"Ìbọn ṣọ́jà ló kán mi lẹ́sẹ̀ lásìkò ìwọ́de EndSARS"

Oyemai Steven Asihamen

Oríṣun àwòrán, Oyemai Steven Asihamen

    • Author, Faoziyah Saanu-Olomoda
    • Role, Broadcast Journalist

Ní ọjọ́ Kọkàndínlógún, oṣù Kẹwàá, ọdún 2020 ni ọkùnrin kan lọ darapọ̀ mọ́ àwọn tó ń ṣe ìwọ́de ìfẹ̀hónúhàn #Endsars ní ìlú Auchi, ìpínlẹ̀ Edo.

Àmọ́ ọgbẹ́ ìbọn ṣójà ló gbé kúrò níbẹ̀.

Oyemai Steven Asihamen tó jẹ́ ẹni ọdún mọ́kàndínlọ́gbọ̀n ní ilé ẹ̀kọ́ gbogbonìṣe poly ni òun wà nígbà náà.

Ó ní òun tẹ̀lé àwọn ọ̀rẹ́ òun láti lọ ṣe ìwọ́de tako bí àwọn ọlọ́pàá ṣe ń tẹ ẹ̀tọ́ àwọn ènìyàn lójú mọ́lẹ̀.

Ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ló mu kí ó pàdánù ẹsẹ̀ kan àmọ́ ó ní òun kò kábàmọ́ wí pé òun kópa nínú ìwọ́de ọ̀hún.

"Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ló bú mi pé kí ni mo wá lọ sí ibi ìfẹ̀hónúhàn náà, wọ́n ní kí ni mò ń wá kiri."

"Àwọn mìíràn ti ẹ̀ sọ fún mi pé mi ò gbọdọ̀ pé àwọn fún ìrànlọ́wọ́ nítorí àwọn kọ́ ló rán mi níṣẹ́ láti kópa nínú ìwọ́de #Endsars."

"Ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan ni mo ti pàdánù nítorí ẹsẹ̀ mi"

Oyemai Steven Asihamen

Oríṣun àwòrán, Oyemai Steven Asihamen

"N kò tíì rí kọ́bọ̀ gbà gẹ́gẹ́ bí owó gbà mábínú lọ́wọ́ ìjọba"

Steven ṣàlàyé pé yàtọ̀ sí ẹsẹ̀ òun tí òun pàdánù lásìkò náà, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àǹfàní ló ti fo òun ru nítorí ẹsẹ̀ òun tí kò pé mọ́.

Ó ní ó yẹ kí òun ti kúrò ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà báyìí nítorí ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀rẹ́ òun tí àwọn jọ bẹ̀rẹ̀ ìgbésẹ̀ náà, ti wà ní àwọn orílẹ̀ èdè bíi Germany àti South Africa.

Ó fi kun pé láti ọdún 2006 ni òun ti kọ́ nípa iṣẹ́ aṣọ fífọ̀ àti lílọ̀ ṣùgbọ́n tí òun kò fi ṣe iṣẹ́ ṣe.

Àmọ́ ó ní láti ìgbà tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti wáyé ni òun tu owó jọ láti ṣí ṣọ́ọ̀bù aṣọ lílọ̀ àti fífọ̀.

Ó ṣàlàyé pé ìdí tí òun fi gbé ìgbésẹ̀ náà ni pé àgbẹ̀ ni àwọn òbí òun, tí òun kò sì le máa wojú wọn kí òun tó jẹun.

Steven tẹ̀síwájú pé òun yọjú sí ìgbìmọ̀ tí ìjọba gbé kalẹ̀ láti wádìí ìṣẹ̀lẹ̀ ìfìyàjẹni àwọn ọlọ́pàá lẹ́yìn ìwọ́de yìí, tí òun sì ṣàlàyé ara òun fún wọn.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó kàn sárá sí ìjọba ìpínlẹ̀ Edo fún àgbékalẹ̀ ìgbìmọ̀ náà, ó ní títí di àsìkò yìí òun kò ì tíì rí kọ́bọ̀ gbà gẹ́gẹ́ bí owó gbà mábínú.

