Akomolede ati Aṣa lori BBC: Kí ní ìtúmọ̀ Sílébù àti àmi ohun tó ń fún ni?

Àkọlé fídíò, Akomolede ati Aṣa lori BBC: Kí ní ìtúmọ̀ Sílébù àti àmi ohun tó ń fún ni?

Olukọ wa lonii ni Niyi Osunlolu, oun si ni yoo maa kọ wa nipa itumọ silebu.

Gẹgẹ bii alaye olukọ, Silebu ni ọrọ tabi ege ọrọ ti eemi le gbe jade lati ẹnu ni ẹẹkan soso laisi isoro kankan.

O ni a le ge ọrọ si silebu niye igba ti eemi ba jade.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Bakan naa ni olukọ salaye pe, iye igba ta ba ni imọ afẹfẹ latinu ẹdọ fooro wa, lo n sọ iye Silebu to wa ninu ọrọ kan.

Alaye olukọ pọ lori Silebu, ẹ wa nnkan fidi le lati kẹkọọ siwaju nipa ege ọrọ, taa mọ si Silebu yii.