EndSars Protest slang: Kíní ìtumọ̀ Sọ̀rọ̀ Sókè tí àwọn afẹ̀họ́núhàn EndSars ń lò káàkiri

Oríṣun àwòrán, Small Doctor
Ojọgbọn imọ Ede Yoruba, Bisoye Ẹlẹsin ti salaye fun BBC idi ti ''Sọrọ Soke'' ṣe di akanlo ede lorilẹ-ede Niajiria lasiko ifẹhọnuhan tako ifiyajẹni ọlọpaa kaakiri orilẹede Naijiria.
Eyi ko ṣẹyin bi awọn ọdọ ni ipinlẹ Eko ṣe pariwo fun gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu lati ''sọrọ soke'' lasiko to n ba awọn ọdọ afẹhọnuhan sọrọ nipinlẹ Eko.
Lati igba naa ni awọn afẹhọnuhan EndSars ti bẹrẹ si ni lo ọrọ naa kaakiri, to fi mọ oke okun.
Kíní ìtumọ̀ Sọ̀rọ̀ Sókè tí àwọn afẹ̀họ́núhàn EndSars ń lò káàkiri:
Bisoye Ẹlẹsin to ba BBC Yoruba sọrọ ni ede lagbara lawujọ nitori naa ni ede asa ṣe n jade ninu ọrọ ti awọn eniyan ma n lo.
O ni bi ede ṣe n gbooro si ni agbegbe kan ni awọn eniyan a maa lo bi o ṣe wulọ si fun ohun ti wọn nilo rẹ fun.
''Ẹwa ede ni ki awọn eniyan lo gẹgẹ bi ọrọ asa(slang) lawujọ fun iwulo wọn''
Imọ wa ti ko pọ nipa ede lo jẹ ki a maa tẹmbẹlu rẹ''
Nibayii, sọrọ soke ti di akanlọ ede, eleyii to tumọ si wi pe awọn eniyan ti n lo o ju bi a ṣe mọ ọ si lọ
Bawo ni aṣe le lo ''Sọ̀rọ̀ Sókè'' tí àwọn afẹ̀họ́núhàn EndSars ń lò káàkiri
- Ojọgbọn imọ Ede Yoruba, Bisoye Ẹlẹsin ni ''sọrọ soke'' bayii ti tunmọ si ki eniyan ṣe ohun to tọ lasiko laifaṣẹyin
- Ki eniyan dide ni kanmọ ko gbe igbeṣẹ to yẹ
- ṣiṣe ojuṣe gẹgẹ bi ijọba
- Awọn ọrọ to tun dabi rẹ ni gbohun soke, gbohun safẹfẹ- eleyii to tun mọ si pe atẹgun ni ọrọ, afẹfẹ lo n gbe kaakiri.
Awọn eniyan gboogi wo lo ti ''Sọrọ Soke'' ni Ilẹ Yoruba?
Obafemi Awọlọwọ
Obafemi Awolowo jẹ ọkan gboogi lara awọn to ja fun ominira orilẹede Naijiria, ti o ''sọrọ soke'' nigba aye rẹ lori aṣemaṣe ti ijọba n ṣe nigba naa.
Lara awọn sọrọ to sọ ni pe '''awọn ọlọla ni orilẹede Naijiria yoo wọ wahala ti wọn ko ba tọju awọn alaini ati awọn mẹkunu to wa ni awujọ.
Olusegun Obasanjọ
Olusegun Obasanjo to ti fi igba kan jẹ adari orilẹede Naijiria ma n sọrọ soke lati igba de igba, ti yoo si tọka si awọn ohun ti ko tọ ti ijọba to wa lode n ṣe ati ọna abayọ si iṣoro to n koju orilẹede Naijiria.
Baba Obasanjo ni orilẹede Naijiria ni ohun alumọni to jẹ wi pe ko yẹ ki iya ati iṣẹ ma a jẹ ẹnikẹni.
Nitori naa Niajiria yoo gbe igbesẹ to yẹ nigba ti asiko ba tọ lati ri wi pe iṣẹ dopin ni Naijiria.
Wole Soyinka
Ọjọgbọn ati onkọwe Wole Soyinka jẹ eniyan kan gboogi to n fa fun ẹtọ awọn ọmọ Niajiria, awọn alawodudu nile ati loko ni ọpọlọpọ igba.
Lara awọn ọrọ to ti sọ lati fi soro sọke ni pe'' gbogbo eniyan lo lẹtọ si idajọ ododo, ati ẹtọ ọmọniyan'', '' orilẹede Naijiria ti la iṣọrọ kọja nitori awọn onijẹgudujẹra, o si ti su wọn.''.
Pasitọ David Oyedepo
Lọpọ igba ni pasitọ David Oyedepo ti ma n sọrọ soke tako ijọba paapaa lori eto abo,ẹsin ẹlẹyamẹya ni Niajiria.
Laiko aarun Coronavirusw yii ni Oyedepo bu ẹnu atẹ lu ijọba aarẹ Muhammadu Buhari lori bi o ṣe gba ki ọja maa si , amọ ki awọn eniyan ma lọ si ile ijọsin.
Pasitọ Enoch Adeboye
Ni ọpọlọpọ igba naa ni adari ijọ Redeem, Pasitọ Enoch Adeboye ti ma n kesi awọn eniyan to wa nipo lati ṣe ohun to tọ lawujọ, ti yoo tun sọrọ nipa idile ati igbe aye onigbagbọ.
Laipẹ yii lo ke si aarẹ Buhari lati ṣe kanmọ nipa atunto orilẹede Naijiria, ki o ma ba pin yẹlẹyẹlẹ.















