EndSARS kò tíì tán torí ìjọba kò tíì fi ọlọ́pàá àrúfin kankan jófin - Mr Macaroni
EndSARS Protest Remembrance: Macaroni ní ìhùwàsí ìjọba kò fihàn pé ó ń ṣòótọ́

Iyan ogun ọdun, a maa jo ni lọwọ bẹẹ si ni ọrọ kii tan.
Isẹlẹ manigbagbe, ti yoo wa ni iranti awọn ọmọ orilẹede Naijiria, ni iwọde EndSARS jẹ, paapaa lẹkun guusu orilẹede yii.
Iwọde naa, to waye losu kẹwa ọdun 2020 ni awọn ọdọ fi n tako iwa ifijajẹni ti ikọ ọlọpaa to n gbogun ti iwa idigunjale (SARS) n hu si wọn laarin ilu.
Awọn ọdọ naa si lo tu jade lọpọ yanturu fun bi ogunjọ lati fi ẹhonu han tako iwa ibajẹ awọn ọlọpaa SARS naa, ti wọn si n beere pe ki ijọba tu wọn ka.
Idi ree ti wọn fi pe akori iwọde naa ni EndSARS.
Gbogbo awọn olu ilu awọn ipinlẹ to wa ni guusu Naijiria atawọn ilu nla nla miran ni awọn ọdọ naa kora jọ si lati fi ẹhonu han.
O ti pe ọdun meji bayii ti iwọde EndSARS waye
Lara ibudo ti wọn si korajọ si lati se iwọde ni ẹnu iloro Lekki to wa nilu Eko, ti wọn si dena lilọ bibọ ọkọ ati ero lopopona naa fun ọ́jọ melo kan.
Amọ nigba to di ogunjọ osu Kẹwa ọdun 2020 naa, ni awọn ologun ya bo awọn ọdọ naa lẹnu iloro Lekki naa, ti awọn eeyan kan sì kú, tí ọ̀pọ̀ mii si ṣese.
Eyi lo mu kawọn janduku ja iwọde naa gba lọjọ keji, ti wọn si n jo awọn dukia ijọba ati ti aladani, to fi mọ awọn agọ ọlọpaa kaakiri awọn ipinlẹ lkun guusu Naijiria.
Nibayii to ti wa pe ọdun meji ti iwọdeEndSARS naa waye, BBC Yoruba ba ọkan lara awọn asaaju ọdọ to sakoso iwọde naa, Debo Adedayo sọrọ lati mọ boya erongba wọn lori iwọde naa ti jọ.
"Ki lo de ti ijọba fi ni abọ igbimọ iwadii lori ohun to se okunfa iwọde EndSARS ko bojumu?"
Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, Debo Adedayo, ti ọpọ eeyan tun mọ si Mr Macaroni sọ pe Endsars ko tii tan o.
Macaroni ni gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu ti jẹjẹ tẹlẹ pe gbogbo awọn eeyan to sokunfa iwọde naa ni awọn yoo fi jofin.
Amọ o ni titi di akoko yii, awọn ko tii gbọ nnkan kan.
"Gbogbo igba ta ba ni anfaani lati sọrọ lọ sibi iwọde Endsars la maa sọrọ nipa rẹ, lati mu awọn alasẹ lọrun ọwọ lori iwọde naa.
Ijọba ipinlẹ Eko lo gbe igbimọ oluwadi kalẹ lati sewadi ohun to waye nipa isẹ awọn ọlọpaa Endsars.
Lẹyin ijoko wọn, wọn gbe abọ iwadii wọn kalẹ amọ lẹyin o rẹyin, ijọba ni abọ iwadii naa ko kunju iwọn to, ki lo fa eleyi?"
"A le sọ pe iwa ifiyajẹni awọn ọlọpaa ti dinku diẹ amọ o si n sẹlẹ"
Macaroni ni o ti foju han pe abọ iwadi igbimọ naa ko tẹ ijọba lọrun ni wọn se ni ni ko ri bẹẹ.
O fikun pe gbogbo ihuwasi ijọba yii lo fihan pe kii se ijọba otitọ, se ni wọn n fi igba kan bọ ọkan ninu, eyi ko si dara.
"A le sọ pe iwa ifiyajẹni awọn ọlọpaa ti dinku diẹ amọ o si n sẹlẹ.
Lọwọ lọwọ bayii, a si tun n gbọ nipa iwa kotọ tawọn ọlọpaa n hu bii ki wọn fipa gba owo lọwọ araalu, ki wọn lu araalu ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Gbogbo ọnakọna ta ba si ni la fi maa ba ijọba sọrọ lai mu ija ati rogbodiyan lọwọ."
"A ko sọ pe gbogbo ọlọpaa ni ko dara amọ awọn to n hu iwa aidaa ni ko yiwa pada
Debo Adeyinka tun tẹsiwaju pe bi araalu ba n sọrọ, o yẹ ki ijọba maa gbọ lati dena biba araalu jẹ.
O wa seleri pe gbogbo titako iwa ti ko kọ lawujọ si lawọn maa se, titi ti awujọ wa yoo fi dara.
"Awa ko fẹ ifiyajẹni kankan mọ lati ọdọ ọlọpaa, a ko sọ pe gbogbo ọlọpaa ni ko dara amọ awọn to n hu iwa aidaa ni ko yiwa pada.
Kii se pe a fẹ ki nnkan buru fawọn ọlọpaa, ọmọ Naijiria ni awọn naa, ara ipese eto idẹrun fun wọn naa si wa lara ohun ta n ja fun."






