Ológun dòòlà àwọn arìnrìn àjò tó bọ́ sọ́wọ́ ajínigbé, wọ́n pa gbajúmọ̀ àjínigbé mẹ́ta

Oríṣun àwòrán, Getty Images
- Author, Akinlabi Afolabi
- Role, Broadcast Journalist
Ileeṣẹ ọmọ ologun ti kede pe awọn ti dola ẹmi awọn arin irinajo kan tawọn ajinigbe jigbe ni opopona Kaduna si Zaria.
Isẹlẹ naa waye lẹyin ti wọn gba ipe pe awọn ajinigbe naa ti ṣe ọṣẹ́.
Ninu atẹsita kan ti wọn fi ransẹ si awọn akọroyin, agbẹnusọ ileeṣẹ ọmọ ologun, Onyemi Nwachukwu ni bakan an ni wọn ṣekupa awọn ajinigbe mẹta nigba ti wọn wọ iyaja pẹlu wọn.
O ni agbegbe abule Abasia Amale ni ijọba ibilẹ Gwari ni ipinlẹ Kaduna.
Onyema ni awọn gba awọn ohun ija ibọn AK47, ọta ibọn ati ẹrọ ibanisọrọ lọwọ awọn ajinigbe naa.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Ajinigbe yinbọn mawọn arinrinajo, ji ọpọ wọn gbe lọ - Ologun
Iroyin to tẹ awọn ọmọ ologun lọwọ lowurọ Ọjọbọ ni pe awọn agbebọn naa ti gbegi dana opopona Kaduna si Zaria.
Bakan naa la gbọ pe wọn sina ibọn bolẹ fawọn arin irinajo to n kọja, ti wọn si tun ji ọpọlọpọ gbe lọ.
O ni kete ti ileeṣẹ ọmọ ologun gbọ, ni wọn sure lọ sibẹ, ti wọn si gbena wo oju awọn ajinigbe naa.
Igbesẹ naa si lo se okunfa bi awọn ajinigbe mẹta ṣe jade laye, ti ọpọ mii si farapa.
Ọgagun Faruk Yahaya ti wa kan sara si awọn ọmọ ologun naa, fun isẹ ribiribi ti wọn ṣe lati dola ẹmi awọn arinrin ajo naa.
Akẹ́kọ̀ọ́ India yọ póńpó tàwọn akẹ́kọ̀ọ́ adúláwọ̀, ìjọba kó akẹ́kọ̀ọ́ Nàíjíríà 86 pamọ́

Oríṣun àwòrán, Screenshot
Ìjọba Naijiria ti bẹrẹ iwadii si ikọlu ti awọn ọmọ orile-ede India kan ṣe si àwọn akẹ́kọ̀ọ́ adulawọ, ninu eyi ti ọmọ Naijiria wa ninu wọn.
Fasiti kan ni orilẹede India ni isẹlẹ naa ti waye.̀Ọjọ Aje ni fidio kan gba ori ayelujara, eyi to safihan bi wọn ṣe n fi igi ati orisirisi nkan ija mii lu awọn akẹkọọ náà. Bakan naa ni fidio ọhun safihan bi awọn akẹkọọ naa ṣe n sa asala fun ẹmi wọn. Alaga ajọ to n ri si ọrọ àwọn ọmọ Naijiria nilẹ okeere, Arabinrin Abike-Dabiri Erewa, sọ pe ọjọ́ Aiku ni iṣẹlẹ naa waye.
Akẹkọọ ọmọ Naijiria mẹrindinlaadọrun ni ileeṣẹ aṣoju Naijiria ni India ko pamọ nitori wahala naa
Ninu atẹjade kan to fi si oju opo Twitter rẹ, Dabiri-Erewa sọ pe ọjọ Abamẹta to kọja ni iṣẹlẹ naa waye lẹyin ede aiyede kan ni papa ìṣeré bọọlu.
Isẹlẹ naa si lo waye laarin awọn akẹkọọ to jẹ ọmọ Africa ati àwọn to jẹ India. O ni ọmọ Naijiria mẹrindinlaadọrun ni ileeṣẹ aṣoju Naijiria ni India ko pamọ nitori wahala naa. Arabinrin Erewa sọ pe ijọba India mu dá awọn aṣoju Naijiria loju pe aabo yoo wa fun awọn akẹ́kọ̀ọ́ naa. Eyi to mu ki wọn o pada si ile ẹ̀kọ́ wọn lọjọ Aiku. O ni lootọ ni awọn kan farapa, sugbọn iwadii ti n waye. Bakan naa lo sọ pe wọn jẹ ko ye ijọba India pe àwọn ni yoo jẹ́jọ́ ti nkan buruku ba fi sẹlẹ si ọmọ Naijiria kankan.
Ki lo se okunfa ikọlu ?
Iroyin sọ pe ìkọlu naa waye ni papa ìṣeré Fasiti GD Goenka n'ilu Haryana, ti ko fi bẹẹ jina si New Delhi, olu ilu India. A gbọ pe awọn akẹkọọ fasiti naa to jẹ ọmọ Africa, ninu eyi ti Naijiria wa lara wọn, lo kọkọ n gba bọọlu lori papa naa. Sugbọn awọn akẹẹgbẹ wọn to jẹ ọmọ India sọ fun wọn pé ki wọn fi papa ìṣeré naa silẹ fun awọn nitori pe awọn ni ojulowo ẹgbẹ́ agbabọọlu fasiti naa. Ọ̀rọ̀ yii ni iroyin sọ pe o di ede aiyede, to fi di pe àwọn akẹkọọ ọmọ India bẹ̀rẹ̀ si kọlu àwọn ọmọ Africa. Àmọ́ BBC ko le fi idi iroyin naa mulẹ pe oun ni orisun ìkọlu ọhun.












