"Ẹ̀kún omi yóò mú ebi pa ìyàwó mi méjèjì àtàwọn ọmọ wa mẹ́tàlá"

Ahmed Ubale Miga
Àkọlé àwòrán, Ahmed Ubale Miga padanu oko ati ile rẹ sinu omiyale

Gẹgẹbi gbogbo awọn agbẹ, Ahmed Ubale Miga, ẹni ọdun marundinlaadọta gbin ohun ọgbin rẹ lasiko ti ojo bẹrẹ loṣu diẹ sẹyin.

Amọṣa lọwọ yii oun pẹlu wa lara awọn ẹgbẹlẹgbẹ agbẹ kaakiri orilẹede Naijiria to n figbe ta lẹyin ti isẹlẹ ẹkun omi ba oko wọn jẹ.

Ẹkun omi yii si tun wọ gbogbo ireti ipese ounjẹ lọdun yipo danu.

Omiyale ti fa ọpọlọpọ wahala lorilẹede Naijiria laarin ọṣẹ diẹ sẹyin, eyi to ti pa ọpọlọpọ eeyan, ti omilẹgbẹ miran si ti ti alarinka ati alainilelori.

“Ohun to wa lọkan mi bayii ni bi maa ṣe ri ounjẹ bọ awọn ẹbi mi lọdunyipo"

Ipinlẹ Jigawa, nibiti Ahmed n gbe, wa lara awọn ipinlẹ ti ọṣẹ omiyale yii ti mulẹ julọ.

Bo si ti jẹ pe awọn agbẹ lo pọ nipinlẹ naa, ọpọ awọn idile ni yoo pebi mọnu bayii nitori omiyale ti gba awọn nnkan oko wọn lọ.

“Omiyale to buru julọ niyi lati igba ti mo ti dele aye, mo si ti ba awọn agbalagba ti ọjọ ori wọn ti le laadọrin ọdun ni ilu wa sọrọ, ohun ti wọn sọ ni pe awọn naa ko ri irufẹ omiyale bẹẹ ri.”

“Ohun to wa lọkan mi bayii ni bi maa ṣe ri ounjẹ bọ awọn ẹbi mi lọdunyipo lai si awọn ere oko ti mo gbin. Iyawo meji ni mo fẹ, mo si bi ọmọ mẹtala, oko ni mo si fi n bọ wọn. Eyi ko mọ awọn mọlẹbi mi yooku o.”

Agbẹ naa tun sọrọ nipa ile rẹ to ni ẹkun omi gbe lọ eyi to ni o mu ki idile oun o wa ibomiran lọ fun gbigbe.

Agbegbe kan ti ẹkun omi waye
Àkọlé àwòrán, Arọọrọda ojo lo fa omiyale naa kaakiri ipinlẹ mẹtalelọgbọn ni Naijiria

Bi o ṣe ṣẹlẹ

Ọgbẹni Ahmed ṣalaye pe ṣaaju ẹkun omi naa eyi to ba gbogbo nnkan jẹ ọsẹ mẹta sẹyin ti ojo arọrọda kan rọ ni Miga to ta wọn lolobo pe ewu n bọ.

O ni wọn ko iyanrin sinu ọpọlọpọ apolati fi wọn daabo bo awọn agbegbe ti ko ṣe daradara to ni ilu naa ti wọn mọ pe omi le gba wọnu ilu naa.

“Ni igba yii, ile wa wa lọkan wa, kii ṣe oko mọ nitori pe ohun akọkọ to yẹ funwa lati ṣe ni lati daabo bo ile wa.”

O ni lẹyin ti wọn ko awọn apo to kun fun iyanrin yii jọ ni ojo ba bẹrẹ lọjọ Ẹti kan ni nnkan bii agogo mẹrin irọlẹ.

Ojo yii lo rọ fun igba pipẹ to si ba ọpọ ile jẹ, titi kan ile ti oun naa ati ọpọlọpọ oko.

‘A ko tii ri iranwọ latọdọ ijọba’

Ahmed ni lọjọ diẹ sẹyin lawọn oṣiṣẹ kan wa si agbegbe naa lati wa gba akọsilẹ nipa ohun to ṣẹlẹ, ti wọn si sọ pe awọn yoo ṣe iranwọ fun awọn eeyan to fara gba omiyale naa.

O ni awọn ko tii ri ohunkohun lati ọdọ ijọba bayii.

O ni ile ẹkọ kantabi ọdọ awọn aladugbo ti nnkan ko ṣe ile wọn loun atawọn eeyan ti ajalu naa ba n sun si lati igba ti iṣẹlẹ naa ti ṣẹlẹ.

Kaakiri Naijiria ni ajalu yii kan

Aworan atẹjade oju opo ori ayelujara

Lati ẹkun ariwa titi de ẹkun gusu ni ajalu ẹkun omi tan kalẹ de.

Oniruuru fidio ati fọto lo n kun ori ayelujara nipa awọn eeyan to ti fara kaasa ajalu omiyale kaakiri orilẹede Naijiria.

Ipinlẹ Kogi lẹkun aringbungbun ariwa pẹlu wa lara awọn agbegbe ti wahala omiyale yii ti gbilẹ julọ ti omi si ti bo opopna to so ipinlẹ naa pọ mọ ilu Abuja atawọn agbegbe oke ọya.

Nipinlẹ Bayelsa, gomina Douye Diri ti tọka si iṣẹlẹ naa gẹgẹgbi ipenija nla pẹlu bi omiyale ti ṣe ti le awọn eeyan kuro nile wọn ni ọdunrun ilu nipinlẹ naa.

Aarẹ Buhari ti paṣẹ agbekalẹ iranwọ

Aarẹ orilẹede Muhammadu Buhari ti paṣẹ pe ki gbogbo awọn ajọ to yẹ o tete gbe igbesẹ lati sa ipa gbogbo to yẹ fun iranwọ awọn eeyan ti omiyale ti da igbe aye wọn ru kaakiri orilẹede Naijiria.

Ninu ọrọ to fi soju opo Twitter rẹ, Buhari sọ pe ọṣẹ ẹkun omi naa ti da ibanujẹ nla si oun lọkan.

Aarẹ Buhari ni ipinlẹ mẹtalelọgbọn ninu mẹrindinlọgbọn to wa ni Naijiria titi kan Abuja tii ṣe olu ilu Naijiria ni ọwọja ẹkun omi naa ti de.