ENDSARS: Nítorí ìwọ́de #EndSARS, ìjọba gbé iléèwé tì pa ní Oyo, Ekiti, Ondo, Eko, Edo, Plateau àti Osun

Lọwọ lọwọ yii ipinlé Osun, Ondo, Ekiti, Eko, Plateau, Edo ti gbe ilọkun ile iwe ti pa.
Koda, ipinlẹ́ Ogun ti ni ojoojumọ ni ijọba oun yoo maa satunse ofin alakale, ti yoo mu ki alaafia joba lasiko iwode #End SARS to ti n bi ige ati Adubi kaakiri Naijiria bayii.
Ọrọ iwọde #EndSARS to bẹrẹ bi ipe alaafia awọn ọdọ fun ijọba lati dẹkun iwa aitọ awọn ọlọpaa, paapaa, ikọ SARS ti wa di wahala to n mu ki ijọba o maa kaya soke lori igbayegbadun araalu.
Ni Ọjọ Aje awọn janduku ni ipinlẹ Edo ya bo awọn ọgba ẹwọn meji ti wọn si tu awọn ẹlẹwọn to wa nibẹ silẹ.
Bakan naa ni ọjọ aje kan naa awọn janduku miran ṣọṣẹ ni ipinlẹ Eko ti wọn si tun tẹsiwaju lowurọ ọjọ Iṣẹgun nibi ti wọn ti dana sun awọn agọ ọlọpaa ti iroyin si tun kede rẹ pe ẹmi awọn eeyan kan lọ sii ti awọn miran si tun farapa.
Gẹgẹ bi ara igbesẹ lati dena ifẹmiṣofo, awọn ijọba ipinlẹ kọọkan ti n gbe igbesẹ nitori rẹ lati ti ileewe pa.
Ipinlẹ Edo.

Lẹyin gbogbo wahala to ṣẹlẹ lọjọ Aje, gomina ipinlẹ naa, Godwin Obaseki kede ofin konile o gbele ọlọjọ yipo eleyi to tumọ si pe ko si si ijade lọ si ibikibi ti kan awọn ileewe.
Ipinlẹ Eko.

Oríṣun àwòrán, AProkodoctor/twitter
Ni ọjọ Aje ni ipinlẹ Eko ti kede pe ki gbogbo ileewe, yala ti ijọba ni tabi ti aladani o wa ni titi pa titi di igba ti alaafia yoo fi jọba ni ipinlẹ naa pẹlu ọwọ tuntun ti ọrọ iwọde #EndSARS n yọ.
Ni ọjọ kejila oṣu kẹwaa ọdun 2020 ni ijọba ipinlẹ Eko kede wiwọle ni Ọjọ kọkandinlogun oṣu kẹwaa.
Ọjọ kọkandinlogun naa ti awọn akẹkọọ wọle ni ijọba ipinlẹ naa kede pe ki awọn akẹkọọ o gbe ile wọn naa titi di igba ti ọrs yoo fi tutu nigboro.
Ondo

Oríṣun àwòrán, Akinfe Akintunde
Awọn akẹkọọ ni ipinlẹ Ondo ṣẹṣẹ wọle ni Ọjọ Aje, ọjọ kọkandinlogun ni lẹyin ti wọn ti fi iwe kikọ ni kilaasi rẹ ni oṣu kẹta ọdun yii nitori ajakalẹ arun COVID-19.
Amọ, ọjọ keji ti wọn bẹrẹ iwe kikọ pada ni ijọba tun kede ki olukuluku akẹkọọ ati olukọ o fi idi mọle wọn nitori gbọnmọgbọnmọ wahala awọn janduku to ti ja iwọde #EndSARS gba ti wọn si ti fi n da ilu laamu bayii.
Ni ọjọ Iṣẹgun ni gomina Rotimi Akeredolu kede pe ki gbogbo iloro ileewe ni ipinlẹ Ondo di titipa lẹyin tawọn janduku ti gba igboro kan pẹlu awọn ohun elo ija loriṣiriṣi ti wọn si ti sọ iwọde di nnkan miran.
Oyo

Ni ọan ọjọ Iṣẹgun ni gomina Makinde ba awọn eeyan ipinlẹ Ọyọ sọrọ lori rukerudo to n waye lori bi awọn janduku kan ṣe ti sa wọ aarin awọn oluwọde ni ipinlẹ Ọyọ ti wọn si ti n lo iwọde naa lati fi kọlu awọn dukia ijọba, ẹmi ati dukia araalu.
Ninu ọrọ to ba awọn eeyan ipinlẹ Ọyọ sọ naa, Gomina Makinde ṣalaye pe ko gbọdọ si ileewe ti yoo ṣi fun ẹkọ kikọ bẹrẹ lati ọjọru, ọjọ kọkanlelogun, oṣu kẹwaa.
O ni wọn yoo wo bi nnkan yoo ṣe ri lọjọ Ẹti, ọjọ kẹtalelogun oṣu kẹwaa lati mọ boya aṣẹ naa yoo tẹsiswaju abi kawọn akẹkọọ pada sẹnu ẹkọ wọn.
Ekiti

Ni ipinlẹ Ekiti, ijọba ipinlẹ naa ti ti gbogbo ileewe pa; yala ileewe aladani ni tabi ti ijọba fun iyoku ọsẹ yii.
Akọroyin BBC nibẹ jẹ ko di mimọ pe kọmiṣọna fun Eto Ẹkọ, imọ sayẹnsi ati imọ ẹrọ, Ọmọwe Ọlabimpe Aderiye ṣalaye pe igbesẹ naa di kanranngida lati daabo bo ẹmi awọn akẹkọọ, olukọ atawọn oṣiṣẹ miran kaakiri awọn ileewe.
Ijọba ipinlẹ naa ni lati gba ti iwọde naa ti bẹrẹ, ẹnu ọjọ mẹta yii ti n mu idiwọ wa fawọn akẹkọọ ati oṣiṣẹ ileewe gbogbo lati de ileewe wọn.
O ni o di ọjọ kẹrindinlọgbọn oṣu kẹwaa ki ileewe to tun ṣi pada.