Kí ló ṣẹlẹ̀ lásìkò ìwọ́de #Endsars?

Àwọn olùfẹ̀hónúhàn #Endsars
Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Nínú oṣù Kẹwàá ọdún 2020 ni àwọn ọ̀dọ́ káàkiri Nàìjíríà bẹ̀rẹ̀ ìwọ́de ńlá láti fẹ̀hónúhàn lórí bí àwọn ọlọ́pàá tó ń gbógunti ìwà olè jíjà (SARS) ṣe ń lọ́ àwọn ọ̀dọ́ lọ́wọ́ gbà, tí wọ́n sì ń tẹ ẹ̀tọ́ àwọn ènìyàn lójú mọ́lẹ̀.

Àwọn olùfẹ̀hónúhàn náà ní àwọn ń fẹ́ kí ìjọba àpapọ̀ wọ́gilé SARS nítorí bí wọ́n ṣe máa ń gba owó lọ́wọ́ àwọn ọ̀dọ́ lọ́nà àìtọ́, yẹ fóònù wọn wò.

Ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ yìí ló lọ sí ọ́fíìsì àwọn gómìnà káàkiri ìpínlẹ̀ wọn láti fẹ̀hónú wọn hàn tí wọ́n sì ń bèèrè fún àyípadà gidi.

Lára àwọn òpópónà ńlá tí àwọn olùfẹ̀hónúhàn ọ̀hún dí pé àwọn ènìyàn kò ní kọjá àyàfi tí ìjọba bá dá àwọn lóhùn ni tollgate Lekki, afárá Ojota ní ìpínlẹ̀ Eko, Afárá Berger ní Abuja àti ráúndàbaòtù Okigwe ní ìpínlẹ̀ Imo.

Ní ọjọ́ kẹjọ, oṣù kẹwàá ni ìwọ́de ìfẹ̀hónúhàn náà bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú pẹ̀lẹ́ kùtù àmọ́ tó di wàhálà lẹ́yìn tí àwọn jàǹdùkú bẹ̀rẹ̀ sí ní kópa nínú rẹ̀ tí wọ́n sì ń bá àwọn ohun ìní ìjọba àti ti aládani jẹ́.

Amnesty International ní kò dín ní ènìyàn àádọ́ta tó pàdánù ẹ̀mí wọn níbi ìwọ́de náà. Human Right Watch ó ṣeéṣe kí ènìyàn tó kú ní tollgate Lekki.

Káàkiri Nàìjíríà ni àwọn ènìyàn ti forí sọ̀tà ìwọ́de yìí tí Steven náà sì jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tó lùgbàdì ti ìpínlẹ̀ Edo, tí ẹsẹ̀ rẹ̀ kan lọ si.

Kí ló ṣẹlẹ̀ ní Tollgate Lekki?

Àwọn olùfẹ̀hónúhàn #Endsars

Lára awuyewuye ńlá tó wáyé lásìkò ìwọ́de #Endsars ni bí àwọn ọmọ ogun ṣe dáná ìbọn yá àwọn olùfẹ̀hónúhàn ni Tollgate Lekki.

Àwọn olùfẹ̀hónúhàn kan sọ wí pé àwọn ènìyàn kú ṣùgbọ́n ìjọba Nàìjíríà ní ẹnikẹ́ni kò pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ sínú ìṣẹ̀lẹ̀ náà.

Mínísítà fétò ìròyìn àti Àṣà, Lai Muhammed ní kò sí bí ìpànìyàn yóò ṣe wáyé láì ní sí àwọn òkú láti ṣàfihàn rẹ̀.

Iléeṣẹ́ ológun ní àwọn yìbọn lóòótọ́ àmọ́ kìí ṣe èyí tó le gbẹ̀mí ènìyàn.

Lónìí, ogúnjọ́, oṣù Kẹwàá ló pé ọdún méjì tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáyé tí àwọn ọmọ Nàìjíríà sì ti ń kọ ọ̀rọ̀ sórí ayélujára láti fi ṣàmì àyàjọ́ ọdún méjì ìṣẹ̀lẹ̀ náà.