Ìgbà méjì ni mo gún Ataga lọ́bẹ àmọ́ mo ti kúrò nílé ìtura kó tó kú – Chidinma

Ọjọ Isẹgun tun ni igbẹjọ tẹsiwaju lati se awari ẹni to pa ọga agba ileesẹ Super TV, Usifo Ataga.
Chidinma Ojukwu, ti wọn fẹsun kan pe o ṣekupa ọkunrinnaa ti wa salaye pe oju oun kọ ni ọkunrin naa se ku.
Ninu fidio kan ti wọn fi lede nile ẹjọ gẹgẹ bi ẹri maa jẹ mi n ṣo, Chidinma ni oloogbe naa ṣi wa laaye lasiko ti oun kuro ninu ile ti awọn wọ si ni Lekki.
Chidinma ati Adedapo Quadri lo n kawọ pọnyin rojọ niwaju adajọ lori ẹsun ipaniyan, iditẹpani ati ole jija.
Nigba ti Chioma Egbuchu n koju ẹsun jiji ẹrọ ilewọ oloogbe naa.

Ki lo wa ninu fidio ti Chidinma mu wa sile ẹjọ?
Ninu fidio naa ni ọlọpaa kan, DSP Olusegun Bamidele ti fi ọrọ wa Chidinma lẹnuwo.
Ninu fidio naa ni afurasi ọhun ti sọ pe oun salọ nigba ti ẹjẹ n da ṣuuru lara oloogbe naa lasiko ti oun pada sinu ile ti wọn gba.
Ọlọpaa wa bere lọwọ rẹ eredi ti ko ṣe ke sita ki wọn le doola ologbe ọhun, o ni ẹru lo ba oun ti oun fi salọ.
Wọn tun beere lọwọ nipa ẹrọ ilewọ iPhone Ataga, o ni oun ko mọ bi ẹrọ ilewọ naa ṣe rin.
Lẹyin naa lo sọ pe oun ko le ṣekupa ẹnikẹni, ati pe oloogbe naa ṣi wa laye lasiko ti oun fi ile itura ti wọn ti ba oku rẹ silẹ.
Alaye mii latẹnu ọlọpaa

Bamidele sọ fun ile ẹjọ naa lẹyin ifọrọwanilẹwo akọkọ pẹlu Chidinma pe, awọn mu afurasi naa lọ sinu yara miran lati sọrọ.
O ni afurasi ọhun sọ pe oun ati oloogbe naa mu siga ati ọti, lẹyin naa ni wọn ni ibalopọ.
DSP Bamildele ni Chinma sọ pe oloogbe naa gbiyanju lati ba oun ni ibalopọ siwaju si amọ oun kọ, ti oun si ti danu eyii to mu ko gba ori mọlẹ.
Ọlọpaa naa ni “O ṣo pe oloogbe ọhun tun pada wa, wọn bẹrẹ ijakadi nitori ibalopo naa, amọ oun gun ni ọbẹ ni ọrun.”
Bamidele ni, Chidinma sọ pe Ataga ṣi lagbara lati bori oun, lo jẹ ki oun fi okun de ọwọ rẹ, ti oun si gun lọbẹ nigba keji.
Ọlọpaa naa fi kun pe Chidinma kọ ọrọ rẹ silẹ pe lootọ ni oun pa Ataga.
Ibi ti ẹjọ naa de duro bayii
Ọdun to kọja ni igbẹjọ naa bẹrẹ lẹyin ti wọn ṣawari oku oloogbe naa ninu ile itura ti oun ati Chidinma ti pade.
Ki wọn to ri oku rẹ ni wọn ti kọkọ n wa lẹyin ti awọn ẹbi ati alabaṣiṣẹ rẹ n pe aago ilewọ rẹ amọ ti ko gbe.
Alabaṣiṣẹ rẹ kan, Raman Obiorah sọ fun ile ẹjọ pe ṣe ni wọn pa ọkunrin naa bii igba ti eeyan ba pa adiyẹ lasan.
Ẹlẹri mẹsan an lo ti yọju sile ẹjọ lori ọrọ naa bayii.
Ẹwẹ, adajọ Yetunde Adesanya ti sun ẹjọ naa si ogunjọ, ọjọ karundinlọgbọn ati ọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu Kẹsan an yii fun itẹsiwaju rẹ.
Inu oṣu Kẹfa, ọdun 2021 ni Ataga jade laye.















