrọ aje dagun ti ọrọ oṣelu lagbaye si n ṣe ṣibaṣibo loun tẹri gbe ẹru ijọba ati pe ohun ti ẹgbẹ oṣelu oun yan oun lati yi pada ni ifasẹyin ọpọlọpọ ọdun to ti de ba orilẹede naa.
O ni iṣejọbva oun kogoja lori owo ina ati agbekalẹ ilana tuntun fun eto ọrọ aje nipa agekuro owo ori gegele.
“Mo rii pe, pẹlu bi nnkan ṣe ri bayii, mi o lee ṣe aṣeyọri lori ohun ti ẹgbẹ oṣelu Conservative party fi yan mi.”












