Akomolede ati Asa: Mọ̀ si nípa àwọn ọ̀nà tí Yorùbá ń gbà ran ara wọn lọ́wọ́

Àkọlé fídíò, Akomolede ati Asa: Mọ̀ si nípa àwọn ọ̀nà tí Yorùbá ń gbà ran ara wọn lọ́wọ́

Lori eto Akomolede ati Asa lori BBC Yoruba fun tọsẹ yii, ohun ta gbeyẹwo ni asa iran ara ẹni lọwọ.

Yoruba ni ajeje ọwọ kan ko gbe ẹru dori, nitori naa lo fi se pataki lati maa ran ara wa lọwọ.

Olukọ wa lọsẹ yii, Arabinrin Funke aya Falade-Young si ti wa nikalẹ lati kọ wa nipa orisirisi asa iran ara ẹni lọwọ to wa ati anfaani wọn.

Olukọ wa salaye lori ilana sise Ajọ, Aaro ati Ọwẹ lati fi ran ara wa lọwọ ati iyatọ to wa laarin wọn.

Bakan naa la tun mọ nipa awọn ọna ta le gba lati san eto yii pada laarin awọn eeyan to ba n kopa ninu rẹ.

Arabinrin Funke Falade-Young salaye ni kikun fun gbogbo wa bi asa iranraenilowo se se pataki nile Yoruba

Ẹ fi ara balẹ, kẹ maa ba olukọ wa bọ, lati kẹkọ nipa asa ilẹ Yoruba to da lori eto riran ara ẹni lọwọ.